Journey to Heaven


    OPENING GLEE

    ITAN ERE NA


  • Ara’iye e wa kawa korin ogo s’Oluwa

  • Angeli e bo kewa korin iyin s’oke o
  • Ara ayiie e gbo mi, ara orun e gbo mi o (2)
  • Omo l’ehin iwa omo l’opo ile
  • Edumare fun wa l’omo
  • Ti yio gb’ehin tun ehin se o
  • Edumare fun wa l’omo
  • Ti yio gb’ehin tun ehin se
  • Eni omo sin l’o bimo, omo l’ayole
  • Eni omo sin l’o bimo, omo l’ayole o l’ayole
  • Edumare awa mbe o o, dariji awon apania
  • Aiye l’oja, orun ni’le
  • Aiye l’oja orun ni’le o
  • Enyin ti mbe l’ayie, e ku oja ayie o
  • Enyin ti mbe l’ayie e ku ewu irin ajo
  • Irin ajo la’taiye lo tarara
  • Titi lo dorun, e ku ewu irin ajo
  • Awon ibeji meji, Taiwo Kehinde
  • ‘Gba won nlo rin irin ajo
  • Irin ajo la’taiye lo tarara
  • Titi lo dorun
  • ‘Gba won de ile ayie
  • Taiyelolu deni ire
  • O mona ti ise ‘rele
  • O mona ti i’sona ire
  • O ranti pe Olodumare
  • L’Oba ti ns’ohun ire
  • At’orun bo wa j’ayie
  • At’aiye pada sorun
  • Aiye loja orun nile o (2)
  • Enyin ti mbe layie e ku oja ayie o
  • Enyin ti mbe layie e ku ewu irin ajo
  • Irin ajo la’taiye lo tarara
  • Titi lo dorun, e ku ewu irin ajo
  • A o yi o, a o yi o
  • ‘Gba won de ile ayie
  • Kehinde gb’ona iya
  • Kehinde gb’ona ibi
  • O sayie yi d’a wa ilo, ara e gbo o
  • Kehinde y’iya-ki-ya
  • O fi ‘le oti se ile, o fi ile ewon s’oja O f’oko meta po
  • Kehinde wa pada wa dolomolanke
  • A Kehinde o se ohun ire
  • A aiye ile a ayie ile o
  • Awon oni tete ayie awon oni baranda oja
  • Awon ni won pa Kehinde da
  • Ti o fi d’eni iku
  • Awon ni won pa Kehinde da
  • Ti o fi d’eni orun Rere rere l’Oluwa
  • Ko ma da enikan fun ibi
  • Ko ma da enikan fun aro
  • A f’eni ba fi owo ara re
  • To fi fa ibi
  • Eni t’o ba se rere
  • A tun pada wa ri ire
  • Eni t’o ba se ibi
  • A tun pada wa ri ibi
  • T’ibi t’ire lo nrin papo nile aiye o
  • Edumare l’Oluwa Oluwa esan
  • A ara mi a, ara mi o
  • Eni t’o mbe laye
  • Ko ranti pe iku mbe (2)
  • Omi omi l’enia, bi oba san wa
  • A tun san pada, eda ayie mbo o nlo
  • A t’orun bo wa j’ayie
  • Ati ayie pada s’orun
  • Edumare awa mbe o
  • Dariji omo enia o
  • F’igba nla bu omi ko ‘mi
  • Ongbe ngbe ‘male
  • F’igba nla bu omi ko ‘mi
  • Ongbe ngbe ‘male

    ACT 1 SCENE 1


  • TAIWO ATI KEHINDE NINU ISALU ORUN NMURA LATI WA SI AYIE

  • TAIWO ATI KEHINDE:
  • Enyin omode l’orun, enyin agbagba l’orun
  • Enyin Eiyele Ogo, enyin Adaba meje
  • Enyin arugbo igbani olodun jojo
  • A ................ A wa juba o
  • K’a to rin irin ajo

  • AWON ANGELI: (The Angels)
  • E ......irin ajo, e nlo rin irin ajo (2)
  • Irin ajo lat’aiye lo tarara
  • Titi lo s’orun, e nlo ri irin ajo (2)

  • TAIWO ATI KEHINDE:
  • Enyin Afun’pe l’orun, enyin akowe orun
  • Enyin asoju Edumare Ologo Meta
  • L’atetekose li enyin wa pelu Olorun
  • Gbogbo asiri ayie at’eyi ti mbe l’orun
  • Enyin pelu Olodumare l’on s’ohun
  • A...... A wa juba kai lo rin irin ajo

  • AWON ANGELI:
  • E ......irin ajo, e nlo rin irin ajo (2)
  • Irin ajo lat’aiye lo tarara
  • Titi lo s’orun, e nlo ri irin ajo (2)

  • TAIWO ATI KEHINDE:
  • Enyin Ato’ni s’ona ona ile ayie o
  • Ko s’ohun to le di ‘na
  • A nre ‘le ayie o
  • Enyin t’o m’oni to tun m’ola lojo ayie o
  • A, A awa juba o kai lo rin irin ajo

  • AWON ANGELI:
  • E ......irin ajo, e nlo rin irin ajo (2)
  • Irin ajo lat’aiye lo tarara
  • Titi lo s’orun, e nlo ri irin ajo (2)

  • AINA NI YIO SI SE IYA WON

  • TAIWO ATI KEHINDE:
  • Awa ibeji meji, a nre ‘le aiye o
  • S’odo Aina wa
  • Enit’o ti loyun ibeji n’ile ayie o
  • Pipe ojo ibi re ko j’ojo merinla lo
  • A nlo pese aye nile aina wa
  • Ko s’ohun to le dina a nrele ayie o
  • Enyin t’o m’oni to tun m’ola lojo ayie o
  • A, A awa juba o kai lo rin irin ajo

  • AWON ANGELI:

  • E ......irin ajo, e nlo rin irin ajo
  • Irin ajo lat’aiye lo tarara
  • Titi lo s’orun, e nlo ri irin ajo

  • TAIWO ATI KEHINDE:
  • Enyi Alamo, Alamo tin mo ‘ri wa
  • A nre ‘le aiye o
  • Ona kini ao gba wiwo tabi rere ni
  • Iwa kini ao hu ibi tabi rere ni
  • Kil’ayie wa yio ti se
  • Kil’ona wa yio ti da
  • ‘gba t’aba de ‘le ayie
  • Ni ‘le ajeji baba nibi t’enikan ko mo
  • B’ibi tabi rere ni
  • Ohun gbogbo l’okunkun fun wa (All things are dark to us)
  • Ni ‘le ayie o (In the world)
  • Enyin Ato’ni sona, ona ile ayie o
  • Enyin arugbo igbani olodun jojo
  • Kil’ayie wa yio ti
  • Kil’ona wa yio ti da
  • ‘gba t’aba de ‘le ayie o

  • AWON AGBAGBA:
  • Enyin ibeji meji ti nrele ayie o
  • Rere rere l’Oluwa
  • Ko ma da enikan fun ibi
  • Ko ma da enikan fun aro
  • Af’eni ba f’owo ara re to fi fa ibi
  • Eni to ba se rere, a tun pada wa ri ‘re
  • Eni to ba se ibi, a tun pada wa ribi
  • T’ibi t’ire l’on nrin papo nile ayie o
  • Edumare l’Oluwa Oluwa esan
  • T’IBI TIRE NI NRIN PAPO NILE AYIE

  • AWON ANGELI:
  • Iba e o , e wi ire o
  • Rere rere l’Oluwa
  • Ko ma da enikan fun ibi
  • Ko ma da enikan fun aro
  • Af’eni ba f’owo ara re to fi fa ibi
  • Eni to ba se rere, a tun pada wa ri ‘re
  • Eni to ba se ibi, a tun pada wa ribi
  • T’ibi t’ire l’on nrin papo nile ayie o
  • Edumare l’Oluwa Oluwa esan

  • AWON AGBAGBA:
  • Enyin ibeji meji ti nrele ayie o
  • E mase gbagbe o ire lai si ‘bi
  • Ati ibi lai si ‘re ko ma si nile ayie o
  • Ogun omode ki mai sire gb’ogun odun o
  • ‘Gba t’ohun gbogbo ba si koro lojo oni o
  • E ranti pe o mbo wa dun to ba di lola
  • T’ibi t’ire l’on nrin papo nile ayie o
  • Edumare l’Oluwa Oluwa esan

  • AWON ANGELI:
  • E ......irin ajo, e nlo rin irin ajo
  • Irin ajo lat’aiye lo tarara
  • Titi lo s’orun, e nlo ri irin ajo

  • TAIWO ATI KEHINDE:
  • Enyin agbagba a wi, enyin agbagba e fo
  • E wi ona t’a o gba
  • T’a o fi rire nikan
  • T’ibi ki yio pade wa
  • Ki a lowo, k’a bimo
  • A, A wa juba o kai lo rin irin ajo
  • Ki a si ko ‘le mo ‘le
  • Ki a si b’etan s’ehin
  • Anile ni porogun ‘laso, ka rire nikan
  • K’ibi mase pade wa, ka mase d’agba osi
  • K’ojo ayie wa si le toro dojo ale o
  • A, A wa juba o kai lo rin irin ajo
  • K’ayie wa le tutu
  • ‘Gbat’a ba wa l’omode
  • Titi ta tun ndarugbo lo
  • Edumare k’o gba wa
  • ‘Gbat’a ba pada s’orun
  • K’a ri enyin agbagba
  • K’e f’ayo wa pade wa
  • K’e mu wa de ‘le ola
  • K’e mu wa d’orun ogo
  • Rere rere l’Oluwa
  • Ko ma da enikan fun ibi
  • Ko ma da enikan fun aro
  • Af’eni ba f’owo ara re to fi fa ibi
  • Eni to ba se rere, a tun pada wa ri ‘re
  • Eni to ba se ibi, a tun pada wa ribi
  • T’ibi t’ire l’on nrin papo nile ayie o
  • Edumare l’Oluwa Oluwa esan

  • A SI KO ILA OWO FUN AWON IBEJI NAA

  • AWON AGBAGBA:
  • Awa nko ‘la, a nko ila owo (2)
  • Enyin ibeji meji ti nlo ile ayie o
  • E S’ori re o, e sori re o
  • Ki E l’owo k’e bimo
  • K’e ma se dagba osi
  • Anile ni porogun ‘laso ke rire nikan
  • E s’ori ire o (2)
  • A nko ila owo
  • Awa nko ila a nko ila owo
  • K’ayie yin le tutu
  • ‘Gbat’e ba wa l’omode
  • T’e ba tun darugbo lo
  • Edumare k’o gba yin
  • ‘Gbat’e ba pada s’orun
  • K’e ri awa agbagba
  • K’a f’ayo wa pade o
  • Ka gbe yin de ‘le ola
  • K’a gbe yin d’orun ogo
  • Rere rere l’Oluwa
  • Ko ma da enikan fun ibi
  • Ko ma da enikan fun aro
  • Af’eni ba f’owo ara re to fi fa ibi
  • Eni to ba se rere, a tun pada wa ri ‘re
  • Eni to ba se ibi, a tun pada wa ribi
  • T’ibi t’ire l’on nrin papo nile ayie o
  • Edumare l’Oluwa Oluwa esan

  • TAIWO ATI KEHINDE NDAGBERE FUN AWON EDA ORUN KI WON TO WA SI AYIE

  • TAIWO ATI KEHINDE:
  • A baba wa lo layie
  • A baba wa l’onile
  • Awa ibeji meji a nrele ayie o
  • A o digba o awa mi lo o (2)
  • A o se ‘le ayie ko wa dabi orun

  • AWON ANGELI
  • A e w’ire, a e fo ‘re
  • Enyin ibeji meji tin lo ‘le ayie o
  • Taiyelolu omo wa, Omokehin a gba ‘gba
  • E nrele ayie o, a o digba o
  • Enyin nlo o, enyin nlo o
  • E o se ‘le ayie ko wa dabi orun

    ACT 1 SCENE 2


  • A BI AWON IBEJI NA SI AYIE AWON EBI ATI ORE SI NKI ALABA BABA WON ATI AINA IYA WON KU EWU OMO

  • AWON ENIA:
  • E ku ewu ye ye o, e ku ewu enia (2)
  • Aina awa ki o, e ku ewu enia
  • Alaba awa ki o, e ku ewu enia
  • T’omode t’agba ni papo
  • Wo oju omo enia o
  • A t’ijo t’ayo lomode k’eyie
  • T’o ba r’eyie
  • A t’ijo t’ayo la fi wa ki o
  • E ku ewu enia
  • Ibeji meji e ku abo o
  • Ibeji meji olori ire
  • E ku ewu irin ajo o
  • Taiyelolu a wa ki o, e ku abo omo wa
  • Kehinde awa ki o, e ku abo omo wa
  • Ibeji meji e ku abo o
  • Ibeji meji olori ‘re, e ku abo omo wa
  • E ku ewu ye ye o, e ku ewu enia o (2)
  • Aina awa ki o, e ku ewu enia o
  • Alaba awa ki o, e ku ewu enia o
  • E ku ewu ye ye o, e ku ewu enia o

  • AINA:
  • Mo dupe enyin ti e wa
  • Mo dupe enyin ti e bo
  • Mo dupe enyin ti e ki mi
  • E ku ewu irin ajo
  • Emi Aina iya omo ati Alaba baba
  • A dupe ola t’e fun wa
  • E ku ewu irin ajo
  • Taiyelolu kin yin pupo
  • Omokehin ki nyin pupo
  • Tomode t’agba e ma wole
  • Ire a kari o, ko ni mo s’ibikan
  • E ku ewu irin ajo

  • AWON ENIA
  • A ire a ire
  • Ire a kari o, ko ni mo si ibikan
  • E ku ewu enia o
  • Tomode t’agba awa ki o, Ire a kari
  • E r’oju ayie o tabi e o ri
  • Awodi bale o gb’eyie lo
  • Agan ti ko bi a d’olomo
  • Awodi bale o gb’eyie lo

  • ALABA:
  • Mo dupe enyin ti e wa
  • Mo dupe enyin ti e bo
  • Mo dupe enyin ti e ki mi
  • E ku ewu irin ajo
  • Emi Alaba baba omo TI Aina iya omo
  • A dupe ola ti e fun wa
  • E ku ewu irin ajo
  • Olodumare Oluwa wa
  • L’o boju wa’le ile ayie o
  • L’o fun wa l’omo aye rere
  • Tokotaya wa f’owo s’osun
  • A f’owo s’osun osun omo
  • Ire a kari o ko ni mo si ibikan
  • E ku ewu irin ajo o

  • AWON ENIA
  • A Ire.... a ire
  • Ire a kari o, ko ni mo si ibikan
  • E ku ewu enia o
  • A, Alaba o wi ire, Ire a kari etc.
  • Tomode t’agba a ki o
  • E r’oju ayie o tabi e o ro
  • Awodi bale o gb’eyie lo
  • Agan ti ko bi a d’olomo
  • Awodi bale o gb’eyie lo

  • AWON ENIA NJO WON SI NYO NI ‘BI ASE AWON OMO TUNTUN NA

  • AWON ENIA
  • Awodi e ku ewu o
  • Ewu ina ki i pa awodi
  • K’oloyele k’oloyele so
  • Ijo wo l’o ma d’agba
  • Olurebete Olureberebe
  • Ijo wo l’o ma d’agba, Olurebete Olureberebe
  • A o jo de ‘le yeye o ,, ,, ,,
  • Ngo se ki npe o o ,, ,, ,,
  • Ijo wo l’ ma d’agba o

    ACT 1 SCENE 3


  • AWON IBEJI NA SI DAGBA, AWON OBI, EBI ATI ORE SI TU WON SILE LATI FE OKO TO WU WON

  • AWON ENIA:
  • A, Aina wa a, Alaba wa(2) (Ah our Aina, our Alaba)
  • A de, a de, tori e npe wa o
  • Igbehin re nbo wa dun o lo o(2)
  • Ejire olowo, Ejire olomo (2)
  • Ejire ara Isokun a-d’aro-pale-aso
  • Igb’enyin ranse aiye, igb’enyin ranse
  • T’e ni ka ma bo
  • K’a wa jayie oba tarara
  • A de, a de ‘tori e npe wa o l’ayie
  • Igbehin re mbo wa dun o lo o (2)
  • Ejire olowo, ejire olomo
  • Ejire ara isokun a-daro-pale-aso
  • Kini k’a wa se t’a o se Aina
  • Kini k’a wa se t’a o se Alaba
  • Aja ki ‘ko wagbawagba eko laiye
  • Eiyele ki ‘ko wagbawagba oka beni
  • Iponri aja o jobi se
  • Iwo ni baba ewe
  • A de, a de ‘tori e npe wa o l’ayie
  • Igbehin re mbo wa dun o lo o
  • Ejire olowo, ejire olomo
  • Ejire ara isokun a-daro-pale-aso

  • ALABA
  • A enyin ara ile, a enyin ara wa
  • Enyin ti e gbo ti e bo
  • Mo dupe ojo oni emi ni baba ewe
  • Kehinde omo wa ma re o enyin ara
  • Taiwo omo wa ma re o enyin ara
  • Won ti d’agba t’eni ile oko a dupe olu
  • Won ti d’agba t’eni ile oko a mi yo sese
  • Enyin ti e gbo ti e bo
  • Mo dupe ojo oni emi ni baba ewe
  • E je k’a fun won l’ase
  • E je k’a yoda fun won
  • Ki won l’oko t’o wu won o
  • Ki won l’oko t’o wu won o
  • Oko t’o l’ebi rere
  • Oko t’o l’ona rere
  • Oko t’o l’owo l’owo
  • Oko t’o l’aso l’eru
  • Oko t’o ri je t’o ri mu
  • Oko ti ko ni gbese l’orun
  • Emi ni baba ewe

  • TAIWO ATI KEHINDE:
  • A aiye ile, a ayie ile o
  • A dupe l’owo baba t’o bi wa l’omo
  • Enyin ti e gbo ti e bo
  • A dupe ojo oni enyin ni baba ewe
  • A ti d’agba t’eni ngbe’yawo a dupe Olu
  • A ti d’agba t’eni ile oko a nyo sese
  • A mi lo f’oko t’o wu wa o layie
  • A mi lo f’oko t’o wu wa o baba
  • Oko t’o l’ebi rere
  • Oko t’o l’ona rere
  • Oko t’o l’owo l’owo
  • Oko t’o l’aso l’eru
  • Oko t’o ri je oko t’o ri mu
  • Oko ti ko ni gbese l’orun
  • Enyin ni baba ewe

  • AWON EBI:
  • A aiye ile, A, ayie ile o (2)
  • E ti d’agba t’eni ngbeyawo a dupe Olu
  • E ti d’agba t’eni ile oko a nyo sese
  • Ile ayie l’e nlo, ile ayie l’e nre
  • E jowo s’ayie re, e jowo se ‘le re
  • Mase gbagbe Olorun, mase gbagbe Jesu
  • E gbo on ni baba ewe
  • L’ojo k’e ri je, l’ojo k’e ri mu
  • L’ojo k’ebi pa nyin d’ale o
  • E ma ma daro o
  • E jowo s’ayie re, e j’owo se ‘le re
  • Mase gbagbe Olorun, mase gbagbe Jesu
  • E gbo on ni baba ewe

  • AWON EBI ATI ORE SI NJO WON SI NYO NI ‘BI APEJO NA

  • Awa l’a b’onifa, awa l’a b’alufa
  • Awa l’a b’onigbagbo o
  • K’o to d’omo Jesu o
  • Igba mba jo, onilu gbe ‘lu lo
  • Ibaka pelebe o gbe bi awo
  • Gbangba ela, gbangba ela o
  • Okuta meta ela o gbangba ela
  • A o pa ra w a l’ayo olele

    ACT II SCENE 1


  • KEHINDE JE ONIWA KIWA OMO. O FE OKO META PO, O SI GBA OWO L’OWO WON

  • ADISA
  • Gbo gbo gbo, arabirin gbo
  • Mo ni oro kan ba o so
  • Mo ni ero kan ba o ro
  • Gba ti mo nwo ‘ju re
  • O da b’oju Angeli
  • Gbati mo nw’ehin re
  • O funfun bi fadaka
  • Mo ni oro kan ba o so
  • Mo ni ero kan ba o ro
  • Mo fe ‘fe o laya ni
  • Omokehin o gba gba
  • Mo fe fi o se ‘yawo o a, emi ni oko re
  • Idile ola ni mi o, Kehinde mi

  • KEHINDE:
  • A mo gbo, a mo gba dandan
  • Mo gba lati se aya re Adisa mi
  • Mo gba lati se aya re titi ayie o
  • Nje olufe mi, oko to l’owo l’owo
  • Oko to l’aso l’eru
  • Mo gba lati se aya re titi ayie o
  • Nje fun mi ni poun mefa
  • Ki nfi r’aso ebi
  • Nje fun mi ni poun meji
  • Ki nfi jeun ata
  • Idile ola ni o o Adisa mi

  • ADISA
  • Gba gba gba, ki o fi r’aso ebi
  • Gba gba gba k’o fi jeun ata
  • Mo nlo k’abo wa ba o ti o ba di l’ola
  • Mo lo k’abo wa bo o Kehinde mi

  • LADIMEJI
  • Gbo gbo gbo, arabinrin gbo
  • Mo ni oro kan ba o so
  • Mo ni ero kan ba o ro
  • Emi omo Ile=Ife, mo ti Ile-Ife wa o
  • Baba mi ko ‘le mo ‘le
  • Iya mi b’etan s’ehin
  • Idile owo idile ola
  • Idile ola ni mi o Kehinde mi
  • Ni ‘bi ise ti mo wa, ogun poun
  • L’owo osu t’ Ijoba nfun mi
  • Baba mi ko ‘le mo ‘le
  • Iya mi b’etan s’ehin
  • Idile owo idile ola
  • Idile ola ni mi o Kehinde mi
  • Mo fe fe o l’aya ni
  • Omokehin o gba gba
  • Mo fe fi o se ‘yawo o a, emi ni oko re
  • Idile ola ni mi o, Kehinde mi

  • KEHINDE:
  • A mo gbo, a mo gba dandan
  • Mo gba lati se aya re Ladimeji mi
  • Mo gba lati se aya re titi ayie o
  • Nje olufe mi, oko to l’owo l’owo
  • Oko to l’aso l’eru
  • Mo gba lati se aya re titi ayie o
  • Nje fun mi ni poun mefa
  • Ki nfi r’aso ebi
  • Nje fun mi ni poun meji
  • Ki nfi jeun ata
  • Idile ola ni o o Ladimeji mi

  • LADIMEJI:
  • Gba gba gba, ki o fi r’aso ebi
  • Gba gba gba k’o fi jeun ata
  • Mo nlo k’abo wa ba o ti o ba di l’ola
  • Mo lo k’abo wa bo o Kehinde mi

  • AJAO:
  • Gbo gbo gbo, arabirin gbo
  • Mo ni oro kan ba o so
  • Mo ni ero kan ba o ro
  • Gba ti mo nwo ‘ju re
  • O da b’oju Angeli
  • Gbati mo nw’ehin re
  • O funfun bi fadaka
  • Mo ni oro kan ba o so
  • Mo ni ero kan ba o ro
  • Nko ni baba mo o, nko ni iya mo o
  • Gbogbo won ku lo s’orun a .......
  • Mo wa d’olomo-lanke
  • Omolanke ni mo nti
  • Mo ti gb’okiki re, o ti gb’okiki
  • Emi t’o l’owo l’owo
  • Iwo t’o l’aso l’eru
  • Mo ni oro kan ba o so
  • Mo ni ero kan ba o ro
  • Mo fe ‘fe o laya ni
  • Omokehin o gba gba
  • Mo fe fi o se ‘yawo o a, emi ni oko re
  • Idile ola ni mi o, Kehinde mi

  • KEHINDE:
  • A mo gbo, a mo gba dandan
  • Mo gba lati se aya re Ajao mi etc

  • AJAO:
  • Gba gba gba, ki o fi r’aso ebi
  • Gba gba gba k’o fi jeun ata
  • Mo nlo k’abo wa ba o etc

  • NITOTO KEHINDE KO SE OHUN RERE

  • A Kehinde ns’ayie re lo
  • A Kehinde nrin irin ajo
  • Lat’ayie yi bo titi d’orun
  • O l’oko meta po, o f’oko meta po
  • Kehinde pada wa d’olomo-lanke
  • A Kehinde ko se ohun rere
  • Ojo ekun ku si dede
  • Ojo ekun sunmo o
  • A Kehinde ko se ohun rere
  • Adisa, Ladimeji ati Ajao pada lati se Igbeyawo pelu Kehinde, asri tu, a si fa Kehinde lo si ile ejo

  • ADISA:
  • Mo de mo de mo de o, Kehinde
  • Omo Onile ki ibo ki ‘le ma mo
  • K’o se ranti ojo t’a ri ‘ra Kehinde
  • Ero ona k’o gbe ‘ra nle ....... k’a sire
  • Omo ayie ma mi w’oju re o omo rere
  • K’o gbe ‘ra nle k’a se ‘gbeyawo ara mi
  • K’o gb ‘ra nle k’a re ‘le o baba mi
  • Awon ebi, ara, ore o won npe o
  • Won mura sile won nreti re o olufe mi
  • Emi t’o l’owo l’owo
  • Emi t’o l’aso l’eru
  • Idile owo, idile ola
  • Idile ola ni mi o Kehinde mi

  • KEHINDE:
  • Wole, wole, wole o, Adisa
  • Omo Onile ki ibo ki ‘le ma mo
  • M’o se ranti ojo t’a ri ‘ra Adisa
  • Mo ti mura k’a se ‘gbeyawo ara mi
  • Mo ti mura k’a re ‘le o baba mi
  • Awon ebi, ara, ore o Adisa
  • Won mura sile won nreti re o olufe mi
  • Wo le wole wole o wa joko
  • K’a mura nle ka re ‘le o olufe mi
  • Iwo t’o l’owo l’owo
  • Iwo t’o l’aso l’eru
  • Idile owo, idile ola
  • Idile ola ni o o Adisa mi

  • LADIMEJI:
  • Mo de mo de mo de o, Kehinde
  • Omo Onile ki ibo ki ‘le ma mo
  • K’o se ranti ojo t’a ri ‘ra Kehinde
  • Ero ona k’o gbe ‘ra nle ....... k’a sire
  • Omo ayie ma mi w’oju re o omo rere
  • K’o gbe ‘ra nle k’a se ‘gbeyawo ara mi
  • K’o gb ‘ra nle k’a re ‘le o baba mi
  • Awon ebi, ara, ore o won npe o
  • Won mura sile won nreti re o olufe mi
  • Emi t’o l’owo l’owo
  • Emi t’o l’aso l’eru
  • Idile owo, idile ola
  • Idile ola ni mi o Kehinde mi

  • KEHINDE:
  • Wole wole o wole o wole o
  • Omo onile ki ibo k’ile ma mo

  • AJAO:
  • Mo de mo de o mo de o Kehinde
  • Omo onile ki ibo k’ile ma mo
  • K’o se ranti ojo t’a ri ‘ra Kehinde

  • KEHINDE:
  • Wole wole o wole o wole o
  • Omo onile ki ibo k’ile ma mo
  • Mo se ranti ojo t’a ri ‘ra o Ajao

  • ADISA
  • Kini mo ri o mori o Kehinde
  • Awon tani won mi wo mi o olufe mi
  • Jowo ye k’o la mi l’oye olufe mi

  • KEHINDE
  • Awon ebi ara ore ni o Adisa
  • Awon egbon ati aburo Adisa mi
  • E fi won sile k’a ma lo Adisa mi
  • Wa wa wa Adisa mi
  • Mo ni oro kan ‘ba o so
  • Mo ni ero kan ‘ba o ro....
  • Kai ara mase sunmo mi ngo ko fe
  • Kai ara mase sunmo mi opada ma lo
  • Eni t’a o pe t’o wa
  • Be ‘le wo oju l’o ya
  • Omo ayie ma mi woju mi o omo rere

  • LADIMEJI ATI AJAO
  • Dajudaju a gbe a gbe o ori wa
  • A fe ‘yawo olosu mefa ara wa
  • O gb’eru ori mi o gb’eru ori re
  • E r’oju ayie tabi e o ri ojo nkoja lo
  • Omo a-jodi-jeso
  • Ko se ranti ojo ta ri ‘ra wa Kehinde
  • K’o se ranti poun mefa
  • Ti o fi r’aso ebi
  • Ko se ranti poun meji
  • Ti ofi jeun ata
  • Idile iro ni o o Kehinde yi o
  • Ile ejo l’a nmu o lo Kehinde
  • Ile ewon l’a nmu o re (2)
  • O d’ile ejo ko to mo wa o Kehinde
  • O d’ile ejo k’o to mo wa o l’olufe re
  • Awa o ni fe, awa o ni gba
  • Ile ejo l’a nmu o re kiakia

  • KEHINDE
  • E jowo aladugbo ara e gba mi o

  • LADIMEJI ATI AJAO
  • Ile ejo la nmu o re kiakia

    ACT II SCENE 2


  • Si Kiyesi i Kehinde je Onikakuna omo osi na gbogbo Owo re tan sinu Faji ati Afe Aye owo si tan

  • AWON ONI SAKARA:
  • Ebi npa wa o ara mi, ebi np’olomo Eko
  • Lailai l’ogun ti nja eyi le julo
  • Lat’igba t’ayie ti se
  • Enia dudu ko ku iku ebi
  • Enyin a-de-‘lu-ma-lo
  • Enyin le mu gari d’owon o l’oju wa
  • Edumare awa mbe o o dariji awon apania
  • Igb’oyinbo nje bota o enia dudu nje jero
  • Igb’oyinbo nje nama, enia dudu nj’awo eran
  • Lat’igba t’ayie ti se
  • Enia dudu ko ku iku ebi
  • Enyin a-de-‘lu-ma-lo
  • Enyin le mu gari d’owon o l’oju wa
  • Edumare awa mbe o o dariji awon apania
  • Igb’oyinbo nje buredi o
  • Enia dud nje jero
  • Igb’oyinbo nje suga
  • Enia dudu nmu omi ata
  • Lat’igba t’ayie ti se
  • Enia dudu ko ku iku ebi
  • Enyin a-de-‘lu-ma-lo
  • Enyin le mu gari d’owon o l’oju wa
  • Edumare awa mbe o o dariji awon apa’nia
  • A ara mi, a ara mi o
  • E fi kota sile k’e d’amure nyin k’o le
  • Dajudaju Olodumare ko gbagbe wa l’orun
  • Edumare awa mbe o o dariji awon apa’nia o
  • O gbe ‘le baba ta fi r’aso
  • E ma ba wi jo o e je o lo o
  • Aje orun yio da o ye ye omo a Jodi-jeso
  • Ti wa ye, ti wa ye, ti wa ye wa (2)
  • Ti wa ye wa ni ikun ara wa o
  • Ohun ti a nf’owo wa r a
  • Ti wa ye wa ni ikun ara wa o
  • Awa nf’owo wa r’aso
  • F’igba nla b’omi ko mi o
  • Ongbe ngbe ‘male
  • F’igba nla b’omi ko mi o
  • Ongbe ngbe ‘malle o

  • AWON OSIRE KEJI

  • Ekun omo re ekun omo da o (2)
  • Ekun omo to nke o oro nse yanmuyanmu
  • K’ayie mase baje o baba mi
  • K’ayie mase baje o baba mi mi
  • E .... baba ayie o
  • K’ayie mase baje o baba mi a
  • Oluwa gbere o baba ayie o (2)
  • T’ojo t’erun bakan na oju re o
  • E ......baba ayie o
  • T’ojo t’erun bakan loju re o

  • AWON OSIRE KETA: *************

  • KEHINDE ;
  • A owo ti tan mo ‘nawo ‘nawo
  • Owo na tan o ara mi o e gbo s’ eti
  • N’ iwoyi ojo ola
  • Awon o ni tete mbo l’odo mi
  • Awon alayo mbo l’odo mi
  • Kini ki nwa se wayi o owo tan
  • Owo ma tan ara mi e gbo s’eti
  • A mo ranti (2)
  • Mo n’ ile meji l’ ehingbeti
  • Mo ni ile meji l’Agege
  • Ti mo fi j’ ogun l’aiye o
  • Mo sit un laso die l’eru
  • Mo l’ egba owo mo l’ewon orun
  • Ma l’ogba owo mo l’ewon orun

  • Ma lo ko won ta b’ oba d’ola
  • Iyen ni ngo se wa yi owo tan
  • Owo ma tan o ara mi e gbo s’eti

    ACT III SCENE 1


  • KEHINDE SI GBE ILE ATI ILE BABA RE TA NI GBANJO

  • KEHINDE ;-
  • Onigbanjo mo de mo de
  • Onigbanjo e gbo mi o (2)
  • Mo n’ile meji l’Ehingnbeti
  • Mo nile meji Agege
  • Mo l’egba owo mo l’ewon orun
  • Mo fe k’ o ba mi ta won o ye
  • Ki ng r’ owo gba kiakia
  • Ki ng r’owo gba lesekese
  • Ki ngo r ‘owo lo b’ o ba d’ ola
  • Afara ko si o a ra mi
  • Onigbanjo o mo mi r’oju

  • ONIGBANOI
  • gbo ara mi
  • Elo l’o fe gba fun ile re
  • At ‘ egba b owo at ‘ewon orun
  • Elo lo fe gba fun ile re
  • At’ egba owo at ewon orun
  • Elo lo fe gba fun eru re
  • Wi fun mi o kin gbo seti

  • KEHINDE;-
  • Mo f’ apo mejo fun ile kan
  • M’o apo mefa fun ile kan
  • At’ egba owo at’ewon orun
  • Mo f’ogun apo fun gbogbo wan
  • Onigbanjo mo mi ro ju

  • ONIBGANJO:
  • Mo gbo ara mi
  • Ngo ra ‘le re t’owo t’owo
  • Ngo ra ‘le re gigagiga
  • At’egab owo at’ewon orun
  • B’o ba di l’ola ko wa gbowo o
  • Ara mi o

  • A SI TA GBOGBO OHUN INI KEHINDE NI GBANJO

  • ONIGBANJO:
  • Gbo ara mi
  • Ohunrere nlo n’iyen (2
  • Egba owo ewon orun
  • Ohun rere nlo n’iyen
  • E wi ka gbo o ara mi

  • AWON ENIA:
  • Ohunrere nlo n’iyen (2)
  • Egba owo ewon orun (2)
  • Ohun rere nlo n’iyen
  • E wi ka gbo o ara mi

  • ONIGBANJO:
  • Kil’o tun wi o ara mi

  • ENITI NRA ‘JA:
  • Poun mefa ni mo wi
  • Poun mefa ni mo fo

  • AWON ENIA:
  • Ohun rere nlo niyen

  • ONIGBANJO:
  • Kil’o tun wi o ara mi

  • ENITI NRA ‘JA:
  • Ogun poun ni mo wi
  • Ogun poun ni mo fo

  • AWON ENIA:
  • Ohun rere nlo n’iyen etc

  • ONIGBANJO:
  • Kil’o tun wi o ara mi

  • ENITI NRA ‘JA;
  • Ogbon poun ni mo wi
  • Ogbo poun ni mo fo
  • AWON ENIA:
  • Ohun rere nlo n’iyen

  • ONIGBANJO:
  • Kil’o tun wi o ara mi

  • ENITI NRA ‘JA:
  • Mo fi poun meji kun (2)

  • AWON ENIA:
  • Ohun rere nlo n’iyen

  • ONIGBANJO:
  • Kil’o tun wi o ara mi

  • ENITI NRA ‘JA:
  • Mo fi poun mefa kun

  • AWON ENIA:
  • Ohun rere nlo n’iyen

  • ONIGBANJO:
  • Gbo ara mi
  • Ile meji l’ehingbeti
  • Ile meji l’Agege
  • Ohun rere nlo n’iyen
  • Kil’o tun wi o ara mi

  • ENITI NRA ‘JA:
  • Apo meji ni mo wi
  • Apo meji ni mo fo

  • AWON ENIA:
  • Ohun rere nlo n’iyen o
  • Ile meji l’ehingbeti
  • Ile meji l’Agege
  • Ohun rere nlo n’iyen
  • E wi ka k’a gbo o ara mi

  • ONIGBANJO:
  • Kilo tun wi o ara mi
  • ENITIN NRA ‘JA
  • Apo mefa ni mo wi
  • Apo mefa ni mo wi
  • Ogun apo ni mo wi
  • Ogun apo ni mo fo
  • Mo fi poun mefa kun

  • AWON ENIA:-
  • A ra’ja tan a nrele e l’aiye
  • K’ Oluwa ma l’ atunri wa o (2)
  • K’ a gbadun egba owo
  • At’ ewon orun t’a ra
  • A raj a tan nrele l’aiye
  • K’ oluwa ma k’ atunri wa o

  • KEHINDE SI GBA OWO OHUN INI RE TI A TA

  • KEHINDE;-
  • Ongbanjo mo de mo de
  • Onigbanjo mo de o
  • Mo wa gb’owo mi leselese
  • Mo wa gb’ owo mi a gbo o
  • Onigbnjo o mo nroju

  • ONIGBANJO –
  • Ogun apo re owo ile
  • Ogun apo re owo ile
  • Egba owo ewon orun
  • Ogunpoun l’owo won
  • Kehinde o omo rere

    ACT III SCENE 2


  • KEHINDE TUN NA GBOGBO OWO RE NI
  • ILE ONITETE O SI KU SU ILE OTI
  • NI ORU OJO KAN

  • AWON ONITETE

  • Awa nonitete aiye awa oni baranda oja (2)
  • A ko mo bi t’ owo sin lo nina l’owo o
  • A ko mo bi t’owo sin lo tita l’oja
  • Enikeni ti o ‘owo ko ba si le na
  • O di eru owo o
  • Awa onitete aiye awa onibaranda oja
  • Awa onitete ayie awa onibaranda oja (2)
  • L’ayie l’a o fi sile lo, ayie l’a b’owo (2)
  • Enikeni t’o l’owo ti ko ba si le na
  • O di eru owo
  • Awa onitete aiye awa onibaranda oja
  • Awa onitete ayie awa onibaranda oja (2)
  • A ko ‘mo bi t’owo sin lo nina l’owo
  • A ko ‘mo bi t’owo sin lo tita l’oja
  • Enikeni t’o l’owo ti ko ba si le na
  • O di eru owo
  • Awa onitete aiye awa onibaranda oja
  • Eyi je eyi o je (hen)
  • Eyi je eyi o je rara (hen)
  • Awa onitete aiye awa onibaranda oja
  • Eyi je eyi o je (hen)
  • Eyi je eyi o je rara (hen)
  • Awa onitete ayie awa onibaranda oja etc

  • ILE OLOTI
  • Ile oloti ile alayo
  • Awa onibaranda oja (2)
  • Ile elerokero ile oniwakuwa
  • Ile omo to sonu lo
  • Ile oloti ile alayo awa onibaranda oja (2)
  • A mi sire lo awa onibaranda oja
  • A mi wole lo awa onibaranda oja

  • NIGBATI TAIWO SI GBO PE KEHINDE TI KU SI ILE OTI ON NA SI LO O SI KU SIBE PELU
  • TAIWO:
  • Pagidari (2) igi da o
  • Kehinde aburo mi, Kehinde ara wa
  • O ku sile oti l’ayie o a
  • Kehinde o se ohun re
  • Nje e gbo ara mi
  • Nko le nikan ma s’ayie lo
  • Nko le nikan rin irin ajo
  • Lat’ayie yi lo titi d’orun
  • Afi bi mo ku pelu re o
  • E o ya mi afi bi mo ku pelu re o
  • A o ya mi afi bi mo ku pelu re o

    ACT III SCENE 3


  • Awon ibeji meji na si pada de orun lehin iku won li ayie, Awon angeli fi tayotayo gba Taiwo
  • sugbon ran Kehinde pada si ayie lati lo tun iwa re se.

  • AWON ANGELI:
  • A ojo pe, a ojo ko
  • Eda ayie nkorin ogo, eda orun nyo sese
  • Olodumare Oluwa Oba nyo l’orun
  • Edumare gbo’ owo wa o
  • Won mbo won mbo l’ona (2)
  • Awon to fi wa sile lo ye
  • Won mbo l’ona o
  • Awon ibeji meji
  • Tayielolu omo wa, omokehin o gba’ gba
  • Awon t’o fi wa sile lo ye
  • Won mbo l’ona o
  • E o lo pade won
  • E o lo pade won l’ona
  • K’e mu won de ‘le ola
  • K’e mu won d’orun ogo
  • Rere rere l’Oluwa
  • Ko mada enikan fun ibi
  • Ko ma da enikan fun aro
  • A! fi eni ba f’owo ara re
  • Ti o fi fa ibi
  • Eni t’o ba se rere
  • A tun pada wa ri’re
  • Eni t’o ba se ibi
  • A tun pada wa ri ibi
  • T’ibi t’ire l’o irin papo lojo ayie o
  • Edumare l’Oluwa Oluwa esan
  • .............................................
  • E ku abo o, e ku abo omo
  • Enyin ibeji meji Tayielolu omo wa
  • Omokehin o gba ‘gba
  • E wa s’alaye fun wa
  • B’e ti se ‘le ayie o
  • Ki e to pada s’orun
  • Bi e ba s’ayie re
  • E je ki a gbo s’eti
  • Bi e ba si b’ayie je o
  • E je ki a mo dandan
  • Eni ba s’ayie re Olorun a mo o

  • KEHINDE:
  • Enyin Angeli l’orun, enyin angeli l’oke
  • E ye e gbo ara mi
  • Gba mo de ile ayie
  • A bi mi s’ebi rere
  • Baba mi l’owo l’owo
  • Ya mi b’etan s’ehin
  • Idile owo, idile ola
  • Idile ola ni mi o ara e gbo o
  • ‘Gbati mo d’agba s’oke
  • Mo wa lo k’egbe k’egbe
  • Mo wa lo yiya kiya
  • Mo f’ile oti se ‘le
  • Mo fi ile ewon s’oja
  • Awon oni tete ayie
  • Awon onibaranda oja
  • Awon ni won pa mi
  • L’okan da ti mo fi d’eni orun
  • Abo mi re o Oluwa
  • Ara e gbo o

  • TAIWO:
  • Enyin Angeli l’orun, enyin angeli l’oke
  • E ye e gbo ara mi
  • Gba mo de ile ayie
  • A bi mi s’ebi rere
  • Baba mi l’owo l’owo
  • Ya mi b’etan s’ehin
  • Idile owo, idile ola
  • Idile ola ni mi o ara e gbo o
  • ‘Gbati mo d’agba s’oke
  • Taiyelolu d’eni re
  • Mo m’ona t ii se rele
  • Mo m’ona t ii s’ona ire
  • Mo ranti pe Olodumare
  • L’oba ti nsohun re
  • Abo ma re Oluwa
  • Ara e gbo o

  • AWON ANGELI:
  • E ye e gbo ara mi
  • E ran Kehinde pada
  • K’o tun pada lo s’ayie o
  • K’o wa lo tun ‘wa re se
  • Gbat’o ba pada s’ayie o
  • K’o lo j’omo afoju
  • K’o d’eni ti ntoro je
  • K’o j’eni ti ko l’ewa
  • T’o ba ronu p’iwa da
  • T’o ba m’Oluwa l’Oba
  • K’o tun pada wa s’orun
  • K’a mu de ‘le ola
  • K’a mu u d’orun ogo
  • Rere rere l’Oluwa
  • Ko ma da enikan fun ibi
  • Ko ma da enikan fun aro
  • A! fi eni ba f’owo ara re
  • Ti o fi fa ibi
  • Eni t’o ba se rere
  • A tun pada wa ri’re
  • Eni t’o ba se ibi
  • A tun pada wa ri ibi
  • T’ibi t’ire l’o irin papo lojo ayie o
  • Edumare l’Oluwa Oluwa esan
  • ..............................................................
  • ..............................................................
  • ..........................................
  • Taiyelolu omo wa
  • ........................................
  • O seun omo odo, omo odo Oluwa
  • Bo sinu ayo Oluwa
  • Ti ko nipekun
  • A ara mi, a ara mi o
  • Eni ti mbe laye
  • K’o ranti pe iku mbe
  • Omi omi l’enia
  • B’o ba san wa a tun san
  • Pada eda ayie mbo o nlo
  • A t’orun bo wa j’ayie
  • A t’ayie pada s’orun
  • Edumare awa mbe O o
  • Dariji omo enia o

  • THE END

  • All Rights Reserved