Herbert Macaulay


  ORIN AKOBERE


 • Araiye e wa
 • Eyin to nwoju baba Macaulay
 • Gbato njagun nile aiye o
 • Angeli e bo
 • Enyin to ngbemi baba Macaulay
 • To nkorin lorun a (2)
 • Omi okun wa
 • Omi osa gberanle o
 • Igi egba igi’ re
 • Lekeleke eiye ola o
 • Olodumare baba wa
 • B’oju wo’ se owo re
 • Ojo mi lo ya ya (2)
 • Enia jeje ri a bi sile aiye
 • A ri wahala aiye
 • Ye rekerudo ile o
 • Awon amoniseni aseni banidaro
 • Ore aiye ko ni itunmo o
 • A f’Olugbala
 • Olodumare baba wa
 • B’oju wa’ se owo re
 • Ojo mi lo ya ya
 • Macaulay ta bi to mi jaiye oba tororo
 • Macaulay ta bi to mi jaiye oba torara
 • Baba ologbon aiye
 • Baba to mowe jinlejinle
 • A gboju soke si o olore o
 • Aiye Eko dowo re loni o
 • Olola Macaulay o
 • Iwe irohin re o
 • Ko fi jagun f’alaini baba
 • Macaulay o se o olore o
 • Gbati o ba gbo to rele
 • Alade ki iku
 • Gbati oba waja ile
 • Oba ki irorun
 • Osika aiye
 • Awon igbimo ile
 • Won sin Akitoye topatopa o laiye
 • Opa wonu iboji
 • O tun pada sile aiye o
 • Macaulay ope ope ope
 • Macaulay ope loni o eni rere
 • Opa adehun lo nile o

 • CHORUS:- Lolalola Oluwaiye o adupe
 • Lolalola Oluwa a o yo sese
 • Apapa wa dile ola o oba to d’ade owo eya
 • T’ oyinbo wa rele Oyo o
 • A dupe dupe Oluwaiye o Edumare gbowo
 • Omo araiye binu awon osika [wa o
 • Won wa o rele Oyo o
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wa po
 • Abinu eni ko ma le
 • Pa kadara wad a
 • Ijapa to komogbon aiye
 • Sinu agbe o
 • To ni ogbon aiye ma tan o
 • Gbato ku dede soke
 • O gbo pe ogbon ku laiye o
 • Gbati won rope a sun
 • A o sun ogbon nbogbon ja loru
 • A dupe lowo re baba Macaulay p
 • Bi o ba nse rere ko mura sire
 • Bi o ba nse ka ko mura si ika o
 • Oju a ti baba to jogun omo
 • Oju a ti egbon to jogun aburo
 • Eni to ba puro a lodufe o
 • Eni ba s’otito ko d’esin re kale o
 • Ogba ewon ki se iku o ti o
 • Ogba ewon ki is’arun o ti o
 • Macaulay lo tori ilu wewon aiye o
 • Oku orun a file re’ se’ ranti o
 • E o yi o Macaulay a dehin bo o
 • B’ina ba mi darugbo
 • A feruru sode
 • B’ogede ba mi darugbo a fomo ropo o
 • Macaulay ko ku laiye o
 • Pipa lo parade o
 • Omo araiye e ma ronu o
 • Macaulay a dehin bo o
 • E agbe lo nile aro o dara
 • Aluko lo nile osun baba
 • Lekeleke elese ogere eiye lorokun
 • Macaulay lo nile Eko o
 • Ki baba to parade o
 • Omo aiye e ma ronu o
 • Macaulay a dehin bo o

  ACT 1 SCENE 1


 • A BI HERBERT MACAULAY SI ODE AIYE AWON
 • ENIA SI NKI BABA RE ALUFA THOMAS ATI
 • IYA RE ABIGAIL KU EWU OMO

 • Ojo ndojo ale o
 • Orun nrora sibi iwo o
 • Olodumare Oluwa wa
 • Oba to laiye to yun l’orun
 • Ko gbagbe eda kan soju aiye o
 • Baba Thomas o
 • A Abigaili awa ki o e ku ewu enia
 • A Thomas a wa ki o e ku ewu enia o
 • Eyin to fi bi mimi se le e ku ewu
 • Enyin to nsise Jesu o e ku ewu o
 • Ebi Alufa lo parapo
 • Te bimo Olorun soju aiye o
 • Omo ekeje Edumare
 • T’Oluwa fun nyin lojo aiye
 • Baba Thomasi o
 • Kabo o mawole o omo iye
 • Kabo o mawole omo awa
 • Ere o ema wo o yi lo o eya wa wo
 • Omo titun to wo nu aiye
 • Omo titun to wole yi o
 • Ye ye o e ma wo o yi lo e yaw a wo
 • Samuel Heelas o Herbert a Macaulay o
 • Iwo to njise Oluwa wa e ku ewu o
 • Omo iranse Oluwa e ku ewu o
 • Ebi Alufa lo parapo
 • Te bimo Olorun soju aiye
 • Baba Thomasi o

 • ABIGAIL:- Ope ope mo dupe
 • Ayo ayo mo yo sese
 • Ojo ndojo ojo ale o
 • Orun nrora sibi iwo o
 • Olodumare Oluwa wa
 • Oba to laiye to laiye
 • To tun lorun ko gbagbe eda kan soju aiye
 • Ere o e ma wo O yi lo e yaw a wo
 • Samuel Heelas o Herbert a Macaulay o
 • Gbogbo ire ti mbe laiye
 • Gbogbo ire ti mbe loke
 • Ko kari gbogbo wa lojo oni o
 • E ku ewu irun ajo o

 • AWON ENIA:- Ye ye o e ku ewu enia o
 • A Abigaili ita omo
 • Omo Bisopu Crowther o
 • Ati Thomasi baba omo
 • Omo ojo oriare
 • Ara Ikirun nilu oke
 • Ikirun omo a f’odo jeun
 • Ikirun omo a f’odo sebe
 • Ikirun lo n’ ile Oyo o
 • Ere o e ma wo o yi lo e ya wa wo
 • Omo titun to wo nu aiye
 • Omo titun to wole yi o
 • Ye ye e ma wo o yi lo e ya wa wo
 • Samuel Heelas o
 • Herbert Macaulay o Ebi Alufa lo parapo
 • Te bimo Olorun s’oju aiye o
 • Gbogbo ire ti mbe l’aiye
 • Gbogbo ire ti mbe l’oke
 • Ko kari gbogbo wa lojo aiye o
 • E ku ewu enia o

 • THOMAS:- Ope ope mo dupe
 • Ayo ayo mo yo sese
 • Emi Thomasi baba omo
 • At’ Abigaili yeye omo
 • Awa to fibi mimo sele
 • Awa to file Jesu s’ogba
 • Ebi Alufa lo parapo
 • Ta bimo Olorun soju aiye o
 • Gbogbo ire to nbe laiye
 • Gbogbo ire tinbe loke
 • Ko kari gbogbo wa lojo oni
 • Eku ewu irin ajo

 • AWON ENIA:- Ye ye ye o – Eku ewu enia o
 • A Abigaili iya omo
 • Omo Bishopu Crowther o
 • Ati Thomas baba omo
 • Omo Ojo Oriare
 • Ara Ikirun ni’lu oke
 • Ikirun omo a f’odo jeun
 • Ikirun omo a f’odo sebe
 • Ikirun lo n’ile Oyo o
 • Ire o o ma wo ete
 • Omo lere aiye o omo lere (2)
 • Oba Oluwaiye ko fun mi
 • Lomo temi omo lere
 • Aiye o omo lere
 • Aiye o Omo lere
 • A o omo lere
 • E igbo nla o mbe
 • Lehin edun edun mi se suwasuwa
 • Oba Oluwaiye o mbe lehin
 • Awa awa reni fehin ti o
 • Iyere o igi ire o
 • Jehova gba wa o eni re Iyere o
 • Iwo la o fehin ti o Igi re o
 • Jesu gba wa o omi a wa Awa reni
 • Iwo la o fehin ti o Fehin ti
 • Jowo o laiye lorun o
 • Iwo la o fehin ti o

  ACT 1 SCENE 2


 • OGBENI HERBERT MAUCAULAY JE OLORIN, OLOHUN IYO, AFUN-FERE ATI O
 • OSELU; O SI TUN JE ALAGBARA ONI-WE IROHIN NI ILU EKO. GBOGBO
 • AWON ENIA ILU FERAN RE. WON SI NBU OLA FUN U

 • AWON ENIA:- Iba laiye o baba Macaulay (2)
 • Ara aiye nwoju re ye o baba olore
 • Ijoba mi woju re won ndorikodo
 • E fi olola f’olola
 • Tori baba lo nile o
 • Kiniun onibudo o
 • Labalaba o ko le badan fo
 • Adan fo lele, ojo mi lo yaya
 • Oba ekun l’olu igbo o yi o
 • Ekinrin loba odan baba
 • Macaulay ko dade o njoba nile Eko o
 • Ojo mi lo ya ya
 • E fi ola f’olola
 • Tori baba lo nile o
 • Kiniun onibudo o
 • Labalaba kole b’adan fo
 • Adan fo lele
 • Ojo ni lo ya ya
 • E agbe lo n’ile aro o dara
 • Aluko lo nile osun baba
 • Lekeleke elese ogere eiye lor’ okun
 • Makoli lo nile Eko e ya
 • Ojo mi lo yaya

 • MAKOLI:- Enyin olola enyin ijoye
 • Enyin oselu enyin igbimo
 • Enyin oloja Eko o e ku ibewo
 • Rere rere l’Oluwao Jesu
 • E fi ola folola o
 • Tori baba lo nile o
 • Kiniun onibudo o
 • Labalaba kole b’adan fo
 • Adan fo lele ojo mi lo yaya
 • Nje enyin o selu
 • Enyin oniwe irohin
 • Ti mbe labe mi o
 • Mo dupe lowo nyin
 • Mo dupe tokantokan
 • E fi ola folola o
 • Tori baba lo nile o
 • Kiniun onibudo o
 • Labalaba o ko le badan fo
 • Adan fo lele
 • Ojo mi lo yaya

 • AWON ENIA:- Macaulay o se o olore o (2)
 • Ara aiye nwoju re ye o baba olore
 • Ijoba mi nwoju re won ndorikodo
 • Efi olola folola o
 • Tori baba lo nile o
 • Kiniun onibudo o
 • Labalaba ko badan fo
 • Adan fo lele
 • Ojo mi lo yaya
 • Awa olola a fi o se baba
 • Awa ijoye a fi o se baba
 • Awa oloja obirin ami wo o o
 • Awa oniwe irohin a gboju soke si o
 • Iwo ologbon aiye iwo to mowe jinlejinle
 • A gboju soke si o olore aiye Eko dowo re
 • Olola Makoli o [loni o
 • Iwe irohin re o ko fi jagun falaini baba
 • Makoli o se o olore o korin fun wa o (2)
 • Iwo olohun iyo iwo olohun orin
 • Baba wa ye a fe sariya ojo mi lo ya ya

 • MAKOLI:- Lebute lebute lebute ilu Eko
 • Olola la je o olola la je o omo onile ni se le o
 • Ajeji o selu o e gbo o boba selu ka mu borisa
 • Orisa lokun orisa losa orisa baba ti mbe lorun
 • Kamuro Kamuro Kamuro ‘lu okun
 • Ye l’ebute lebute lebute ilu Eko
 • Awa yio ma yo omi okun alade ori
 • Omi osa olori odo
 • Igi egba jowo reanti mi igi ire
 • Igi egba jowo ranti mi sir ere o
 • Lebute lebute lebute ilu Eko
 • Olola la je o olola la je o omo onile ni se le
 • Ajeji o selu o egbo o bo ba selu la mu borisa
 • Orisa lokun orisa losa orisa baba ti mbe loru
 • Kamuro Kamuro Kamuro okun
 • Ye lebute lebute lebute ilu Eko awa a ma yo
 • Goke aiye, gbe mi soke aiye (2)
 • Gbe mi gbe mi s’ola o
 • Gbe mi gbe mi s’ola ori okun
 • Ye o f’okun we ko s’omi ta le f’okun we
 • F’osa we ko s’omi ta le f’osa we
 • F’ Eko we ko sibi ta
 • Eko ro ni laso Eko wo ni lewu
 • Eko fun ni lola o Eko fun ni lola
 • Eko somo alakisa o tun dalas o F’ Eko we

  ACT 1 SCENE 3


 • Awon Oyinbo gba ile Apapa Oba Oluwa si so fun Ogbeni Makoli
 • lehin Idajo ni Eko. Nwon mura lati gbe ejo kotemilorun
 • si ile lo si ile ejo to ga julo ni ilu Oyinbo

 • AWON ENIA:- A ara aiye baba Makoli o (2)

 • OLOYE OLUWA:- Ore Makoli mo wa ri o
 • Mo ni ejo kan lati fi sun niti ese kan to ga ju o
 • Ninu ijoba ti ise t’ emi emi Oluwa oba
 • Emi Oluwa oba ijoye ile Apapa tiletile olowo
 • Ile Apapa togbatogba titi lo dokun titi lo osa
 • Temi Oluwa baba ni ise omo onile ni se le
 • Ajeji o selu o l’Eko o araiye e gbo o
 • Awon oyinbo olowo aiye ati awon ti nsowo
 • Ijoba oyinbo to ni wa won gbale Apapa tiletile
 • Wom gbale Apapa togbatogba
 • Lai san owo kobo lori won Hun …
 • Makoli ye gba mi o mo kepe o o
 • Gba mi lowo awon ajeji,
 • Gbami lowo awon adelumalo
 • Ti ngba onile tipatipa ti ngbale onile tijatija
 • To tun f’ okunkun lile bow a loju
 • Edumare ko gbeja lorun aiye ndorikodo loile
 • Mo lo si ile ejo won le mi sa
 • Nibi ole gbe mi jare oniun
 • Eke lo rojo ika lo gba ro
 • Ijoba to gba le ‘o tun dajo o
 • Gba mi lowo awon ajeji
 • Gba mi lowo awon adelumalo
 • Ti ngbale onile tipatipa ti ngbale onile tijatija
 • Ti won f’ okunkun lile bow a loju
 • Edumare ko gbeja lorun aiye ndorikodo lo
 • AWON ENIA:- Oba Oluwa oba olowo
 • Oba Oluwa Oba ijoye Ile Apapa tile
 • Ile Apapa togbatogba titi lo dokun titi lo osa
 • Toba Oluwa baba ni se omo onile ni se le
 • Ajeji o se lu l’Eko o araiye e gbo o
 • Awon oyinbo olowo aiye ati awon ti nsowo po
 • Ijoba oyinbo to ni wa o
 • Won gba le Apapa tile tile
 • Won gba le Apapa togbatogba
 • Lai san owo kobo lori won Hun …………..
 • Macaulay ye gba wa o a kepe o o
 • Gba wa lowo awon ajeji
 • Gba wa lowo awon adelumalo
 • T ngba’ le onile tipatipa
 • Ti ngba’ le onile tijatija
 • To tun f’okunkun lile bow a loju o
 • Edumare ko gbeja l’ orun
 • Aiye ndorikodo lo a lo sile ejo won le wa a
 • Nibi ole gbe mi jare oniun
 • Eke lo rojo ika lo gba’ ro
 • Ijoba to ngba’ le lo tun dajo o
 • Gba wa lowo awon ajeji
 • Gba wa lowo awon adelumalo o
 • Ti ngbale onile tipatipa ti ngbale onile tijatija
 • To tun f’okunkun lile bow a loju
 • Edumare ko gbeja lorun aiye ndororikodo lo

 • AWON ENIA:- Macaulay o se o olore o
 • Adupe dupe lowo re olore o
 • Ilu oyinbo la nlo o Pelu oba wa Pataki
 • Ati iwo ologbon ogbon aiye, iwo to mo’ we jinle jinle
 • Ka p’awon oyinbo ologbon aiye
 • Ati awon ti nsowo po, si ile ejo to ga ju lo
 • Ilu oyinbo ki ise gbe ilu oyinbo ki isetan
 • Ijoba to gba ‘le ko ni dajo o omo oni le nise
 • Ajeji o selu l’Eko o, araiye egbo o

 • OLOYE OLUWA:- Duro duro duro Makoli duro
 • Ronu ronu jinle o, Eshugbayi oba wa
 • Ko ni le lo o, a mo ranti (2)
 • Opa adehun t’ oba wa boyinbo se
 • O mbe ninu ibi to jin
 • Ninu iboju oba awa Akitoye oba agba
 • Oba alade ki irorun Hnn …………..

 • AWON ENIA:- A o se o se o po
 • Opa adehun toba wa b’oyinbo se
 • O mbe ninu ibi to jin ninu iboji oba wa
 • Akitoye oba agba awon igbimo oba aiye
 • Awon igbimo oba ika won sin Akitoye topa topa o
 • Opa adehun t’oba wa boyinbo se
 • O mbe ninu ibi to jin a ba le reni ti nlosorun
 • Ko ba Akitoye oba soro
 • Ko gbopa adehun bo saiye Omo onile ni sile
 • Ajeji o selu o l’Eko o Araiye e gbo o

 • MACAULAY:- A e ma ma daro aiye
 • A e ma ma rahun aiye
 • Opa adehun ko si ninu iboji
 • Araiye e gbo o (2) Opa adehun nbe lowo mi
 • E ma ma rahun aiye

 • Inu awon enia si dun lati ripe opa adehun na si wa lori ile
 • aiye nwon si dupe lowo Ogbeni Herbert Macaulay

 • AWON ENIA:- a ose ose ose
 • Macaulay ose loni o eni rere
 • Opa adehun lo nile o A ope ope ope ope
 • Macaulay ope loni o eni rere
 • Opa adehun lo nile o
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wa po
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wad a
 • Macaulay ope ope ope
 • Macaulay ope loni o eni rere
 • Opa adehun lo nile o
 • Macaulay A egbo egbo egbo Araiye e loni o eni rere
 • T’ oba wa b’ oyinbo se
 • Gbati oba gbo to rele (alade ki iku)
 • Gbati Akitoye wa w’ aja (oba ki irorun)
 • Awon osika aiye awon igbimo ika
 • Won sin Akintoye topatopa o laiye
 • Opa wonu iboji o tun pada sile aiye o
 • Araiye e gbo loni o eni rere
 • Opa adehun lo nile o
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wa po
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wa da
 • Ijapa to ko ogbon aiye sinu agbe o
 • To ni ogbon aiye ma tan o
 • Gbato ku dede soke
 • O gbo pe ogbon ku kaiye gbati won rope a sun
 • A o sun ogbon nbogbon ja l’ oru
 • Macaulay ope loni o omo rere
 • Opa adehun lo nile o
 • Awon enia A ope ope ope
 • Macaulay ope loni o omo rere
 • Opa adehun lo nile o
 • Eyi l’ opa adehun
 • T’ oba wa b’ oyinbo se
 • Gbati oba gbo to rele (alade ki kiu)
 • Gbati oba w’ aja ile (oba ki irorun)
 • Awon osika aiye awon igbimo ika
 • Won sin Akitoye topatopa o laiye
 • Oba wonu iboji o tun pada sile aiye o
 • Macaulay ope ope ope
 • Macaulay ope loni o omo rere
 • Opa adehun lo nile o
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wa po
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wa da
 • Ijapa to ko ogbon aiye sinu agbe o
 • To ni ogbon aiye ma tan o
 • Gbato ku dede soke
 • O gbo pe ogbon ku kaiye gbati won rope a sun
 • A o sun ogbon nbogbon ja l’ oru
 • Macaulay ope loni o omo rere
 • Opa adehun lo nile o

 • Oloye Oluwa ati Ogbeni Macaulay mura lati lo se ejo Apapa ni ilu oyinbo,
 • won si fi Opa adehun na ran ore kan siwaju won lo si odo Agbejoro won ni
 • ilu Oyinbo

 • ORE:- A e ku ale e ku ale o
 • Baba Macaulay oo
 • Mo wa dagbere ikehin fun iwo ore ti moni o
 • Ilu oyinbo mo nlo o
 • Ile baba to bi mi lomo Baba Macaulay o
 • O d’ odun mefa ti mo ti de ‘le yi o
 • Araiye e gbo o
 • Mo sise sise mo nrele
 • Ile baba to bi mi lomo
 • M wa dagbere ikehin
 • Fun iwo ore ti mo ni o
 • Ilu oyinbo mo nlo o
 • Ile Baba to bi mi lomo
 • Baba Macaulay o

 • MACAULAY:- Duro duro na

 • Duro o ko gbo s’eti
 • Mo ni ise kan Pataki
 • Lati an sibi ti o nlo
 • Ore to mo ni ma ma dale
 • Eni ba dale a ba’ le lo a o
 • Ala ti aja la inu aja ni ngbe
 • Eda kan o m’ehin ola
 • Owo a te’mo n’imo isun
 • Ore ti mo ni ma ma da’le lo a o

 • ORE:- Isekise to wu ko le kan
 • S’enikan nile ti mo nlo
 • Mo ti wa ma jise ti o ran mi
 • Ala ti aja la inu aja ni ngbe
 • Eda kan o m’ehin ola
 • Owo atemo ni imo isun
 • Ore bad a ‘le a ba ‘le lo o
 • Baba Macaulay

 • MACAULAY:- Gba gba gba
 • Ko fi pamo sinu eru
 • Si inu eru ti o ni o
 • Gbato ba dele re gbo o
 • Ko fun agbejoro ti mo wi o
 • Ore ti mo ni ma ma da ‘le o
 • Eni bad a ‘le a ba ‘le lo o

 • ORE:- O digba ara e gbo (2)
 • Ki Oluwa ma k’atunri o
 • Ala ti aja la inu aja ni ngbe
 • Eda kan o m’ehin ola
 • Owo atemo ni imo isun
 • Ore bad a ‘le a ba ‘le lo o
 • Eni bad a ‘le a ba ‘le lo o

 • AWON ERO ILU OYINBO:-

 • O digba ara e gbo (2)
 • Ki Oluwa ma k’ atunri o
 • Baba Macaulay o
 • Ilu Oyinbo la nlo o
 • Pelu oba wa pataki
 • Ka p’awon oyinbo ologbon aiye
 • Ati awon to nsowo po
 • Sile ejo to ga julo
 • Ilu oyinbo ki isegbe
 • Ilu oyinbo ki isetan
 • Ijoba to gba ‘le ‘ko ni dajo o
 • Omo onile ni ise ‘le oto rele (Alade ki iku)
 • Ajeji o selu o l’Eko o
 • Araiye e gbo o

  ACT II SCENE 1


 • Esugbayi Eleko Ninu Iga Re, Awon Enia Nbu Ola Fun u

 • Ijoba Si Nfe Ki Eleko Ranse Gba Opa Adeun Pada Lati Owo Oloye
 • Oluwa Ati Macaulay. Ni Ilu Oyinbo Eshugbayi Si Ko Jale

 • AWON ENIA:- Iba Eshugbayi Oba wa toto aro
 • Iba Eshugbayi Oba wa n’ole Eko
 • Ade ape lori oba wa l’aiye
 • Ileke ape l’orun oba oba Pataki
 • Eshugbayi iwo l’Oluwa
 • Ye ye ya iwo lo nile Eko
 • Oba iga oba iga oba iga l’aiye
 • Oba iga oba iga oba iga lode
 • Dajudaju o (2)
 • Iwo l’Oluwa
 • Ye ye ya iwo lo ni Eko
 • Oba Akitoye lo j’aiye rere
 • Gbati oba gbo to rele (Alade ki iku)
 • Gbati oba w’aja ile (Oba ki irorun)
 • Eshugbayi o gori oye Docemo baba re
 • Ye ye ya iwo lo nile Eleko
 • Enia lo nile aiye o dara
 • Angeli lo nile loke baba
 • Eshugbayi iwo l’Oluwa
 • Ye ye ya iwo lo nile Eleko
 • Eshugbayi mo gbo mo gbo seti
 • A mo yo mo yo mo po sese
 • Ara aiye emi l’Oluwa
 • Yo ye ye emi lo nile Eko
 • Oba nla Akintoye lo j’aiye rere
 • Gbati oba gbo to rele (Alade ki iku)
 • Gbati oba w’aja ile (Oba ki irorun)
 • Eshugbayi o gori oye Docemo baba re
 • Ye ye ya iwo lo nile Eleko
 • Opa Adehun ile i baba b’oyinbo se
 • La fi nrojo ejo aiye nile oba
 • La fi nrojo ejo nile baba wa
 • Ile Apapa o tiwa ni
 • Yeye ya emi lo nile Eko
 • Enia lo nile aiye o dara
 • Angeli lo nile loke baba
 • Eshugbayi iwo l’Oluwa
 • Ye ye ya emi lo nile Eko
 • Olopa gbo gbo gbo Esshugbayi gbo
 • Ko gbo ko gbo ko gbo
 • Eshugbayi gbo
 • Opa adehun oba oba wa Pataki
 • Ti o fi ran Oluwa oba to lo sile ajo
 • Ti o fi ran Macaulay to lo sibi igbimo
 • Oti lo d’ija sile ni ilu oyinbo o
 • Rukerudo de’le re
 • Yeye ya iwo a tun pada d’eru
 • Ko gbo ko gbo ko gbo
 • Esugbayi gbo
 • Kiakia si l’agogo ko pe gbogbo enia
 • Ko ranse si Oluwa oba to nbe nile ejo
 • Ko ranse ko pe Macaulay nile Igbimo
 • Ko ranse ko gb’opa adehun
 • Ti won fi nrojo
 • Ko ranse ko gb’opa adeun o nibi igbimo
 • Ko so pe iwo ko lo ran won
 • Rukerudo de’le re
 • Ye ye ya iwo a tun pada deru
 • Esugbayi A ko gbo ko gbo ko gbo
 • A ko gba ko gba ko gba, dandan
 • Opa adeun ile ti baba b’oyinbo se
 • Ti Oluwa ati Macaulay ti won fi nrojo
 • Ti won fi mi rojo ile baba wa
 • Loto emi lo ran won
 • Ye ye ya emi lo nile Eko
 • Ohunkohun to wu ko le se nidi oro yi o
 • A mo ti wa mo ti wa kenken
 • Mo ti wa bi ewa
 • Ara e-gbo mi emi l’Oluwa
 • Ye ye ya emi lo nile Eko
 • Olopa Oba A ko gba dandan
 • Ijoba o loye
 • A so o deni irele re
 • Ye ye ya iwo atun pada deru
 • Awon Enia Eshugbayi o ma ronu Oluwa
 • Jowo ye fokan bale o
 • Bo se ni dida owo gbogbo wa a da wa
 • Bo se ti ki f’eru sile gbogbo wa lo leru
 • Bo ku dede ki ojo kan ri
 • Oye a ye dandan
 • Bo ku dede k’oba wa, dile gbogbo wa a dile
 • Ka parapo ka gbe’ le wa ta ka fig be o ga
 • Eshugbayi o ma ronu Oluwa
 • Jowo ye fokan bale o
 • Ohunkohun to wu ko lese nidi oro yi o
 • A a ti wa ati wa kenken
 • A ti wa bi ewa
 • Eshugbayi o ma ronu Oluwa
 • Jowo ye f’ okan bale o

 • AWON OLOYE ATI MACAULAY SI PADA BO LATI
 • ILU OYINBO

 • Awon Enia ye
 • E ku abo o E ku abo oba wa (2)
 • E ku abo Oluwa oba oba ijoye
 • E ku ipada sile o baba Macaulay o
 • Eyin to ti lo sile ejo e ya
 • Ile ejo to ga julo
 • E tun pada bow a
 • Jogun baba to bi yin lomo
 • Apapa wa dile ola o
 • Awa olola awa ijoye
 • Awa oselu awa igbimo
 • Gbogbo awa idile Esgugbayi oba wa
 • Tomode tagba ile pe
 • E ku abo sile o
 • E ku abo o e ku abo wa

 • MACAULAY:- E ku ile e ku ile o
 • Mo ki enyin olola
 • Mo ki enyin agbagba
 • Eshugbayi oba wa o ku ile o
 • ‘Gbati a de ile ejo
 • Nibit’ o gbe ga julo
 • Awon oyinbo gb’ ejo ro
 • Won s’ori wa dir ere
 • Ile Apapa o ti wa ni
 • Ye ye ya awa lo nile Eko
 • Opa adehun ole
 • Yoba wa b’oyinbo se
 • L’o fit un rojo ejo aiye
 • L’a fi tun ro jo ejo ile baba wa
 • Awon oyinbo gbejo ro
 • Won s’ori wa di rere
 • Ijapa to ko ogbon aiye sinu agbe o
 • To ni ogbon aiye ma tan o
 • Gbato ku dede s’oke
 • O gbo pe ogbon ku laiye o
 • Gbati won ro pe a sun
 • A o sun ogbon nb’ogbon ja l’oru
 • Macaulay ope ope ope ope
 • Macaulay ope ope loni o eni rere
 • Opa adehun lo nile o

 • AWON ENIA:- E ku abo o e ku abo Oba wa (2)
 • E ku abo Oluwa oba oba ijoye
 • E ku ipada sile o baba Macaulay o
 • Enyin to ti lo sile ejo e ya
 • E Ile ejo to ga julo
 • E tun pada bow a
 • J’ogub baba to bi yin lomo
 • Apapa wa dile ona o
 • Awa olola awa ijoye
 • Awa oselu awa igbimo
 • Gbogbo awa idile Rshugbayi oba wa
 • T’omode t’agba ile pe
 • E ku abo sile o
 • E ku abo e ku abo wa
 • Ijapa to ko ogbon aiye sinu agbe o
 • To ni ogbon aiye ma tan o
 • Gbato ku dede s’oke
 • O gbo pe ogbon ku laiye o
 • Gbati won ro pe a sun
 • A o sun ogbon nb’ogbon ja l’oru
 • Macaulay ope ope ope ope
 • Macaulay ope ope loni o eni rere
 • Opa adehun lo nile o

 • A FI OGNON ETAN MU ESHUGBAYI ELEKO PE KO WA JE
 • EJO NI KOTU GIGA A SI WA A NI OKO MOTO SI ILU OYO

 • Olopa Oba Kabiyesi enyin olola
 • Kabiyesi o enyin agbagba oba olola mo wa ri
 • Eshugbayi o
 • Adajo agba lo fe ri o ni ile ejo ni Tinubu
 • Ni ile ejo to ga julo iwe ejo ma re o
 • Iwe ejo ni Kotu gberanle k’a rele ejo
 • Eshugbayi o oba rere

 • ESHUGBAYI:- Ko gbo o ko gbo emi ko ni rele ejo
 • Emi ko ni rele Kotu o oba alade ki irojo
 • Oba inu iga ki rojo o olopa oba ajeji
 • Gberanle ka rele re ile oba ko gbajeji o
 • Oluwa ati Ewo ba won lo ba won lo (2)
 • AWON ENIA:- Ohunkohun to wu ko le se
 • Ati wa ba won sile ejo o
 • Eshugbayi oba wa
 • Awon Enia Kilo de kilo de
 • Kil’o de t’o nronu
 • Kil’o de o kil’o de
 • A wi fun wa o ka gbo o
 • Wi fun wa o ka gbo s’eti
 • Macaulay Iro ni won pa p’oba nrele ejo
 • Eshugbayi o rele ejo
 • Eke ni won se poba nre Kotu
 • Eshugbayi o re Kotu
 • Won ti m’oba wa rin jinn a
 • Won ti wa Eshugbayi rele Oyo o
 • Ara mi o e gbo seti

 • CHORUS:-
 • A Eshubayi ko rele ejo
 • Be Eshugbayi ko gb’ ona ewon
 • Eshugbayi ti rele Oyo o
 • Ara aiye e gbo o
 • Oba Oluwaiye a da a da
 • Oba to nile a da a da
 • Enyin orisa ti mbe lokun
 • Enyin orisa ti mbe losa
 • Orile Eko to ni wa o
 • A da a da a da a da
 • A da tiwon s’ebi
 • Eshugbayi to rele Oyo o
 • A toju mi bo si le Oba

 • MACAULAY:-
 • Enyin olola e ma ronu
 • Enyin igbimo e ma ronu o
 • E mura sile e ma ronu
 • E d’amure k’o le e ma ronu
 • Eshugbayi to rele Oyo o
 • A t’oju mi bo sile oba
 • Enyin orisa ti mbe lokun
 • Enyin orisa ti mbe losa
 • Orile Eko to ni wa o
 • A da a da a da a da
 • A da tiwon s’ebi
 • A da ti wa s’are a
 • Eshugbayi to rele Oyo o
 • A toju mi bo si le Oba

 • AWON ENIA
 • Baba Macaulay olore olore enia (2)
 • Enyin olola e ma ronu
 • Enyin igbimo e ma ronu o
 • Emura sile e ma ronu
 • E d’amure k’o le e ma ronu
 • Eshugbayi to rele Oyo o
 • A t’oju mi bo sile oba
 • E je ka rele ile ejo
 • Ile ejo to ga julo
 • Ka p’awon oyinbo ologbon aiye
 • Ati awon ti nsowo po
 • Si ile ejo to ga julo
 • A toju mi bo sile oba
 • Enyin orisa ti mbe lokun
 • Enyin orisa ti mbe losa
 • Orile Eko to ni wa o
 • A da a da a da a da
 • A da tiwon s’ebi
 • A da ti wa s’are a
 • Eshugbayi to rele Oyo o
 • A toju mi bo si le Oba

  ACT II SCENE 2


 • OGBENI MACAULAY NINU OGBA EWON NITORI
 • ORO ILU EKO

 • AWON ELEWON:-
 • Ibonbo loji iya uya ibonbo oji
 • Iya iya ibonbo loji
 • Ka gbe ku ku ka gbe ke ke
 • Ka gb’ ogba ewon lo ye ye
 • Se mi se mi s’ olose
 • Ogba ewon re o ara mi aunhun (8)
 • Ojo ma mi r’ojo ale o o dara
 • Orun mi re’ bi iwo o baba
 • Ogba elewon o se o
 • Ogba ewon re o ara mi o
 • Ye . . . . . . . . . . . . . . . . . . . . . .
 • Kilo gbe o de le yi o kilo gbe o dele ewon
 • Olola ni o nilu re
 • Baba Macaulay o
 • Macaulay:-
 • E ye e gbo ara gbogbo
 • Awon osika oba aiye
 • Nitori oro ilu Eko
 • Won gbe mi ju s’ewon ara wa
 • Eni ba puro laiye nfe
 • Eni sotito ko d’esin re kale o
 • Ara mi e gbo seti
 • CHORUS:-
 • Ara aiye Baba Macaulay
 • Otito lo gbe o de’le yi o
 • Otito lo gbe o de’le ewon
 • Eni ba puro l’aiye nfe
 • Eni sotito ko d’esin re kale o
 • Ara mi e gbo seti
 • Ogba ewon ki ise’ ku
 • Ogba ewon ki is’ arun
 • Orile Eko to ni wa o
 • A s’ori re di ori re


  ACT II SCENE 3


 • Ogbeni Macaulay Si Padabo Lati Ogba Ewon
 • Awon Enia Ilu Si Nye e Si

 • AWON ENIA:-
 • Bi o ba nse rere ko mura s’ire
 • Bi o ban se ‘ka ko mura s’ika o
 • Oju a ti baba to jogun omo
 • Oju a ti egbon to jogun aburo
 • Baba wa to rele ejo o o mbo o
 • Macaulay a toju mi bo sile o
 • Ara aiye mo baba to j’aiye rere
 • Olorun nw’eni to nseka loke o
 • Baba wa rele onigo ku abo o
 • Macaulay a toju mi bo sile o
 • Ku abo o ku abo o
 • Baba wa to rele ejo ku abo o
 • Baba wa to rele onigo o ku abo o
 • Eni to bapuro al’olufe o
 • Eni ba s’otito ko d’esin re kale o
 • Ogba ewon ki ise’ ku
 • Ogba ewon ki is’ arun
 • Macaulay lo tori ilu w’ewon aiye o
 • B’araiye ba gbagbe o
 • Oku orun a f’ile re se ‘ranti o

 • MACAULAY:-
 • Enyin olola mo ki yin o
 • Bi o ban se rere k’oo mura s’ire
 • Bi o ba nse’ ka k’o mura s’ika o
 • Oju a ti baba to j’ogun aburo
 • Oju a ti egbon to j’ogun aburo
 • Emi eni to rele onigo mo de o
 • Oku orun a f’ile mi se ‘ranti o
 • Enito puro a l’olufe o
 • Enito s’otito k’o d’esin re kale o
 • Ogba ewon ki mise iku o ti o
 • Ogba ewon ki ise arun o ti o
 • Emi eni to tori ilu w’ewon aiye o
 • B’araiye ba gbagbe o
 • Oku orun a f’ile mi se ‘ranti o

 • AWON ENIA:-
 • Ku abo o ku abo
 • Baba wa to rele ejo ku abo o
 • Baba wa to rele onigo ku abo o
 • Eni to ba puro a l’olufe o
 • Eni to s’otito a d’esin re kale o
 • Ogba ewon ki ise’ ku
 • Ogba ewon ki is’ arun
 • Macaulay lo tori ilu w’ewon aiye o
 • B’araiye ba gbagbe o
 • Oku orun a f’ile re se ‘ranti o
 • Ku abo o o ku abo (2)
 • Omo abile sore (2)
 • K’ile lanu ku abo o

 • ESHUGBAYI ELEKO SI PADA LATI OYO
 • GBOGBO AWON ARA ILU SI NYO

 • AWON ENIA:-
 • Lola-lola Oluwaiye o adupe
 • Lola-lola Oluwaiye o ayo sese
 • Apapa wa d’ile ola o
 • Oba to d’ade ade owo e ya

 • T’ oyinbo wa rele Oyo o
 • A dupe dupe Oluwaiye o
 • Edumare gbowo wa o
 • O mbo o mbo lona (2)
 • Eshugbayi oba wa onti ile Oyo bo o
 • E ku abo olola o E ku abo Oluwa
 • Eshugbayi oba wa E ku abo o
 • Omo aaiye binu awon osika sika
 • Won wa o rele Oyo o
 • Asese d’aiye ejimere o lawo funfun
 • Aiye ma lo r’aso ejimere to di pupa
 • Enia bi aparo l’omo araiye ma fe o
 • A nrin nile inu nb’elesin loke o
 • Eda kan ko fe ni fun rere af’ori eni
 • Eshugbayi adupe lowo re baba Macaulay o
 • Gbogbo enyin olola ati enyin agbagba
 • Gbogbo araiye egbo E ku ile o
 • Mo dupe lowo yin enyin enia gbogbo
 • Mo duoe lowo re baba Macaulay o
 • Omo araiye binu
 • Awon osika sika
 • Won wa mi rele Oyo o
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wa po
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wad a
 • Ijapa to ko ogbon aiye sinu agbe o
 • T’o ni ogbon aiye ma tan o
 • Gbat’o ku dede soke
 • O gbo pe ogbon ku l’aiye o
 • Gbati won rope a sun
 • A o sun ogbon mbogbon ja l’oru
 • Mo dupe lowo re baba Macaulay o

 • AWON ENIA:- E ku abo olola o
 • E ku abo Oluwa omo araiye binu
 • Awon osika sika won wa o rele Oyo o
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wa po
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wad a
 • Ijapa to ko ogbon aiye sinu agbe o
 • T’o ni ogbon aiye ma tan o
 • Gbat’o ku dede soke
 • O gbo pe ogbon ku l’aiye o
 • Gbati won rope a sun
 • A o sun ogbon mbogbon ja l’oru

 • MACAULAY:- A dupe lowo re baba Macaulay o
 • MACAULAY:- Ema da mi lare
 • E ma ma gbe mi s’oke
 • E ranti pe Olodumare
 • L’oba tin se ohun re
 • Edumare Oluwa aiye o
 • L’o m’Oba wa bo o
 • E lo gbeke l’Oluwa
 • Oba wa wa tin se ohun re
 • Ogb’agba ti ngba ar’aiye o lojo idanwo
 • Edumare Oluwa ranti mi sir ere
 • K’ o f’ ile mi se’ ranti o
 • Omo araiye a fe o fife oju ni
 • B’ omo araiye nye o wo
 • K’o lo sora o
 • Olodumare Oba ni np’ ojo ibid a si re
 • Ogb’agba ti ngba ar’aiye o lojo idanwo
 • Edumare Oluwa ranti mi sir ere
 • K’ o f’ ile mi se’ ranti o
 • AWON ENIA:- Macaulay o se o olore o
 • A ranti pe Olodumare
 • L’oba tin se ohun ‘re
 • Edumare Oluwa aiye o
 • L’o m’oba wa bo o
 • Elo gbeke l’Oluwa
 • Oba wa tinse ohun ‘re
 • Ogb’agba ti ngba ar’aiye o lojo idanwo
 • Edumare Oluwa ranti mi sir ere
 • K’ o f’ ile mi se’ ranti o

 • AWON ONIJO NJO, GBOGBO ILU SI NYO NITI IPADABO
 • OBA ELEKO ATI TI OGBENI HERBERT MACAULAY

 • Iya mi abo ma re o omo rere
 • Iya mi abo ma re o omo rere
 • Obirin ti so iyun
 • Won so ileke nirori owo ebi
 • A gbogbo wa l’a mi k’atike
 • K’a le ba won lo
 • Iya mi abo ma re o omo rere
 • Iya mi abo ma re o omo rere
 • Alajani ewo alajani ogo
 • Alajani iya ojo iwo ni baba ewe
 • Iya mi abo ma re o omo rere

 • AWON ENIA:-
 • Gbogbo ire tinbe la’iye
 • Gbogbo ire tin be loke
 • Ko kari gbogbo wa lojo oni o
 • E ku ewu enia o
 • AWON ENIA:-
 • Macaulay ope ope ope
 • Macaulay ope lonio eni rere
 • Opa adehun lo nile o

 • OLOYE OLUWA:-
 • Gbati oba gbo to rele
 • Alade ki iku
 • Gbati oba waja ile
 • Oba ki irorun Awon osika aiye
 • Awon igbimo ile Won sin Akitoye topatopa o laiye
 • Opa wonu iboji O tun pada si le aiye o
 • Araiye e gbo e gbo e gbo o
 • Araiye e gbo loni o eni rere
 • Opa adehun lo ni le o

 • AWON ENIA:-
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wa po
 • Abinu eni ko ma le yi kadara wad a
 • Ijapa to ko ogbon aiye sinu agbe o
 • T’o ni ogbon aiye ma tan o
 • Gbat’o ku dede soke
 • O gbo pe ogbon ku l’aiye o
 • Gbati won rope a sun
 • A o sun ogbon mbogbon ja l’oru
 • Macaulay ope ope ope
 • Macaulay ope lonio eni rere
 • Opa adehun lo nile o

 • AWON ENIA:-
 • Lolalola Oluwaiye o a dupe
 • Lolalola Oluwaiye o a yo sese
 • Apapa wa dile ola o
 • Oba to d’ade owo e ya
 • Toyinbo wa rele Oyo o
 • A dupe dupe Oluwaiye o
 • Edumare gbowo wa o

 • ESHUGBAYI:-
 • Omo araiye binu awon osika sika
 • Won wa mi rele Oyo o
 • Asese d’aiye ejimere o lawo funfun
 • Aiye ma lo r’aso ejimere to di pupa
 • Enia bi aparo l’omo araiye ma fe o
 • A nrin nile inu nb’elesin loke o
 • Eda kan ko fe ni fun rere
 • Af’ori eni
 • A dupe lowo re baba Macaulay o

 • AWON ENIA:-
 • Macaulay o se o olore o
 • A ranti pe Olodumare
 • L’oba tin se ohun ‘re
 • Edumare Oluwa aiye o
 • L’o m’oba wa bo o
 • Elo gbeke l’Oluwa
 • Oba wa tinse ohun ‘re
 • Ogb’agba ti ngba ar’aiye o lojo idanwo
 • Edumare Oluwa ranti mi sir ere
 • K’ o f’ ile mi se’ ranti o

 • AWON ENIA:-
 • Omo araite a fe o fife oju ni
 • Bomo araiye nye o wo
 • K’o lo sors o
 • Olodumare oba ni
 • Np’ojo ibid a s’ire
 • Ogbagba ti ngba ara aiye o lojo idanwo
 • Edumare Oluwa ranti mi sir ere
 • K’ofile mi se ranti o

 • SOLOS AND CHORUS:-
 • Ibonbo loji iya uya ibonbo oji
 • Iya iya ibonbo loji
 • Ka gbe ku ku ka gbe ke ke
 • Ka gb’ ogba ewon lo ye ye
 • Se mi se mi s’ olose
 • Ogba ewon re o ara mi aunhun
 • Ojo ma mi r’ojo ale o o dara
 • Orun mi re’ bi iwo o baba
 • Ogba elewon o se o
 • Ogba ewon re o ara mi o

 • CHORUS:-
 • E o yi o Macaulay a dehin bo o
 • Bina ba mi darugbo A feruru ss’ode
 • B’ogede ba mi darugbo a f’omo ropo
 • Makoli k ku laiye o pipa lo parade
 • Omo araiye e ma ronu o Makoli a dehin bo
 • E agbe lo nile aro o dara
 • Aluko lo nile osun o baba
 • Lekele elese ogere eiye lo rokun
 • Macaulay lo nile Eko o ki baba to parade o
 • Omo araiye e ma ronu o Makoli a dehin bo o

 • THE END

 • ALL RIGHTS RESERVED