Black Forest


  Opening Glee


  ITAN ERE NA


 • A” ye, ye, a ye, ye,
 • Ara ayie e gbo mi
 • Ara orun ‘gbo mi o
 • Lailai l’alayie ti d’ayie o dara
 • Lailai l’onika mi se ‘ka ti ko gbe
 • B’o ba w’ola a Jesu o
 • Yoruba a mo Olorun
 • L’ola l’ola Oluwa aiye o
 • Yoruba a mo Jesu o
 • Igbo Oluwo Igbo Olore
 • Igbo irunmale l’o da o
 • Yoruba igbani
 • won s’ofin lilelile
 • P’eni t’o ku iku oro
 • K’o mase f’ile bo ra
 • P’eni t’o ku iku iya
 • K’o mase f’ile bo ra
 • O d’igbo efon o d’igbo erin
 • Igbo irunmale l’o da o
 • Oba Ladosun Oluwa Oba toto
 • Oba Ladosun Oluwa Oba orisa
 • O f’omo f’oko l’agbara
 • O f’omo fun ijoye t’o nr’orun
 • ‘Gba t’omo ko jale
 • Oba Ladosun Oluwa
 • Binu o fa’da yo
 • Omo oba wa sonu lo
 • Igbo irunmale l’o wo o
 • A, k’e gbo o a k’e mo o
 • ‘Gbat’o de inu igbo
 • O p’ara da o r’orun
 • O b’awon oku soro
 • O b’awon oku jeun
 • Awon Sango pa, Awon ara pa
 • Won ko ‘ra won po
 • Won mi s’ayie oba tororo
 • Won ko ‘ra won po
 • Won mi s’ayie oba tarara
 • Omo Oba t’o sonu lo
 • Igbo irunmale lo wo o
 • Oba Ladosun Oluwa Oba toto
 • Oba Ladosun Oluwa Oba orisa
 • ‘Gba t’omo oba sonu lo
 • O ranse o p’onifa
 • O ranse o p’osanyin
 • Oju alawo ki i wo‘fa ko ma ri
 • Oju awole ki i wo‘bi ko ma yan
 • Oju Osanyin ki i woju ona k’o malo
 • Omo oba t’o sonu lo
 • Igbo irunmale lo wo o
 • Omo oba ko ni i ku
 • Omo oba ko n ii run
 • Omo oba ko ni sonu lo
 • Igbo irunmale l’o wo o
 • A ara mi, a ara mi o
 • Oku t’o ku iku oro
 • K’o mase ya l’odo mi
 • Oku t’o ku iku iya
 • K’o mase ya l’odo re
 • O d’igbo efon o d’igbo erin
 • Igbo irunmale l’o da o
 • Mase ya l’odo mi
 • O d’igbo efon o d’igbo erin
 • Igbo irunmale l’o da o

  The Black Forest


  ACT 1 SCENE 1


 • Oba Ladosun ninu ijoba re; awon enia re nse Kabiyesi

 • Kabiyesile a ki Oba Ladosun baba
 • Kabiyesile a ki oba Ladosun o (2)
 • Oba Oluwa mi Oba Oluwa re
 • Oba t’o l’ayie t’o tun l’orun
 • Ladosun baba
 • Kiniun oba igbo, Ekinrin baba odan
 • Lomilomi l’Oluwa
 • Ara ayie nki baba
 • Ara orun nyo sese
 • Ko s’aja t’o le laya
 • Ko f’oju d’ekun dandan
 • Kabiyesile a ki Oba Ladosun o (2)
 • Kabiyesi o Kabiyesi o
 • Omo erin j’ogun ola
 • Omo erin g’oke ola
 • Ajanaku m’igbo kijikiji l’oju ayie o
 • Iku baba orisa
 • Kabiyesile a ki Oba Ladosun baba
 • Kabiyesile a ki oba Ladosun o

 • OBA LADOSUN SI DA WON L’OHUN

 • Mo dupe l’owo yin
 • Enyin ti npe mi l’oluwa Ladosun baba
 • Emi kiniun igbo. Emi ekinrin odan
 • Lomilomi l’Oluwa
 • Ko s’aja t’o le laya
 • Ko f’oju d’ekun dandan
 • Omo erin j’ogun ola
 • Omo erin g’oke ola
 • Ajanaku m’igbo kijikiji l’oju ayie o
 • Iku baba orisa
 • Mo dupe l’owo yin
 • Enyin ti npe mi l’Oluwa Ladosun baba

 • AWON ENIA MBERE OFIN LOWO OBA NIPA SISINKU AWON ENITI WON KU IKU ORO

 • Oba Ladosun o Oba Ladosun o
 • Awa wa f’ejo kan sun
 • A wa f’ejo kan sun o o
 • A wa bere imoran
 • Jowo ye la wa l’oye
 • Oba Ladosun
 • BI Sango ba pa’nia
 • Bi Sopono bo’nia pa
 • Ole k’ole t’a ba pa
 • Kini ka ti s’oku won
 • Ka sin won sinu ile
 • Tabi ka sin won s’oko
 • K’a sin won sinu ira
 • Tabi ka ju won s’omi
 • A wa bere imoran
 • Jowo ye la wa l’oye
 • Oba Ladosun

 • OBA LADOSUN SI SE OFIN PE KI WON MA SIN OKU AWON TI WON KU IKU ORO SINU “IGBO OLUWO”

 • Mo dupe l’owo yin enyin enia gbogbo
 • Awon eni ara lu pa
 • Ko le ba mi gbe layie
 • Awon eni Sango lu pa
 • Ko le ba mi gbe o
 • K’iru won ma mase ya l’odo mi
 • K’iru won ma mase ya l’odo re
 • K’iru won ma mase ya l’odo wa
 • O d’igbo efon o d’igbo elerin o
 • O d’igbo efon o d’igbo oluwo o
 • O d’igbo olomo ko gbo’hun omo
 • A awon eni ara lu pa
 • Ko le ba mi gbe o

 • AWON ENIA SI F’ARA MO OFIN NA

 • Awon eni ara lu pa
 • Ko le ba wa gbe layie
 • Awon eni Sango lu pa
 • Ko le ba wa gbe o (2)
 • Oba Ladosun o wi ‘re
 • K’iru won ma mase ya l’odo mi
 • K’iru won ma mase ya l’odo re
 • K’iru won ma mase ya l’odo wa
 • O d’igbo efon o d’igbo elerin o
 • O d’igbo efon o d’igbo oluwo o
 • O d’igbo olomo ko gbo’hun omo
 • A awon eni ara lu pa
 • Ko le ba wa gbe o

 • AWON ONIJO ILU NA SI NSE ARIYA NIWAJU OBA

 • Iba baba Ladosun o, baba Ladosun o
 • T’ayie t’orun nw’oju re
 • Orisa loo ngba o la (2)
 • Sansangele o eyie oko
 • Ko gbe mi pade ire
 • Baba Ladosun o
 • Awon enia nj’ola re
 • Ologini t’ajo bo o
 • E Ladosun a de o, orisa oluwa
 • Ologini t’ajo bo o

  ACT 1 SCENE 2


 • A SI SIN OKU OKUNRIN KAN TI ARA PA SINU IGBO OLUWO NA

 • E ile ire o. E ile ire re o (2)
 • Ara ye o lo o a ile ire re o
 • Awa nsofo baba awa
 • Baba awa t’o d’ologbe o
 • O ti lo ‘ipe n’ile orun
 • O d’ile ayo kai ri ‘ra
 • O d’igba kan na (2)
 • Olojo de o pari
 • Gbogbo eda orun nki o
 • Efufulele ko gbe o de ‘le orun
 • O d’ipade o
 • Enyin ara wa e gbo o
 • ‘Gbati baba wa ns’agbe l’oko
 • Ojo su dede ojo fe ro
 • Ara omokunrin orun
 • O de ‘le ayie k’ile o mi
 • O mi ‘le ayie kijikiji
 • O san lat’orun s’ori ile
 • O pa baba wa li a pa de orun a
 • A ko le sin o o s’ile wa
 • A ko le sin o o s’ona wa
 • Iwo eni ara lu pa
 • Ko le ba wa gbe layie
 • Iwo eni Sango lu pa
 • Ko le ba wa gbe o
 • K’iru re ma mase ya l’odo mi
 • K’iru re ma mase ya l’odo re
 • K’iru re ma mase ya l’odo wa
 • O d’igbo efon o d’igbo elerin o
 • O d’igbo efon o d’igbo oluwo o
 • O d’igbo olomo ko gbo’hun omo a
 • Iwo eni ara lu pa
 • Ko le ba wa gbe o

 • A SI SIN OKU OLE KAN S’INU IGBO OLUWO NA

 • E ile ire o. E ile ire re o (2)
 • Ara ye o lo o a ile ire re o
 • Awa ns’ofo odaran yi o
 • Eni t’o jale ninu oko
 • O j’agutan kan o fi r’aso
 • O j’elede kan o fi l’aya
 • O j’eyiele o fi mu ‘ko
 • Oba Ladosun wa fi bo oro
 • Idajo ayie ni ‘dajo orun
 • O d’igba kan na (2)
 • Olojo de o pari
 • Gbogbo eda orun nki o
 • Efufulele ko gbe o de ‘le orun
 • O d’ipade o

 • A SI SIN OKUNRIN KAN TI, SOPONA BO PA SINU IGBO OLUWO NA

 • E ile ire o. E ile ire re o (2)
 • Ara ye o lo o a ile ire re o
 • Enyin ara wa e gbo
 • Sopona lo lu u pa
 • Sopona lo ‘bo pa
 • Sopona omo a f’oru rin o
 • A ko le o o s’ile wa
 • A ko le sin o o s’ona wa
 • Eni Sopona lu pa
 • Ko le ba wa gbe layie
 • Eni Sopona bo pa
 • Ko le ba wa gbe o
 • K’iru re ma mase ya l’odo mi
 • K’iru re ma mase ya l’odo re
 • K’iru re ma mase ya l’odo wa
 • O d’igbo efon o d’igbo elerin o
 • O d’igbo efon o d’igbo oluwo o
 • O d’igbo olomo ko gbo’hun omo a
 • Eni Sopona lu pa
 • Ko le ba wa gbe o

 • A SI TUN SIN OPOLOPO AWON ENITI WON KU IKU ORO SINU IGBO OLUWO NA

 • O d’igba kan na (2)
 • Olojo de o pari
 • Gbogbo eda orun nki o
 • Efufulele ko gbe o de ‘le orun
 • O d’ipade o
 • Iwo eni ara lu pa
 • Ko le ba wa gbe l’ayie
 • Iwo eni Sango lu pa
 • Ko le ba wa gbe o
 • K’iru re ma mase ya l’odo mi
 • K’iru re ma mase ya l’odo re
 • K’iru re ma mase ya l’odo wa
 • O d’igbo efon o d’igbo elerin o
 • O d’igbo efon o d’igbo oluwo o
 • O d’igbo olomo ko gbo’hun omo a
 • Iwo eni ara lu pa
 • Ko le ba wa gbe o

 • NITOTO IGBO BUBURU N’IGBO OLUWO ISE

 • A ara ayie
 • Igbo buburu ni ‘gbo Oluwo ise
 • Ara mi o e gbo s’eti
 • Egberin oku, oku elese ayie ara mi o
 • Ni won mi se yalayala nibe o
 • Awon ti Sango ti pa
 • Awon ti Sopona ti bo (2)
 • O d’igbo oluwo
 • A ki igbe oku elese sinu ile
 • Igbo buburu n’igbo oluwo ise
 • Ara mi o e gbo s’eti
 • Edumare ye o Oba ‘lola
 • Ko gbe wa le’ke oni soro
 • ‘Gbat’o ba d’ojo atisun
 • K’o ri wa mase sun s’igbo
 • Igbo buburu nigbo oluwo ise
 • Ara mi o e gbo s’eti

  ACT 1 SCENE 3


 • OBA LADOSUN FI OMO RE OBINRIN TI A NPE NI ODUNAIKE FUN ARUGBO IJOYE KAN NI IYAWO O SI KO LATI FE E

 • OBA: Odunaike mi Odunaike mi
 • Mo fi o f’oko o nko ‘ko (2)
 • Mo fi o fun ‘joye o ko je gba
 • Sugbon ranti o e gbo o
 • Bi o ko lati gba ‘se mi
 • Ida mimu ti ise ;da Oba
 • Yio s’ori re ka ‘le d’eni orun
 • Odunaike o

 • AWON IJOYE SI GBE OBA LE’SE

 • AWON IJOYE: Odunaike mi Odunaike mi
 • A fi o f’oko o nko ‘ko (2)
 • A fi o fun ‘joye o ko je gba
 • Sugbon ranti o e gbo o
 • Bi o ko lati gba ‘se mi
 • Ida mimu ti ise ;da Oba
 • Yio s’ori re ka ‘le d’eni orun
 • Odunaike o

 • ODUNAIKE SI NFE LATI SE AYA OMOKUNRIN TALAKA KAN NI ILU NA

 • ODUNAIKE: A mo dupe, A mo dupe

 • ‘Tori mo ri olufe m
 • Akande mi o
 • Iwo ni mo fe. Iwo ni mo yan
 • Iwo ni mo ri, iwo ni mo gba
 • B’ewure mi ke, b’agutan mi fo
 • B’akuko adie npa mo l’eyin
 • B’orun su dede, b’ayie nlo
 • B’o ku ‘rawo kan l’oju orun
 • Iwo ni mo fe. Iwo ni mo yan
 • Iwo ni mo ri, iwo ni mo gba
 • Iwo l’o ni mi o l’ayie l’orun o
 • Akande mi o
 • Baba Ladosun ntan’ra re je
 • O fi mi f’arugbo o t’o nku lo
 • O fi mi fun ‘joye t’o nku lo
 • Ng le s’aya arugbo o
 • Iwo ni mo fe. Iwo ni mo yan
 • Iwo ni mo ri, iwo ni mo gba
 • Iwo l’o ni mi o l’ayie l’orun o
 • Akande mi o
 • AKANDE: Odunaike omo oba ) one line
 • Odunaike aya mi
 • Iwo ni mo fe. Iwo ni mo yan
 • Iwo ni mo ri, iwo ni mo gba
 • B’ewure mi ke, b’agutan mi fo
 • B’akuko adie npa mo l’eyin
 • B’orun su dede, b’ayie nlo
 • B’o ku ‘rawo kan l’oju orun
 • Iwo ni mo fe. Iwo ni mo yan
 • Iwo ni mo ri, iwo ni mo gba
 • Iwo l’o ni mi o l’ayie l’orun o
 • Iyawo mi o

 • OMO OBA ODUNAIKE ATI AKANDE ATI ORE WON KAN SI NSE IDARAYA

 • Osupa nran roro n’ibode )
 • Oluwa ayie e ma ku atijo o )4
 • E Olomo k’ilo f’omo re o )
 • K’e ma pe baba lo gbomo lo)4
 • We we we o, we we we o (2) )
 • We we we, l’a we ‘le asa ) AD. LIB
 • E gbigbo gbigbo l’a gb’osun o)
 • We we we, l’a we ‘le asa )

 • OBA LADOSUN SE ILERI LATI PA OMO RE, BI O BA KO LATI S’AYA ARUGBO IJOYE NA

 • OBA: Odunaike mi Odunaike mi
 • Mo fi o f’oko o nko ‘ko (2)
 • Mo fi o fun ‘joye o ko je gba
 • Sugbon ranti o e gbo o
 • Bi o ko lati gba ‘se mi
 • Ida mimu ti ise ;da Oba
 • Yio s’ori re ka ‘le d’eni orun
 • Odunaike o

 • AWON ENIA SI TUN GBE OBA WON L’ESE

 • AWON ENIA: Odunaike mi Odunaike mi
 • A fi o f’oko o nko ‘ko (2)
 • A fi o fun ‘joye o ko je gba
 • Sugbon ranti o e gbo o
 • Bi o ko lati gba ‘se mi
 • Ida mimu ti ise ;da Oba
 • Yio s’ori re ka ‘le d’eni orun
 • Odunaike o

 • OMO OBA NA SI FI EJO BABA RE SUN, O SI SALO KURO NI ILU NA

 • Ara ye o egbo s’eti
 • Enyin ara orun e gbo mi o (2)
 • Oba Ladosun baba mi
 • Ngb’ero lati be mi l’ori o
 • Ngb’ero lati f’ida pa mi o
 • ‘Tori mo ko lati s’aya arugbo
 • ‘Tori mo ko lati s’aya ijoye
 • Ijoye to mi ku lo s’orun
 • B’ewure mi ke, b’agutan mi fo
 • B’akuko adie npa mo l’eyin
 • B’orun su dede, b’ayie nlo
 • B’o ku ‘rawo kan l’oju orun
 • Akande mo fe. Akande mo yan
 • Akande mo ri, Akande mo gba
 • On l’o ni mi o l’ayie l’orun o
 • Akande mi o
 • A Akande mi wa wa
 • A Akande mi bow a gbo s’eti
 • E je k’a salo s’ilu okere o
 • K’a mase d’eni iku
 • E je k’a salo s’ilu okere o
 • K’a mase d’eni orun
 • K’ida mimu ti ise ‘da oba
 • Ma s’ori wa ka ’le d’eni orun
 • Akande mi o

 • SUGBON AKANDE KO JALE LATI SALO S’ILU OKERE PELU OMO OBA ODUNAIKE

 • ODUNAIKE: Odunaike mi, Odunaike mi
 • Nko le salo s’ilu okere o
 • Nko le d’eni iku
 • Nko le salo s’ilu okere o
 • Nko le d’eni orun
 • Ida mimu ti ise ‘da oba
 • Ko le s’ori mi ka ’le d’eni orun
 • Iyawo mi o

  ACT II SCENE 1


 • NITOTO IGBO BUBURU N’IGBO OLUWO ISE

 • A ara ayie
 • Igbo buburu ni ‘gbo Oluwo ise
 • Ara mi o e gbo s’eti
 • Egberin oku, oku elese ayie ara mi o
 • Ni won mi se yalayala nibe o
 • Awon ti Sango ti pa
 • Awon ti Sopona ti bo (2)
 • O d’igbo oluwo
 • A ki igbe oku elese sinu ile
 • Igbo buburu n’igbo oluwo ise
 • Ara mi o e gbo s’eti
 • Edumare ye o Oba ‘lola
 • Ko gbe wa le’ke oni soro
 • ‘Gbat’o ba d’ojo atisun
 • K’o ri wa mase sun s’igbo
 • Igbo buburu nigbo oluwo ise
 • Ara mi o e gbo s’eti

 • AWON EMI BUBURU GBOGBO TI O WA NINU IGBO OLUWO NA NSE ARIYA

 • AWON EMI: E, ko wa gb’ire o
 • Baba wa ar’owo – s’ade o
 • Ajaguna n’iwaju Olodumare
 • Pelupelu ogbegbe nle oko ore mi
 • Omo adaro-pale-aso Ore mi dara bi oja ododo
 • OLododo o mo’we o Olododo ko m’ege ye
 • K’o wa gb’ire o aworo n’isoro
 • K’o wa gb’ire eribamo o

 • AWON OLORI: S’iwaju ngo s’iwaju
 • Gbehin ngo gbehin b’omode meji
 • Nro oko won a s’epe s’ora
 • Mo je rogbo je rogbo k’ohun mi le gbo
 • Mo j’ola ‘ej’olele k’ohun mi le le
 • Mo je kukunduku olohun a ke riri
 • S’idaro re o mo pe’ri aje
 • Mo s’idaro re o
 • Mo pe’ri aje mo s’idaro re o
 • AWON EMI: S’idaro re o ye baba wa a’ro-wo s’ade
 • Ajaguna n’iwaju Olodumare
 • Pelupelu ogbegbe nle oko ore mi
 • Omo adaro-pale-aso Ore mi dara bi oja ododo
 • Olododo o mo’we o Olododo ko m’ege ye
 • S’idaro re o mo pe’ri aje
 • Mo s’idaro re o
 • Mo pe’ri aje mo s’idaro re o

 • OMO OBA ODUNAIKE RIN DE IGBO OLUWO. NIGBATI ILE SU O DUBULE O SI SUN

 • OMO OBA:- A mo de’nu igbo a mo de’nu iju
 • Okunkun su biribiri Okunkun su bile rere
 • Igbo buruku ni’igbo oluwo ise
 • Ara mi egbo s’eti
 • Eyin orisat’ oga julo
 • Eyin orisa to ga l’oke
 • K’ e sokale wa w’ omo oba
 • K’ e sokale wa weni ola o
 • A mo de nu igbo a mo de nu iju
 • Okunkun su bole rere
 • Igbo buburu nigbo oluwo ise
 • Ara mi e gbo seti

 • NITOTO IGBO BUBURU NIGBO OLUWO ISE

 • A ara aiye igbo buburu
 • Nigbo oluwo ise ara mi e gbo s’eti
 • Egberun oke oku elese aiye
 • Ara mi o ni won mi se yalayala nibe o
 • Awon ti Sango ti pa
 • Awon ti s’onpono bo
 • O d’ igbo oluwo
 • A ki igbe oku elese sinu ile
 • Igbo buburu n’ igbo oluwo ise
 • Ara mi e gbo s’eti
 • Edumare ye o oba olola
 • Ko gbe wa leke onisoro
 • Gbati’ o ba d’ ojo a ti sun
 • K’ ori wa mase sun s’ igbo
 • Igbo buburu ni igbo oluwo ise
 • Ara mi e gbo seti

  ACT II SCENE 2


 • OMO OBA NA SI LAALA BAYI PE

 • AWON EMI OKU:- B’ onigba ngbe babalawo nse (2)
 • Eni ebi npa a sai so
 • Keregbe n’ ibudo awope n’ ileo
 • Bamu bamu la yo a ko mo
 • P’ ebi np’ enikan
 • Kayokayo l’amo a ko mo
 • Ladosun l’ Oluwa
 • Keregbe n’ ibudo awope nile o
 • K’ a fi ragba ko r’agba o (2)
 • K’ atun fi won la’ kuta
 • Keregbe n’ ibudo aeope n’ ile o
 • A mo Ladosun omo Ladosun
 • Ki lo wa de bi
 • Igbo irunmale lo wo o
 • B’ o ba tile j’ omode o
 • K’ o tun pada j’ alagba o
 • Idobale l’awa nki baba
 • Omo Ladosun ko mura o
 • K’ o wi t’enu re omo Ladosun

 • OMO OBA NA SI RO EJO FUN AWON OKU NA BI ON TI SE DE IGBO

 • A mo gbo a moyo see eni sango eni ara pa
 • E ko ra yin po e ns’aye oba tororo
 • E ko ra yin po e ns’aye oba tarara
 • Nko m’ona mo wa b’ enyin wo
 • E dariji ni (2)
 • Igbo irunmale lo wo o
 • Oba Ladosun oluwa lo fe pa mi
 • ‘Tori mo ko lati wa saya arugbo
 • ‘Tori mo ko lati wa saya ijoye
 • E gba mi o ye ara mi
 • Igbo irunmale mo wo o

 • AWON OKU NA SI FI ODUNAIKE J’OBA WON

 • A eyi buru o a eyi le julo
 • K’ a fi ni foko lagbara
 • K’ a fi ni fun’ joye t’ o nr’ orun
 • Ijoye to nku lo s’ orun
 • Igbo irunmale lo wo o
 • Nje a ko raw a po
 • Awa sango pa awa ara pa
 • A fi o joye oba a fi o joye ile
 • Kabiyesi o a wole f’ oba to ga julo
 • Igbo irunmale lo wo o

 • ODUNAIKE: Rara rara rara o ma danwo
 • Enyin l’ e ti ku laiye
 • Awa si mbe laiye
 • Ara aiye ko le wa joba fun oku orun
 • Igbo irunmale mo wo o

 • AWON EMI OKU: A erin pa wa o
 • Igbo irunmale lo wo o
 • Iyen nipe o si ngbero
 • Pe o wa l’ aiye
 • Iyen nip e o ko ti mo
 • Pe o ti ku o
 • Iwo to ti ku ti a sin
 • Igb irunmale lo wo o
 • Bi o fe b’ o ko a mu o
 • A fi o j’oba
 • Bi o fe b’ o ko a mu o
 • A fi o je ‘joye
 • Kabiyesi o a ki o oba inu igbo
 • Kabiyesi o a ki oba orisa
 • Wo t’ o faiye sile lo
 • Igbo irunmole lo wo

 • AWON OKU NA SI NSE ARIYA

 • Yayo o ya yo o mai wa o e
 • Ojo soro omi ma mi jo danu o
 • Ya yo o
 • Igba mba jo onilu gbelu lo
 • Okun to ku f’ ara d’ oruka
 • Gbami gbami omokunrin soro
 • Ka le ja se a sa
 • Ya yo o (2) ma se wa o
 • Ojo soro omi ma mi jo danu o
 • ‘Ma ba won lo (2) s’iwa (2)
 • O yi biri koko
 • ‘Ma lo f’oju kan oba
 • Elenu gbagba kan gbagba (2)
 • Elenu gbagba la’kuta (2)
 • Iwa lo ju o
 • Orisa wa jo ara ya male o (2)
 • Ore se o ngbo’ hun lenu mi
 • Orisa wa jo ariya ya’male o (2)
 • Odede m’ale awo ye ka (2)
 • Ore se e ngb’ohun l’ enu mi
 • Orisa wa jo ara ya’male o
 • Adaba gb’ori igidi d’aro f’elubute
 • Aiye nyi lo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o
 • Omo oba ki iku
 • Omo oba ki isonu lo
 • Igbo irunmale lo wo o
 • Gbangba ela o (2)
 • Okuta meta elao
 • Gbangba ela o
 • A o pa’ra wa l’ayo o

  ACT III SCENE 1


 • AWON ENIA OBA LADOSUN NS’IPE FUN

 • A ewo o l’ode o la’ye
 • Oba Ladosun ewo lo de o (2)
 • Oba alade ki ronu
 • Oba inu iga ki wole
 • Oba Ladosun ewo lo de o
 • Kil’o se o o t’o nronu
 • Kil’o se o o t’okan re o bale
 • Ladosun baba awa hun
 • Oba t’o l’ayie to tun l’orun
 • O de ‘le ayie ki ile o mi
 • O m’igbo ayie kijikiji
 • Kiniun oba a bija kikan
 • Wi fun wa o k’a gbo
 • Oba alade ki ironu
 • Oba inu iga ki iwole
 • Kabiyesi awa wa ki o
 • Oba Ladosun ewolo de o

 • OBA LADOSUN SI SO IDI RE TI ON FI NRONU
 • Eyin olola eyin ijoye
 • Eyin ara mi e gbo o
 • Mo nse ‘ronu omo mi
 • Mo nse ‘daro omo mi
 • Omo to rin sonu laye o
 • Awa nwa aw o ri
 • Awa o sun awa o wo
 • Awa o mo bi t’ogbe wo o
 • Boya o wo ‘gboro lo
 • E ye e gbo ara mi
 • E ba mi wa awon ologbon ayie
 • E ba mi wa awon elese osun
 • Awon alawo mejemeje
 • Awa nwa aw o ri
 • Awa o sun awa o wo
 • Awa o mo bi t’ogbe wo o
 • Boya o wo ‘gboro lo

 • AWON ENIA SI LO PE BABALAWO KAN ATI AWOLE KAN ATI OSANYIN LATI SE IWADI IBITI OMO OBA GBA LO

 • A Oluwa ayie baba Ladosun o (2)
 • A ba o d’aro omo re
 • A ba o k’edun omo re
 • Omo t’o rin sonu l’ayie o
 • Odunaike o
 • Awa nwa awa o ri
 • Awa o sun awa o wo
 • Awa o mo bi t’ogbe wo o
 • Boya o wo ‘gboro lov
 • Oju onifa ki iwo ju
 • Ohun t’o pa mo o ko ma ma ri
 • Oju awole ki iwo oju
 • Ohun t’o sonu ko ma ma ri
 • Oju Osanyin baba okun
 • O r’ohun t’o sele ninu okun
 • O r’ohun t’o sele ninu osa o
 • O r’eni t’orin sonu l’ayie o
 • E ba mi kalo k’a p’onifa
 • E ba mi kalo k’a p’Osanyin
 • K’a tun p’awole k’o wa w’oba
 • Oba Ladosun o
 • Awa nwa awa o ri
 • Awa o sun awa o wo
 • Awa o mo bi t’ogbe wo o
 • Boya o wo ‘gboro lo

 • OBA ATI AWON ENIA RE NSE IBERE L’ODO BABALAWO
 • Orunmila gbo agboniregun
 • Orunmila gbo o ifa oba
 • Oba Ladosun nronu aiye
 • Oba Ladosun o nse ‘daro
 • Omo t’ o rin sonu l’ aiye o
 • Odunaike o
 • Awa nwa awa o ri
 • Awa o sun awa o wo
 • Awa o mo bi t’ogbe wo o
 • Boya o wo ‘gboro lo
 • Orunmila gbo agboniregun
 • Orunmila gbo o ifa oba
 • Onifa onifa awole awole
 • Jowo wa f’odu ‘fa se ‘bere
 • K’ a mo ‘bi t’ omo oba ti gba lo
 • Boya o ti ku boya o mbe laye
 • K’ a mo ‘bi t’ o ti gba lo
 • B’ o wo ‘gboro lo

 • BABALAWO SI DA IFA RE BAYI PE
 • Oyeku l’ o ni ileyile
 • Nibi gbogbo’ aiye nda ‘na iro o
 • O d’ ifa f’ eni mimo o
 • T’ a ko le pa titi lai
 • Bi a ba p’ oku ni popo o
 • Alaye ni yio f’ ohun e gbo (2)
 • Awon ‘ra won ma je ‘ra won lo
 • Apadi ni isaju ina o o
 • Awon ‘ra won ma je ‘ra won lo
 • B’ akere p’ ojo ko le ri mi
 • O d’ori ara re l’ aiye l’orun o
 • Awon ‘ra won ma je ‘ra won lo (2 )
 • Fa wi rere o ifa for ere o

 • AWON ENIA SI PE OSANYIN LATI KO ‘RIN
 • Osanyin baba onifa Osanyin baba orisa
 • Iwo t’ o m’ aiye to tun m’orun
 • K’ o ko ‘rin fun wa o ojo nlo

 • OSANYIN SI KO ‘RIN IDARAYA FUN WON BAYI PE
 • Dehin o k’ o d’ ehin (2)
 • Bi o ba d’ ehin ‘wo a d’ odo aro
 • D’ ehin o k’ o d’ ehin
 • Bo o ba d’ ehin wo a d’ odo eje o
 • Dehin o k’ o d’ ehin
 • ‘Wo a b’ egungun patako o l’ alede orun
 • Ekini gbe ‘le ijeje ijeje
 • Ekeji gbe ‘le ijeje ijeje
 • Olokose f’ara ko ewo o
 • Elulu eiye osa o
 • Kanakana mo ‘le oyo
 • Omide re ara Ikoyi
 • Ikoyi re ‘mo ‘gbe ‘mojo
 • Omo ‘gbo mo ‘jo mojo olowo
 • Eniti ko ku a se olomide
 • Soro sara se olomide
 • E olomo kilo f’omo re o
 • We, we we, o we, we we, o (2)
 • We we we l’ a wele asa
 • F’ gbigbo gbigbo l’ a gb’ osun o
 • We we we la we’ le asa

  ACT III SCENE 2


 • AWON ENIA TUN WA KI OBA NITORI OMO RE TI O SONU

 • A alade aiye a alade ile o
 • Aiye nyi lo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o
 • Esin ta ta ta o lo o lo gbere
 • Enia rin rin rin o rin o rin sonu (2)
 • Aiye nyi lo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o
 • B’ omo oba ba ku a gbo
 • B’ omo oba run a mo
 • B’ omo oba sonu lo
 • Kil’ a o ti o wi
 • B’ omo oba ba sonu lo
 • Kil’ a o ti ro
 • Aiye nyi lo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o
 • Oba alade ki ironu laiye o
 • Oba orile ki isoju idaro omo
 • Oba Ladosun a ki o
 • ‘Tori omo t’o sonu lo
 • Kil’a o ti se yi si o eyin alade
 • Kil’a o ti se yi si o eyin agbagba
 • B’omo oba ku a gbo
 • B’omo’ba arun a mo
 • B’omo ‘ba sonu lo
 • Bil’a o ti wi
 • K’omo ‘ba sonu lo
 • Kil’a o ti ro
 • Ayie nyi loo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o

 • OBA LADOSUN SI FI EJO AKANDE SUN
 • Lailai l’ayie ti d’ayie o dara o
 • Lailai l’onika mi se ‘ka ti ko gbe
 • Tibi tire l’o nrin papo loju ayie o
 • Ayie nyi lo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o
 • Akande l’o tun m’oju
 • Ohun rere ti ko se
 • Akande l’o tun m’oju
 • Ohun ika o buse
 • Ayie nyi lo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o
 • Akande nyo ‘le da ohun ibi l’ on se
 • On lo gb’odunaike t’o salo sinu igbo
 • On lo gb’odunaike t’o salo sinu ira
 • B’omo ‘ba ku a gbo
 • B’omo ‘ba run a mo
 • B’omo ‘ba sonu lo
 • Ki l’a o ti wi
 • B’omo ‘ba sonu lo
 • Ki la o ti ro
 • Ayie nyi loo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o
 • E lo m’akande wa
 • E lo m’akande bo
 • E ba mi gb’okun t’o le
 • K’e wa de Akande l’okun
 • K’oju re ran ‘ko
 • B’ojo nfe ro ko ro
 • K’o p’Akande o
 • B’orun nfe ran ko ran
 • K’o p’Akande o
 • Lailai l’ayie ti d’ayie o dara o
 • Lailai l’onika mi se ‘ka ti ko gbe
 • Tibi tire l’o nrin papo loju ayie o
 • Ayie nyi lo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o

 • AWON ENIA SI LO MU AKANDE WA FUN IDAJO
 • Lailai l’ayie ti d’ayie o dara o
 • Lailai l’onika mi se ‘ka ti ko gbe
 • Tibi tire l’o nrin papo loju ayie o
 • Ayie nyi lo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o
 • Akande l’o tun m’oju
 • Ohun rere ti ko se
 • Akande l’o tun m’oju
 • Ohun ika o buse
 • Ayie nyi lo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o
 • Akande nyo ‘le da ohun ibi l’ on se
 • On lo gb’odunaike t’o salo sinu igbo
 • On lo gb’odunaike t’o salo sinu ira
 • B’omo ‘ba ku a gbo
 • B’omo ‘ba run a mo
 • B’omo ‘ba sonu lo
 • Ki l’a o ti wi
 • B’omo ‘ba sonu lo
 • Ki la o ti ro
 • Ayie nyi loo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o
 • Oba Ladosun oluwa o wi ‘re o
 • E lo m’akande wa
 • E lo m’akande bo
 • E ba mi gb’okun t’o le
 • K’e wa de Akande l’okun
 • K’oju re ran ‘ko
 • B’ojo nfe ro ko ro
 • K’o p’Akande o
 • B’orun nfe ran ko ran
 • K’o p’Akande o
 • Lailai l’ayie ti d’ayie o dara o
 • Lailai l’onika mi se ‘ka ti ko gbe
 • Tibi tire l’o nrin papo loju ayie o
 • Ayie nyi lo bi ogo
 • Enia mi lo bi osa o

 • AWON ENIA BERE ORO LOWO AKANDE
 • A! Akande yi o
 • A! wa wi t’enu re o (2)
 • Nibo l’omo oba ti gba lo
 • Wa wi t’enu re
 • Nibo l’omo oba ti gba lo
 • Wa wi eyi t’o mo
 • A! Akande yi o
 • A! wa wi t’enu re

 • AKANDE SI BURA PE ON KO MO NIPA IBITI OMO OBA SALO
 • E ye e gbo ara mi
 • Bi mo mo’ bi t’omo oba gba lo
 • Ki Sango pa mi
 • Bi mo mo’ bi t’omo oba gba lo
 • K’arun gbe mi de o
 • Ng ko mo’ bi t’omo oba gba lo
 • E ye E ma de mi l’okun o

 • AWON ENIA NA SI DE AKANDE L’OKUN
 • Akande nsokun oro o dara
 • Akande njoro okun (2)
 • Igun orun k’o wa
 • Akala orun k’o wa
 • K’e wa yo ‘ju ape’ re je
 • Akande mi nj’oro okun
 • Akande nj’oro okun
 • O gb’oju l’ogun
 • Akande nj’oro okun
 • Oju re a yo
 • Akande nj’oro okun
 • Gbangba ela o (2)
 • Okuta meta ela o
 • Gbangba ela o

  ACT III SCENE 3


 • OMO OBA ODUNAIKE PADA BO SI ILE AWON ENIA SI NDUPE LOWO BABALAWO
 • Lolalola oluwa ye o a adupe
 • Lolalola Oluwa ye o a yo sese
 • Babalawo mi bo wa gb’ifa o omo rere
 • Oju alawo ki iwo ‘fa ko ma ri
 • Oju awole ki iwo obi ko ma yan
 • Oju osanyin ki iwoju ona ko ma lo
 • Babalawo mi bo wa gb’ifa o omo rere
 • Oba alade ki ironu l’ayie o
 • Oba iga ki isoju idaro omo
 • Oju alawo ki iwo ‘fa ko ma ri
 • Oju awole ki iwo obi ko ma yan
 • Oju osanyin ki iwoju ona ko ma lo
 • Babalawo mi bo wa gb’ifa o omo rere
 • Awa ba o yo a ba o je lojo oni o
 • Omo oba t’o sonu lo
 • Igbo Irunmale lo re o
 • B’omo oba ku a gbo
 • B’omo oba saisan a mo
 • Eyi si ye wa
 • Sugbon enu kil’a o fir o
 • P’omo oba sonu lo
 • Omo oba t’o sonu lo
 • Igbo irunmake lo re o
 • Omo oba ki iku
 • Omo oba ki irun
 • Omo oba ki i sonu lo
 • Igbo irunmale lo re o

 • OBA LADOSUN NYO AYO OMO RE TI O PADA BO
 • OBA: Enyin olola eyin agbagba
 • Eyin oselu eyin igbimo
 • Mo dupe lowo yin enyin enia gbogbo
 • Omo oba t’o sonu lo
 • Igbo irunmale lo re o
 • Omo oba ki iku
 • Omo oba ki irun
 • Omo oba ki i sonu lo
 • Igbo irunmale lo re o
 • B’omo oba ku a gbo
 • B’omo oba saisan a mo
 • Eyi si ye wa
 • Sugbon enu kil’a o fi ro
 • P’omo oba sonu lo
 • Omo oba t’o sonu lo
 • Igbo irunmale lo re o
 • Oju alawo ki iwo ‘fa ko ma ri
 • Oju awole ki iwo ‘le ko ma yan
 • Oju osanyin ki iwoju ona ko ma lo
 • OMo oba t’o sonu lo
 • Igbo irunmale lo re o

 • AWON ENIA SI NKI OMO OBA ‘KU ABO
 • AWON ENIA: E ku a bo omo oba
 • Omo oba t’o f’ile s’ile
 • T’o tun wo ‘gbo lo
 • Omo oba t’o f’iga s’ile
 • T’o tun wo ‘gbo lo
 • ‘Gba t’o de inu igbo
 • O para da o r’orun
 • O ba awon oku so’ro
 • O ba awon oku jeun
 • Igbo irunmale lo re o
 • Awon sango pa awon ara pa
 • Won ko ‘ra won po
 • Won mi se ayie oba tororo
 • Won ko ‘ra won po
 • Won mi s’ayie oba tarara
 • Omo oba t’o sonu lo
 • Igbo irunmale lo re o

 • OMO OBA: E ku ile o E ku ile o
 • Mo ki enyin agbagba
 • Mo ki enyin oselu o
 • Emi eni t’o sonu lo
 • Igbo irunmale mo re o
 • ‘Gba mo de inu igbo
 • Mo para da mo r’orun
 • Mo ba awon oku so’ro
 • M ba awon oku jeun
 • Awon Sango pa awon ara pa
 • Igbo irunmale lo re o
 • B’omo oba ku a gbo
 • B’omo oba saisan a mo
 • Eyi si ye wa
 • Sugbon enu kil’a o fi ro
 • P’omo oba sonu lo
 • Igbo irunmale mo re o
 • Omo oba ko ni ku
 • Omo oba ko ni run
 • Omo oba ko ni sonu lo
 • Igbo irunmale lo re o

 • AWON ENIA: E ku a bo omo oba, E ku abo omo oba
 • Omo oba t’o f’ile s’ile
 • T’o tun wo ‘gbo lo
 • Omo oba t’o f’iga s’ile
 • T’o tun wo ‘gbo lo
 • ‘Gba t’o de inu igbo
 • O para da o r’orun
 • O ba awon oku so’ro
 • O ba awon oku jeun
 • Igbo irunmale lo re o
 • Awon sango pa awon ara pa
 • Won ko ‘ra won po
 • Won mi se ayie oba tororo
 • Won ko ‘ra won po
 • Won mi s’ayie oba tarara
 • Omo oba t’o sonu lo
 • Igbo irunmale lo re o

 • OBA SI P’ASE KI A TU AKANDE SILE KI A SI FI OMO OBA FUN U NI IYAWO OBA:
 • E lo m’ Akande wa
 • E lo m’ Akande bo
 • E tu u l’ okun k’ o gbe’ ra
 • K’ o wa pada f’ omo oba
 • Omo oba t’ o sonu lo
 • Igbo irunmale l’o re o

 • AWON ENIA E lo m’ Akand wa
 • E lo m’ Akande bo owun
 • E tu u l’ okun k’ o gbera
 • K’ owa pada f’ omo oba
 • Omo oba t’ o sonu lo
 • Igbo irunmale l’ o o re o

 • A TU AKANDE SILE O SI KO ‘RIN OPE

 • AKANDE ;- Mo dupe l’owo yin
 • Enyin enia gbogbo
 • Mo dupe l’owo re oba Ladosun o
 • Ori buruku k ii gb ogun odun laiye o
 • Ori Akande tun wa d’ ana oba o
 • Eni t ‘ a ti gab l’eti
 • O tun pada f’omo oba
 • Enit’ a ti de l’okun
 • O tun pada f’omo oba
 • Ori buruku k ii gb’ogun odun laiye o
 • Ori Akande tun wa d ‘ ana oba o
 • Omo oba ko n ii ku
 • Omo oba ko ni run
 • Omo oba ko ni sonu lo
 • Igbo irumale l’o re o

 • AWON ENIA;- Ori buruku k ii gb’ ogunodun laiye o
 • Ori Akande tun wa d’ ana oba o
 • E nit’ a ti gba l’ eti
 • O tun pada f’ omo oba
 • Enit ‘ a ti a de l’okun
 • O tun pada f’ omo oba
 • Omo oba ko n ii ku
 • Omo oba ko ni run
 • Omo oba ko ni sonu lo
 • Igbo irumale l’o re o

 • AWON ENIA ILU NA SI NSE ARIYA
 • NITI OMO OBA TI O SONU LO TI O
 • SI TUN PADA BO

 • Dajudaju o baba saki oba aiye
 • Edumare fun wa l’omo
 • Ti yio gb’ ehin t ‘ ehin se (2)
 • Eni omo sin l ‘ o bimo o
 • Omo l ‘ ayole o (2)
 • Igba a ba ti ri ra wa se o
 • K’ a ma se d’ aro o l’aiye yi o
 • Omo oba ko n ii ku
 • Omo oba ko ni run
 • Omo oba ko ni sonu lo
 • Igbo irumale l’o re o

 • THE END
 • ALL RIGHTS RESERVED