Adam and Eve (The Garden of Eden and the Throne of God)  ORIN AKOBERE (Opening Song)


 • Gbogbo eda aiye o, E bo k’a lo
 • E wa k’a lo yin Jesu l’oke o
 • Gbogbo eda orun o, E bo k’a lo
 • E wa k’a yin Baba t’o da wa
 • Ati Jesu t’o nsise Emi o
 • Gba t’ayie ti se, ko s’igi
 • Ko s’aja ko s’ope ko, s’omi
 • Okunkun l’ayie wa o
 • Ki Baba to s’ise Eda o
 • Baba l’o da ‘mole oun l’o da orun
 • Iraw’ osupa han o Enia wa bori Eda o
 • Beni a da Adam, beni a da Efa
 • Li aworan Baba, Enia wa bori Eda o
 • A o yi o, nwon je igi eleso )
 • Nwon d’enia t’o se ) 2ce
 • A iku ma de o, wahala pupo o w’ayie
 • Nigba ti a da won, ihoho l’a da won
 • A l’ojo ikehin o won ko ni le mu nkan d’oke o
 • Baba wa Jesu wa mura
 • O f’ade Re s’ile O mura O gb’ayie lo
 • O ku f’omo arayie
 • Ki won le joba l’ode orun e ya
 • Enia to se yio ye o
 • A ara mi ibikibi ti Jesu ba wa la o lo
 • A o gbade imole n’ile Re l’oke o
 • A! ile A! ile o
 • Ile ewa wonni b’o ti dara to o
 • Jesu Eleda mi k’o mu mi de be o

  ACT 1 SCENE 1

 • Adam oun Efa ninu ogba Eden nyin Oluwa

 • Ninu ogba ti a da’wa si
 • Paradise n’ile ogo ) 2ce
 • Baba Oluwa Omo Oluwa
 • Emi t’o gbe wa ro
 • Awa juba awa wole
 • A dupe Oluwa fun dida t’o daw a
 • A Oluwa mu wa de’le ogo
 • O fi wa joba lori eran
 • O fi wa joba lori eja
 • Gbogbo eyie oju orun
 • A o f’iyin f’Oluwa
 • A Oluwa gbe wa de ‘le ogo
 • Bi Baba l’o ntoju wa
 • Ninu ogba, ninu ogba Eden
 • A o ma je ninu eso
 • Esokeso t’o le so
 • A Oluwa, Iwo t’o j’Oluwa aiye

  ACT 1 SCENE 2


 • Oluwa si wa lati be won wo ni imoru ojo ninu ogba

 • Olorun: Oju Re da, nibo l’o wa o
 • Oju Re da, Adam?

 • ADAM ATI EFA


 • Orun l’o ran hanhan n’nu ogba
 • Oluw’ayie E ma ku atijo o

 • ADAM AND EFA


 • Orun l’o ran hanhan n’nu ogba
 • Oluw’ayie E ma ku atijo o
 • Baba o Baba
 • Ope lo ye Baba t’o da wa o
 • Baba t’o da ayie
 • Ka ri O ma bo, ka ri O o Baba
 • Baba t’o da wa s’inu ayie
 • Ka ri O ma bo, ka ri O o Baba
 • A ranti Oluwa
 • Pe Olodumare lo nsogo
 • Baba o Baba
 • Ope lo ye Baba t’o da wa o
 • Baba t’o da ayie

 • A si pase fun won pe won ko gbodo je ninu eso igi imo rere ati buburu

 • Olorun: Enyin ti mo da o omo enia
 • E ku ayo, E o jire?
 • Alafia mi mbo wa ba yin
 • Ile ayie o ile rere ni fun nyin
 • Ile ibukun o ti mo ti pese s’ode ayie
 • E ma a jo o, k’e si ma yo o
 • E ma je, k’e si ma a mu
 • Ninu ola Baba t’o da ayie
 • E o ma je ninu eso
 • Esokeso t’o le se
 • Sugbon e ewo ni t’e ba je ninu eso
 • Igi imo buburu, igi imo rere o
 • Nitori t’e ba je e, e o ma ku o
 • Emi l’o si mo rere o

 • ADAM ATI EFA


 • A dupe Oluwa Baba Ogo
 • Aws mo O o
 • L’Oluwa olore wa
 • Jowo gba wa o s’ile ogo
 • Ope ni f’Oluwa ibukun wa l’oke
 • A o ma a yo, ayo sir ere
 • Alafia re mbo wa ba wa
 • Sunmo wa ma a bo, sunmo wa o Baba
 • Ope lo ye, Baba t’o da wa o
 • Baba t’o da ayie
 • Ile ayie o, ile rere ni fun o
 • Ile Ibukun o t’Iwo ti p’ese s’ode ayie

  ACT 1 SCENE 3


 • Ejo sa se arekereke ju gbogbo eranko igbe ‘yoku lo, o tan Efa, oun si je ninu eso igi na

 • Ejo: Nje l’otito l’Oluwa wipe
 • E ko gbodo je ninu eso
 • Ti mbe ninu ogba Eden?
 • Efa: Oluwa lo ‘o pa a lase
 • Pe a o ma je ninu eso
 • Esok’eso t’o le so
 • Sugbon eewo ni t’a ba je ninu eso
 • Igi imo buburu, igi imo rere o
 • Nitori t’a ba je a o ma ku o
 • Baba l’o si mo rere o
 • Ejo: Iro ni, eke ni a, oro etan e a o
 • Nitori Baba mo pe l’ojo t’e ba je
 • E ki yio ma ku o
 • Oju yin yio la e o Olorun
 • E o si mo buburu
 • E o si mo rere o
 • Efa: Nitori t’a ba je e a o ma ku o
 • Baba l’o si mo rere o
 • Ejo: Gba mi gbo Efa
 • Gba mi gbo o, otito ni
 • Efa: Gba mi gbo nitori
 • Otito o l’oro Oluwa
 • Ejo: Gba mi gbo Efa
 • Gba mi gbo o, otito ni
 • Efa: Gba mi gbo nitori
 • Otito o l’oro Oluwa
 • Ejo: Gba yi je, bi o ba )
 • Gba yi je rere ni ) 3ce

  ACT 1 SCENE 4


 • Efa si fifun oko re on si je , oju awon mejeji si la, nwon si rip e awon wa ni ihoho, nwon si fi ara pamo

 • Efa: Sare, sare k’o wa wo
 • K’o wa gbaje ninu eso
 • Onje to dun t’o l’oyin
 • Bale mi wa gba k’o wa je
 • Ohun t’o dun
 • Adam ati Efa Emo o, Emo o
 • Oju wa o la o si o
 • Olorun l’o mo rere o
 • Eru wa ba mi (2)
 • Tori a ti se s’Olorun
 • Ihoho l’a da wa, ihoho l’a wa o
 • Ewe opto o, ewe rere Oluwa
 • Ewe opoto o l’a o fib o itiju ayie

  ACT 1 SCENE 5


 • Oluwa Olorun si ko si Adam pe “Nibo ni iwo wa”!

 • Olorun: Oju re da, nibo lo wa o
 • Oju e da, Adam
 • Adam: Mo gbo ohun re l’eti mi
 • Eru wa ba mi o Oluwa
 • Mo wa sapamo o
 • Nitori ihoho mo wa o
 • Olorun: Bawo l’o ti se mo
 • Kini o ti se gbo
 • Tani eni t’o so fun o
 • Pe iwo wa ni ihoho
 • Tabi o ti je ninu igi
 • Eyi ti mo ti pa l’ase
 • Pe o ko gbodo je?
 • Adam: Obinrin t’o pelu mi
 • On l’o fi fun mi
 • Ninu eso na, mo si je
 • Olorun: Bi o ban sire ona oto
 • Bi a ba nsokun, nriran
 • Ki l’o sun o, de be Efa?
 • Efa: Ayokele bi ekun igbo
 • Aringbere ma k’ero l’ona
 • Ejo l’o tan mi o, mo si je
 • Olorun: Iwo eni etan, nitori eyi ti o se
 • A fi o bu o, ninu eran inu igbo
 • Inu re n’iwo o ma fi wo
 • L’ojo ayie o
 • Erupe ile n’iwo o ma fi je
 • L’ojo ayie, l’ojo ayie re gbogbo
 • Emi yio se nyin l’ota ara
 • Iwo ati oun, oun o fo o li ori
 • Iwo o pa o, ni gigirise o
 • Olorun: Nje mo wi fun o, obinrin
 • Wipe iponjure re yio po
 • Ninu iponju o ni iwo o s’abiyamo
 • Ife re yio po s‘oko re
 • Niti olori o, oko ni se baba
 • On ni yio se olori re
 • Olorun: Nje mo wi fun o, okunrin
 • Nitori eyiti o se
 • Ti o gba iyawo re gbo
 • Ti o si se ni jije ninu eso
 • Igi imo buburu, igi omi rere o
 • A f’ile bu nitori re
 • Ninu wahala n’iwo o ma jeun
 • L’ojo ayie re gbogbo
 • Egun ogan on osusu
 • Ni yio ma hu wa fun o
 • L’ojo ayie re gbogbo
 • Eweko igbo l’onje fun o
 • L’ojo ayie re gbogbo
 • L’oogun oju re n’iwo o ma jeun
 • Titi iwo o bo wa s’orun
 • Nitori lati ‘le la ti mu o wa o
 • Erupe ni o o, Iwo o pada s’ile o

 • Awon angeli ti o yi ite ka si mbe Olorun fun igbala emi enia

 • Enia subu, enia subu
 • Tori nwon ti se s’Olorun
 • Ihoho la da won, enia t’o se o (2)
 • Ewe opoto o, ewe rere Oluwa (2)
 • Ewe opoto o, ni nwon fib o itiju ayie
 • Awa be O Oluwa )
 • Pe emi enia ki yio segbe )2ce
 • O d’owo Re igbala won )
 • O d’owo Re Baba )2ce
 • A f’oju ni won ti ko mo ‘kan o
 • Esu lo tan won o
 • O d’owo Re igbala won
 • O d’owo Re Baba
 • B’esu nleri o t’o si nsogo
 • L’ori enia t’o se o
 • O d’owo Re igbala won
 • O d’owo Re Baba
 • Ma je ki won te o
 • Ma je ki won o segbe
 • Ranti Oluwa O d’owo Re
 • Igbala won O d’owo Re o Baba

 • Olorun: Mo to gbo tin yin o enyin Angeli mi
 • Pee mi enia ki yio segbe
 • E kiyesi o pe omo enia
 • O dabi okan ninu wa
 • Lati mo eewo s’oto o
 • Nje ko ma ba a je ninu igi iye o
 • E lo le won jade
 • E lo le won kuro nibe o
 • Kerubu mi o, iyen d’owo re o dandan (2)

 • Oluwa Olorun si le won jade kuro ninu ogba

 • Kerubu: Nje l’oruko Jehova ni mo le nyin jade
 • E lo kuro nibe o buse
 • Eni ti ki isoro ko ye o
 • Nje k’e ma ba je ninu igi iye o
 • Mo wa le nyin jade
 • E lo kuro nibe, o buse

 • Meje ninu awon akorin orun nkorin ebe si Olorun nitori enia

 • Oluwa t’o ngbe nu ayie
 • Si O Baba Oluwa
 • Ranti dida t’o da won
 • K’o gba k’o gbo Oluwa (2)
 • Baba Omo
 • Edumare k’o gba won o Jesu Baba
 • Won je igi eleso won d’enia t’o se o (2)
 • Olugbala ko gba won o Jesu Baba
 • Ranti dida t’o da won
 • K’o gba k’o gbo Oluwa
 • Esu odale l’o mu won se
 • Jesu mimo yio mu won ye
 • Bi enia ti ku ninu Adam
 • Beni won yio d’alaye ninu Jesu
 • Baba Omo
 • Olugbala k’o gba won o Jesu Baba
 • Won je igi eleso won d’enia t’o se o
 • Olugbala ko gba won o Jesu Baba
 • Ranti dida t’o da won
 • K’o gba k’o gbo Oluwa
 • Ye! Baba Messiah o
 • Omo Oluwa t’o k’ese ayie lo
 • Eje mimo Messiah
 • L’o le ba wa tun t’eda se
 • NIgbati a da won
 • Nwon ko ni kini kan
 • A! ojo ikehin o
 • Nwon ko ni le mu nkan d’oke o
 • A f’Oluwa a f’Oluwa
 • Ko ma s’enia l’ayie o
 • Ko ma si Angeli l’oke
 • T’o le ba wa tun t’eda se
 • A f’Oluwa a f’Oluwa (2)
 • Jowo da won l’are
 • Jowo gbe won l’eke o
 • A f’Oluwa

  ACT 2 SCENE 1


 • Lucifer ninu ijoba re, awon omo ogun re nse Kabiyesi

 • Kabiyesi Lucifer wa, oba alade, oba ‘lela
 • Eni ruru bi omi okun
 • Bombata ti ba agba l’eru
 • Oba apota p’elegbe, Lucifer eni ‘re
 • Ayokele bi ekun igbo
 • Aringbere ma k’ero l’ona
 • Oba to m’oni to tun m’ola
 • Eni ba se o, o se Olorun
 • Igbakeji Olorun Lucifer eni ‘re
 • Kabiyesi o, Kabiyesi o
 • Kokoro owo mbe l’owo re
 • Kokoro ola mbe lowo re, Oba apota p’elegbe
 • Igbakeji Olorun, Lucifer eni ‘re

 • Lucifer dahun o si ngbero lati bere emi enia l’owo Olorun
 • Nje mo dupe lowo nyin
 • Enyin ti npe mi l’Oluwa
 • Emi alade imole ti njoba ninu ina
 • Emi kiniun oba ina
 • O ti Baba l’orun ko le mu mi
 • Erin oko ti b’agba leru
 • Lucifer eni re
 • Nje mo be nyin ara mi
 • E je ka papo ka lo ri Olorun
 • Ka bere emi enia
 • Ka le mu won bo sinu ina o
 • Emi alade imole ti njoba ninu ina
 • Enia to se, ti wa ni se
 • E je ka mu won bosile wa
 • Lucifer eni re

 • Awon omo ogun re si mura lati ran a lowo, ki emi enia le je ti won

 • Iba, Iba, Iba, Baba awa o Lucifer mimo
 • Ologbo wewe inu orun, Lucifer mimo
 • Oba to m’oni to tun m’ola, Lucifer mimo
 • Oba to dade inu ina, e ya
 • Eni riru bi omi okun, e ya
 • Enia to se yio segbe
 • Bi a ba be Olorun Orun ti ko gbo o
 • A o jagun ni l’ode orun, e ya
 • Enia ti o se yio segbe

 • Lucifer mura lati ba Olorun jagun bi ko ba fie mi enia le on l’owo

 • Ye! Ara mi o (2)
 • E mura k’e d’amure ko le
 • Bi a ba be Olorun Orun ti ko gbo o
 • A o jagun ni l’ode orun, e ya
 • Enia ti o se yio segbe
 • AWON OMO OGUN LUCIFER
 • Bi a ba be Olorun Orun ti ko gbo o
 • A o jagun ni l’ode orun, e ya
 • Enia ti o se yio segbe

  ACT 2 SCENE 2


 • Awon Angeli Olorun si nkorin iyin niwaju ite Olodumare

 • Baba Oluwa a dupe, Oluwa
 • Iwo t’o j’Oluwa aiye lo
 • Baba Oluwa a dupe, Oluwa
 • Iwo t’o j’Oluwa aiye lo
 • Atamatase Oluwa Olugbala ologo
 • K;a ma se gbagbe Re, a juba Re
 • Atamatase Oluwa Olugbala ologo
 • K;a ma se gbagbe Re, Baba ogo
 • Baba, Emi, Jesu, Olugbala ba mi gbe (2)
 • Baba, Emi, jeka le wo nu ogo (2)
 • Ki Baba l’oke gbowo wa
 • Ki Omo l’oke gbowo wa
 • Eni meta a dupe Oluwa
 • Iwo to j’Oluwa ayie
 • Mimo Mimo Mimo
 • Ijinle meje orun
 • Mimo Mimo Mimo
 • Eni t’o ga ju orun
 • Owo, Owo, Baba to n’ile ayie
 • Baba Ologo Oluwa
 • Kabiyesi o Kabiyesi o
 • Awa wa juba Oluwa
 • Wariri f’Oluwa (2)
 • Iwo ile ayie o

 • TEN MINUTES INTERVAL


  ACT 2 SCENE 3


 • Lucifer ati awon omo ogun wa siwaju Ite aanu. Awon Angeli si nki won ma wole

 • Lucifer de o, e ma wole o
 • Irawo owuro de o, e ma wole o
 • Eni to ga ninu ayie
 • Alagbara ninu orun
 • Igbakeji Orisa, Igbakeji Olorun
 • Lucifer eni re
 • Awa ki o k’abo, baba mi
 • Baba ‘re, Baba awa de
 • Igbakeji Orisa, Igbakeji Olorun
 • Lucifer eni re
 • Baba ki o, k’abo
 • O de o, Lucifer eni re
 • Alada imole o de o, Lucifer eni ‘re
 • Awa ki o k’abo, baba mi
 • Baba ‘re, Baba awa de
 • Igbakeji Orisa, Igbakeji Olorun
 • Lucifer eni re

 • Lucifer ati awon omo re bere Emi enia lowo Olorun

 • A wa se dupe Oluwa
 • Nitori enia ti o da
 • A wa se dupe Oluwa
 • Nitori enia tim o da
 • Sugbon nwon subu (2)
 • Oju wa, wa nsaanu fun won
 • Iwo lo da won sinu ayie
 • Awa si mu won te si ti awa
 • Iwo lo da won ti nwon subu
 • Awa ti mu won se ‘fe awa
 • Lucifer eni ‘re
 • Awa wa be o OLuwa
 • Ki Emi enia le je ti wa (2)
 • Awa yio mu won da’de ogo
 • Nwon ki yio si se wahala
 • Tori nwon ti se ‘fe awa
 • Ati li opin ojo won ninu ayie
 • Awa ni yio mu won bo wa
 • J’oba ninu ina (ina)

 • Olohun dahun, o si ko lati fi Emi enia le Lucifer l’owo

 • Enyin eni epe, enyin eni etan
 • Enyin eni egun, Alade ayie ofo
 • Gbogbo ola ti e ni o
 • Yio pin sinu ina
 • Sugbon enia omo mi
 • Omo ogo, omo ileri
 • Ki yio joba ninu ina
 • Nitori o ga ju nyin lo
 • Enia to je aworan mi
 • Emi eni t’o s’owon fun mi
 • L’ayie l’orun o,
 • Ki yio joba ninu ina

 • Lucifer ati awon omo ogun re se ileri lati ba Olorun jagun

 • Bi a ba be O, to lo gbo?
 • Bi o ba gbagbe Lucifer Re
 • Okunkun ko ma m’eni owo
 • Ete ni yio kehin l’oju Re
 • Ogun a j’ayie atun j’orun
 • Rogbodiyan yio se l’orun
 • Enia ni yio jebi o
 • Ati li opin ti ija ba pari
 • Gbogbo wa ni yio parapo
 • Wa j’oba ninu ina

  ACT 2 SCENE 4


 • Lucifer ati awon omo ogun re wa nibiti won yio jagun

 • Itajesile o ya o )
 • Itajesile l’a o se )2ce
 • Ka ge ni l’owo, ka ge ni l’ese
 • Ka fo ni l’oju, ka ge ni l’orun
 • Ka gbe ni dori o, ka tun la ni mole
 • E re, Itajesile l’a o se
 • Awa ko ma ni sokun re, o lo o (2)
 • Ka gbe ni dori o
 • Ka tun la ni mole, E re
 • Itajesile la’ o se

 • Itajesile o ya o )
 • Itajesile l’a o se )2ce
 • Ka ge ni l’eti, ka ge ni ni ‘kun
 • Ka ko ni l’eru, ka ko ni leru
 • Ka fo ni n’le o, ka tun la ni mole
 • E re, itajesile l’a o se
 • Awa ko ma ni sokun re, o lo o (2)
 • Ka gbe ni dori o
 • Ka tun la ni mole , E re
 • Itajesile la o se
 • Itajesile o ya o
 • Itajesile l’a o se
 • Ka gba ni l’eti, ka gba ni l’orun
 • Ka da ni n’ikun, ka ge ni l’orun
 • Ka gbe ni dori o, ka tun la ni mole
 • E re, Itajesile l’a o se
 • Awa ko ma ni sokun re, o lo o (2)
 • Ka gbe ni dori o
 • Ka tun la ni mole, E re
 • Itajesile la’ o se

 • Itajesile o ya o
 • Itajesile l’a o se (2)
 • Ka ge ni l’owo, ka ge ni l’ese
 • Ka fo ni l’oju, ka ge ni l’orun
 • Ka gbe ni dori o, ka tun la ni mole
 • E re, Itajesile l’a o se
 • Awa ko ma ni sokun re, o lo o (2)
 • Ka gbe ni dori o
 • Ka tun la ni mole, E re
 • Itajesile la’ o se

 • Michaeli ati awon omo ogun re si de, lati ba Lucifer jagun

 • Ogun mbo o, oti de na (2)
 • Ayie a gbina o, orun a fo lo (2)
 • Awa mura fe ja ogun orun
 • Lucifer oni yio subu
 • Michaeli oni yio bori
 • Awa mura fe ja ogun orun
 • Awa ko ma ni sokun re . o lo o (2)
 • Awa mura fe ja ogun orun
 • Enyin, Enyin, Enyin, Enyin
 • T’e mura lati ja o
 • Ejo yin d’orun
 • Itajesile la o se, Itajesile la o se
 • Awa ko ma ni s’okun re, o lo o
 • Itajesile la o se

 • Ija nla si sele ninu awon orun, ogun Michaeli sib a ogun Lucifer ja

 • Ariwo ya, ya, ya, ariwo e
 • E gbe won d’ori o ke tun la won mole o
 • Itajesile l’o gb’ode
 • E f’ida gun won o, e so won l’oko
 • Ariwo ya, ya, ya, ariwo o
 • E gbe won d’ori o ke tun la won mole o
 • Itajesile l’o gb’ode

  ACT 2 SCENE 5


 • Lucifer ati awon omo ogun re wa nibiti won yio jagun

 • Enyin ti mbe l’orun
 • Enyin ti mbe l’oke o
 • Awa wa yin Baba ogo (2)
 • Eni t’o segun t’o segun
 • Eni t’o gbeja alaini
 • E s’ope fun Baba orun
 • Enia t’o se yio ye o
 • Michael segun iku tan, e ya
 • Lucifer l’o d’eni egbe o
 • A segun iku l’ode orun e ya
 • Enia t’o se yio ye o
 • A! e yo, e yo, e yo (2)
 • Enyin omode inu ayie
 • Enyin omode inu orun
 • Enia t’o se yio ye o
 • Michael segun iku tan, e ya
 • Lucifer l’o d’eni egbe o
 • A segun iku l’ode orun e ya
 • Enia t’o se yio ye o

  ACT 3 SCENE 1


 • Awon Angeli Olorun nkorin iyin s ii nipa iseda ayie

 • T’ayie t’orun njuba Re Oluwa
 • Iwo t’o j’Oluwa ayie )2ce
 • Yin Baba l’oke yin Omo Re
 • Eni Metalokan Oluwa
 • T’a npe ninu iseda ayie
 • Latetekose l’ayie wa ninu ofo )2ce
 • Li ayie ko s’igi, li ayie ko s’ope
 • Okunkun l’o bo ‘le
 • Emi Olorun si nra l’oju ibu
 • Oba Oluwa ogo dide
 • On l’o da imole, On l’o da orun
 • Irawo pelu osupa han
 • Eja ninu omi Okun, Halleluyah!
 • Oke nla farahan, awon ewko hu
 • Eranko ninu igbo at’eiye oju orun
 • Gbogbo won ni ise owo Re
 • Iwo t’O j’Oluwa ayie
 • ‘Gbana ni Baba pe
 • E wa o enyin orun
 • Enyin ti mo ti yan
 • Fun ‘se iseda ogo
 • E wa k’a mo enia (2)
 • K’o j’aworan ara wa
 • Emi Olodumare k’o joba nile ayie
 • Dida enia ohun t’o jinle ni
 • Oba Oluwa Anu
 • Ijinle meje orun
 • Ijinle, ijinle, Baba Oluwa t’o daw a
 • E ke Halleluyah s’Oluwa ogo (2)
 • F’iyin f’Oluwa Oba ogo (2)
 • Baba Oluwa Iwo t’o j’Oluwa aiye

 • Awon olori akorin orun meta mbebe fun Emi enia niwaju Oluwa

 • Lebute, lebute ogo (2)
 • Awa l’ankorin f’Olodumare
 • Nitori enia t’o ti d’ese
 • Ki won le j’arole ogo
 • L’ebute, l’ebute ogo (2)
 • Ainiye l’awon Angeli l’oke
 • Ti ngberin k’enia to se
 • B’a le j’arole ogo
 • Oluwa Baba wa, Jesu gbere o
 • Oluwa A! Messiah gbere o
 • Jehovah Eni’re nase j’enia sonu o
 • Gbadura wak’enia to se
 • B’a le j’arole ogo
 • Lucifer eni ibi
 • L’o m’enia kose o
 • Gbadura wa k’enia to se
 • B’a le bori idanwo
 • Baba mimo Oluwa mi esan (2)
 • Eni ba se rere a ri re
 • Eni ba s’ika yepa o gbe
 • Lucifer eni ibi
 • L’o ti m’enia kose o
 • Sugbon Baba wa o d’owo Re o
 • K’a ba le gb’enia l’eke o
 • Afoju ni nwon o enia t’o se o
 • Ihoho la da won enia t’o se o
 • Esu lo tan won ti won je igi eleso
 • K’o ma s’eni ti ko le se )2ce
 • A fi Baba Olodumare o
 • O d’owo Re, ise igbala d’owo Re
 • Ona igbala, o d’owo Re Baba ogo
 • Ma je ki won te o, ma jeki won segbe
 • Dariji won
 • O d’owo Re, ise igbala d’owo Re
 • Ona igbala, o d’owo Re Baba ogo

 • Awon Angeli l’oke bebe fun igbala emi enia niwaju Olorun

 • Enia subu (2)
 • T’ori won ti se s’Olorun
 • Ihoho l’a da won
 • Enia t’o se o (2)
 • Ewe opoto o, ewe rere Oluwa
 • Ewe opoto o, ni won fib o itiju ayie)2ce
 • Awa be O , Oluwa
 • Pe emi enia ki yio segbe
 • O d’owo Re, igbala won
 • O d’owo Re o, Baba
 • Afoju ni won o
 • Ti ko ni imo kan
 • Esu lo tan won o
 • O d’owo Re, igbala won
 • O d’owo Re o, Baba
 • Ma je ki won te o
 • Ma je ki won segbe
 • Ranti Oluwa
 • O d’owo Re, igbala won
 • O d’owo Re o, Baba
 • B’esu nleri
 • T’o si nsogo
 • Lori enia to se o
 • O d’owo Re, igbala won
 • O d’owo Re o, Baba

  ACT 3 SCENE 2


 • Olorun dahun, O si mbere eniti yio lo lati gba Emi enia la
 • Mo to gbo tin yin o, enyin Angeli mi
 • Pe Emi enia ki yio segbe (2)
 • Nje Mo fun ipe, E wa o enyin orun
 • Enyin ti mo ti yan fun ‘se iseda ogo
 • Nje tani yio lo s’ayie o
 • Lati ra enia pada o
 • Tani yio f’ade re sile
 • K’o wa mura ko gb’ayie lo
 • Ko lo ku f’omo arayie
 • Ko lo jiya f’awon elese
 • Ko le mu won bo sile ogo
 • Agbelebu igi oro
 • Agbelebu igi iya o
 • Tani yo le lo o (2)
 • Michaeli wi o, Gabrieli wi o
 • Ebi yio pa nyin, ongbe yio gbe nyin
 • Egun itiju yio won yin lorun
 • Ati lehin gbogbo wahala
 • Agbelebu igi oro
 • Agbelebu igi iya o
 • Tani yo le lo o

 • Michaeli ati Gabrieli ko lati fie je won ra enia pada

 • A dupe o Baba orun
 • A dupe o Baba ogo
 • Iku ayie o, ijiya ayie o
 • Agbelebu igi oro
 • Agbelebu igi iya o
 • A ko ni le lo o
 • Itelorun lo wa fun wa
 • Ni Paradise ile wa
 • Ebi ko pa wa
 • Ongbe ko gbe wa
 • Awa njo a nyo si o
 • A ko ni le f’ayo sile
 • K’a wa mura ka gb’ayie lo
 • Lati ku f’omo arayie
 • Ka le mu won bo s’ile ogo
 • Agbelebu igi oro
 • Agbelebu igi iya o
 • A ko ni le lo o
 • Bi a ba lo ku o, a ko ni le ji o
 • Iranse l’a je Oluwa
 • Agbelebu igi oro
 • Agbelebu igi iya o
 • A ko ni le lo o

 • Awon Angeli ko, lati fie je won ra enia pada

 • A gbo o, Baba orun
 • A gbo o, Baba ogo
 • Iranse l’a je Oluwa
 • A ko ni le f’ayo sile
 • K’a wa mura ka gb’ayie lo
 • K’a lo ku f’omo arayie
 • Ka le mu won bo s’ile ogo
 • Agbelebu igi oro
 • Agbelebu igi iya o
 • A ko ni le lo o
 • E je ka bi Jesu lere
 • Omo Oluwa ogo, Oluwa ogo ye
 • Agbelebu igi oro
 • Agbelebu igi iya o
 • A ko ni le lo o

  ACT 3 SCENE 3


 • Jesu Omo Olorun yoda ara Re lati fie je Re ra enia pada

 • Mo dupe o, Baba orun
 • Mo dupe o, Bab ogo
 • Mo fe lati f’ade sile
 • Ati ipo to ga l’orun
 • Mo fe lati f’ayo sile
 • Ki nlo ma sokun layie
 • Ki nlo ku f’omo arayie
 • Ki nle mu won bo sile ogo
 • Agbelebu igi oro, agbelebu igi iya o
 • Iyen ko lopin re o
 • Ebi yio pa mi, orugbe yio gbe mi
 • Egun itiju yio wo mi l’orun
 • Gbogbo wonyi ko ja mi laya o
 • Agbelebu igi oro, agbelebu igi iya o
 • Ko ma ja mi laiya o
 • Ati nikehin t’ayie ba pin
 • Iboji ko ni de mi m’ole
 • Beni eni mimo Oluwa
 • Ki yio dibaje
 • Ki yio ku iku ayie ailopin
 • Agbelebu igi oro, agbelebu igi iya o
 • Ko ma ja mi laiya o
 • Iku l’ota ikehin
 • Ti a o pare l’ayie o
 • Emi yio si fi oku re
 • D’ikoto iku aiye pa
 • Agbelebu igi oro, agbelebu igi iya o
 • Ko ma ja mi laiya o
 • Nigbati mo ba pari ise
 • Irapada fun ayie o
 • Emi yio pada sile ogo
 • Pelu awon ti mo ra pada
 • Lati ri oju Oluwa
 • Ni Paradise ile orun
 • Emi yio gb’ade ikehin
 • Pelu ola Oluwa
 • Agbelebu igi oro, agbelebu igi iya o
 • Ko ma ja mi laiya o

 • Awon Angeli l’orun dupe lowo Jesu fun iyoda ara re

 • Baba wa, Jesu adupe
 • Baba wa jesu a dupe o
 • Enia t’o se yipo ye )
 • Alapa gigun to ngbani )
 • Ogbagba ni ojo idanwo )
 • Baba wa ti nlo ‘le ayie )
 • Eje Mimo Olodumare ) 2ce

 • JESU:

 • E, E gbo, E gbo, E gbo
 • Enyin Angelo le orun
 • Gbati mo ba lo le ayie
 • Igba die la o pinya mo
 • Ng o pada sile mi orun o
 • Enia yio gbade pelu mi

 • ANGELI:

 • Wa wa, ara mi (2)
 • K’a ki Baba pe o digba o
 • Baba wa ti nlo ‘le ayie
 • Eje mimo Olodumare

  ACT 3 SCENE 4


 • Jesu si dagbere fun Olorun ati awon Angeli ti mbe niwaju ite aanu ki o to kuro li orun

 • A o digba o, A o dabo o (2)
 • Baba mi ti mbe l’orun, a o dabo o
 • Angeli ti mbe lorun, a o dabo o
 • Ki Oluwa ma k’atunri o
 • ‘Gba mo ba pada, ka ri raw a
 • Ni Paradise ile ogo
 • A o dabo o
 • Mo nlo ile ayie, mo nlo
 • O dabo o (2)

 • Awon Angeli na si da A lohun pe o dabo o

 • A o dabo o, A o dabo o (2)
 • Iwo ti nrele igbala
 • Jowo ma ma pe o, K’o tete bo o (2)
 • K’o tete bo o, k’o tete bo o (2)
 • Iwo ti nrele igbala
 • Jowo ma ma pe o, K’o tete bo o
 • L’e nlo, Ile ayie l’E nlo
 • O dabo o

  ACT 3 SCENE 5


 • Gbogbo Eda orun si jumo ko iyin orin si Olorun

 • Oni l’ojo ti Baba wa ti yan
 • Ojo mimo ojo simi ogo
 • Enyin Angeli l’orun e dide
 • K’a jo juba Olodumare
 • Egbe: A dupe fun dida to da wa
 • A dupe fun gbogbo ore re
 • Baba Olodumare
 • F’ebun mimo fun wa k’a to lo
 • Baba to da wa, awa mbebe lodo Re
 • Solo: Be, Oluwa je ka ri O loni
 • Wa gbadura fun iranlowo wa
 • Gbogbo ileri esu a d’ofo
 • Sunmo wa l’agbara Re Jesu
 • Egbe: A dupe fun dida to da wa etc
 • Solo: Oluwa ko wa lona adura
 • Si gba wa, gba t’ota ba de
 • Jesu, eyi t’o ku, o di tire o
 • K’a le mu wa de ‘le wa loke o
 • Egbe: A dupe fun dida to da wa etc
 • Solo: A! lojo na, A lojo ikehin
 • Ti Baba wa yio k’awon tire jo
 • Ka le ka wa m’awon ti yio gbade
 • Ka sib a o d’ori ite Re
 • Egbe: A dupe fun dida to da wa etc

 • THE END

 • All rights reserved