King Solomon


  ITAN ERE NA


 • Araiye e wa kawa korin ogo s’Oluwa
 • Angeli e bo kawa korin iyin so’ke o
 • Adajo aiye adajo ile adake dajo o l’Oluwa
 • Ba o ba sere wa jere ire
 • Ba o ba e ka wa jere ika, Eledumare l’Oluwa
 • K’ ma son ika ki sawa wa
 • B’enia se ibi a jere ibi
 • B’oba seka ika awa jere ika
 • Adajo aiye adajo ile adake dajo l’Oluwa wa
 • Adajo ile o
 • Oba Dafidi Oluwa Oba to d’ade aiye
 • O pa Uraya sinu ogun o si mu aya Uraya o
 • O fi wa saya o nile oba Edumare gbo lorun
 • Dafidi wa jere ese, Dafidi wa jere ibi
 • E ma se gbagbe o p’eni ba sere a jere ire
 • P’eni ba seka a jere ika adajo aiye adajo ile
 • Adake dajo o l’Oluwa wa adajo ile o
 • Solo o ri Oluwa omo Dafidi baba
 • O gori aiye o joye Dafidi baba
 • Oba kiniun aiye oba koroko lorun
 • Ajan ku mi gbo ki ikiji loju aiye
 • Ko saja to le layako foju dekun dandan
 • Alagbala wura omo Dafidi baba
 • Edumare ranti re Solomoni o
 • Solomoni ni oluwa omo Dafidi baba
 • Gbat’o se rubo loru Oluwa wa l’ara han
 • Oluwa wa fun logbon Oluwa wa fun loye
 • Lati se dajo aiye lati se dajo ile
 • Solomoni Oluwa (2)
 • A dupe fun ogbon re adajo ile o
 • Ki yio si soba saju ki yio si oba lehin
 • Ti yio dabi re Solomoni ola ti ndajo aiye
 • Solomoni Oluwa omo Dafidi baba
 • O dajo fun araiye o dabi Oluwa
 • Agbere aya to sun li orun
 • To pa omo re li a pa dorun
 • To gbomo olomo pon emi o ri iwo o ri
 • Awa o ro eda kan o rii
 • Solomoni oba to ndajo aiye o
 • Edumare loba onidajo orun
 • Obi kole Oluwa oba satogun ona
 • Okiki oba wa kan sori awon ile gbogbo
 • Ayaba Seba lati le jinjin wa koba wa
 • Gbat’o de ile oba ohun gbogbo wadeto

 • O way a Seba lenu iku baba orisa
 • Okiki ki ipowo, okiki ki ipoja
 • Eni rere lo bi o Solomoni o
 • K’a to r’erin o digbo o k’ato r’efon o d’odan
 • K’ato r’adajo iru re, o di ‘le Oluwa
 • Awa nrele o Solomoni oba ti ndajo aiye
 • Igb’ojo s wo, t’ jo dojo ale e gbo o
 • Edumare je ka gogun omo sile k’ai lo
 • Solomoni oluwa o jogun baba re o

  ACT 1 SCENE 1


  AWON ARA SEBA SI MU AYA URAYA WA

  FUN OBA DAFIDI LATI SE AYA


 • Kabiyesi o oba nla, kabiyesi o oba agba
 • Kabiyesi o Dafidi wa, asoju aiye to tun
 • Pada d’asoju oba Edumare
 • O a to l aiye to tun lorun asiri aiye o di tire
 • Iwo to sore Baba lorun. A baba Dafidi o
 • Iyawo Uraya la mu wa o iyawo omo aborisa
 • Ehin fun jowo amororo aponbepore aweroro
 • K’ole wa pada d aya oba
 • K’ole wa pada d’eni ola o
 • Enitoti’mi sun ‘le oko ko le w pada sun le
 • A! baba Dafidi o
 • To gbe mi de ‘le o ile oba, a ‘baba Dafidi o
 • Emi ti mo to nsun le oko
 • Mo tun pada wa nsun le ola
 • Emi to jaya aborisa mo tun pada wa daya oba
 • Mo tun pada wa d’eni ola o
 • Mo dupe lowo ori mi
 • To gbe mi dele o ile oba, a! baba Dafidi o

 • OBA DAFIDI FI AYO GBA BATSEBA GEGEBI IYAWO

 • Inu mi dun o dun si olufe mi
 • Ehin fun jowo amororo iyawo mi
 • Nje ma bo (2) Bo wa s’owo otun mi o (2)
 • Ko wa pada d’aya oba lati wa pada deni
 • Lati joba nibe titi aiye o Iyawo mi o

 • AWON ARA ILU SEBA SI NBA A YO FUN IDALOLA NA

 • Iyawo Uraya la mu wa o. Iyawo omo aborisha
 • Ehin fun jowo amororo, aponbepore aweroro
 • Kole pada wa daya oba. Ko le pada wa deni
 • Enito ti mi sun le oko lola o
 • Kole wa pada sun le oba, A ! baba Dafidi o

 • INU BATSEBA SI DUN LOPOLOPO LA TI
 • DI AYA OBA O SI NYO

 • Ori ‘ re o ori ‘re o
 • Ori buruku ki ngbogun odun o
 • Ori iwefa tun wa d’aya oba o
 • Aropin ni t’eda aropin nt’enia ara
 • K’o ma s’eni to le ri opin enia ara
 • Talaka ti ko ku tun le pada d’elesin
 • Ori iwefa tun wa daya oba o

 • AWON WNIA OBA DAFIDI SI NBA A YO PELU

 • Batseba o wi i ‘re o
 • Ori buruku ki gbogun odun o
 • Ori iwefa tun wa d’aya oba o
 • Aropin ni t’eda aropin ni t’enia
 • Ko ma s’eni to le ri opin enia ara
 • Talaka ti ko ku tun le pada d’elesin
 • Ori iwefa tun daya oba

 • BATSEBA SI TUN DA ‘RIN BAYI PE

 • Araiye e mura ara on ba mi yo
 • E ba mi gbohun soke ka k’orin iyin s’Oluwa
 • Araiye ma mi bow a gbona ara de ‘le o

 • AWON ENIA DAFIDI SI TUN DAHUN BAYI PE

 • Batseba aya oba o wi ire o
 • Ori buruku ki ngbogun odun o
 • Ori iwefa tun wa d’aya oba o
 • Aropin nt’eda aropin ni t’enia ara
 • Talaka ti ko ku tun le oada d’elesin
 • Ori iwefa tun wa daya oba o

 • WOLI NATANISI WA LATI BI ESE DAFIDI
 • HAN A O SI PA OWE MO LARA BAYI PE

 • Oba Dafidi mo wa ri o, mo ni ejo kan lati fi
 • Ni ti ese kan to ga julo ninu ijobati nse tire
 • N’ibi tokunrin meji gbe wa
 • Okan je oloro to ri je talakani keji ti ko ri je
 • Opolopo ni agutan ati malu t o sanra
 • Ninu agbala ti lo o sugbon talaka ara keji
 • Ko ni kinikan t’on sin bi ko s’agutan kekere
 • Bi ko saguntan kekere kan
 • Nwon jijo nje ninu awo
 • Nwon jijo nmu ninu ago
 • Nwon jijo nsun lori aga
 • Nwon fe ara won ju emi lo Baba Dafidi o
 • O si se l’ oru ojo kan alejo wa ba oloro
 • O si ko lati meyo kan ninu aguntan ti o sanaa
 • O si mu agutan talaka yen kafi salejo loru yen
 • Baba Dafidi o

 • INU OBA DAFIDI SI RU SOKE O FI
 • IBINU DAHUN BAYI PE

 • Bi Oluwa mbe laiye
 • Okunrin to se buburu yen
 • K’afi s’ alejo loru yen
 • Kiku ni yio lu o jebi
 • WOLI NATANI SI JA OWE FUN OBA
 • DAFIDI BAYI PE

 • Iwo, iwo lokunrin na o jebi
 • Iwo to kegan oro Oluwa
 • Iwo si fid a Uraya
 • Iwo si maya Uraya o, eniti nsomo aborisa
 • Lati wa pada d’aya oba o a! Dafidi o ti jebi
 • Nje nitorina ko gbo o Ida mi yio kuro nile re
 • Titi aiye o, emi yio o si je k’ ibi dide
 • Lati inu ile ti ‘wo gbe wa
 • Awon obirin ti wo ni o
 • L’a o ya kuro lata re lao gba kuro lara re
 • Oba Dafidi o

 • ERU MU OBA DAFIDI OSI NBEBE
 • FUN DARIJI

 • Gba mi o Natani o (2)
 • Emi ti dese si Olorun gba min, Natani o

 • OLORUN SI TI ENU WOLI
 • SORO BAYI PE

 • Olorun baba to ga lorun
 • L’o ti mu ese re kuro
 • Gba mi gbo o, Dafidi mi
 • E ki yio ma ku o
 • Sufbon nitori iwa re
 • Omo kunrin ti abi fun o
 • Kiku ni yio ku o
 • Oba Dafidi o

 • AWON ANGELI OLUWA SI NJERISI
 • ISUBU OBA DAFIDI

 • Isubu aiye, e wa
 • Wo subu aiye loni o
 • Oba Dafidi nf’ aya kan
 • Oba Dafidi ngba’ yak an
 • Oba t’ o nd’ ade ade aiye
 • Tun pada wa gb’ aya aborisa
 • Adake dajo l’ Oluwa wa
 • Ako-ma-gbela l’ Olorun
 • Ojo ekun ku si dede
 • Ojo ekun sun mo o
 • Isubu aiye E e wa
 • Wo ‘subu aiye loni o
 • Isubu eda o

  ACT 1 SCENE II


 • SOLOMONI SI JOBA NI IPO DAFIDI
 • BABA RE AWON ENIA RE SI NYE E SI

 • Kabiyesile a ki oba t’ o d’ade owo
 • Kabiyesile oba to ga ju won lo
 • Solomoni oluwa omo Dafidi baba
 • Oba t’ o f’owo mo le
 • T’ o fi ‘leke se ogba
 • Alagbala wura omo Dafidi baba
 • Edumare ranti re, Solomoni o
 • Oba kiniun aiye oba kori o l’ orun
 • Ajanaku mi ‘gbo kijikiji l’ oju aiye o
 • Ko s’ oju t’ o le l’ aya
 • K’ o f’ oju d’ ekun dandan
 • Alagbala wura, omo Dafidi baba
 • Edumare ranti re Solomoni o
 • Ki gba re san wa laiye o omo Dafidi
 • Ki gba re san l’orun o omo Dafidi
 • Jowo wa s’ aiye ‘re k’o si f’ otito joba
 • Ko ranti pe toba t’enia ni yio ma ku o
 • T’ao papo lati wa jihin ise aiye
 • Alagbala wura omo Dafidi baba
 • Edumare ranti re Solomoni o

 • OBA SOLOMONI SI FI AYO ATI IRELE
 • DA AWON ENIA RE LOHUN BAYI PE

 • Enyin olola, enyin agbagba
 • Enyin oselu enyin igbimo
 • Enyin Balogun ninu ogun Dafidi baba
 • E feti bale e fokan bale
 • Tori Oluwa l’Oluwa layekaye
 • E je ka gbekele l’ Oluwa to ga ju wa lo
 • Enyin ti e wa ba mi yo l’ ojo oni
 • Mo dupe fun baba orun ologo meta
 • A f’ emi a f’ enia f’ emi a f’ Oluwa
 • Ko s’aja to le laya
 • Ko foju dekun dandan
 • Alagbala wura omo Dafidi baba
 • Edumare ranti mi Solomoni o

 • AWON ENIA RE SI DUPE LOWO RE
 • PELU NWON SI NSE ADERA FUN U
 • A! E! Solomoni Oluwa o
 • A dupe lowo re a dupe tokantokan
 • Omo Dafidi baba
 • Af’ iwo a f’ enia a f’ iwo a f’ Oluwa
 • Edumare ranti re Solomoni o
 • Enyin ara ea enyin iwofa
 • Enyin Balogun enyin Ijoye
 • Enyin omode aiye o
 • Ao f ‘iyin fun baba ao fiyin f’enia
 • Awon to fi o joye eku igbimo baba
 • A fiwo a f’ enia a fi wo a f’ Oluwa
 • Ko s’ aja to le laya ko f’ oju dekun dandan
 • Alagbala wura omo Dafidi baba
 • Edumare ranti re Solomoni o
 • A! beni awa se hun!
 • Erin jogun ola erin jogun baba re
 • Gbojo se wo tojo dojon ale e gbo o
 • Edumare je ka fogun omo sile lai lo
 • Solomoni oluwa jogun baba re o
 • Ina ku feru boju
 • Ogede ku f’ omo ropo baba Dafidi
 • Igba ojo nrekoja lo igba otutu mbo
 • Igba erun ni yio jogun toye totutu dandan
 • Solomoni Oluwa o jogun baba
 • A! beni awa se hun!!!
 • Erin jogun ola o erin jogun baba re
 • ‘Gbojo se wo t’ojo dojo ale egbo o
 • Edumare je ka fogun omo sile kai lo
 • Solomoni oluwa o jogun baba re
 • Baba laiye o (Hun !!!)
 • Baba lorun o (Hun !!!)
 • Baba to d’ade aiye to tun feti bale
 • Boya won a tun pe on lorun (Hun !!!)
 • Solomoni Okuwa jogun baba re
 • A beni tiwon se hun
 • Erin jogun ola erin jogun baba re
 • ‘Gbojo se wo t’ jo dojo ale o gbo o
 • Edumare je ka f’ ogun omo sile kai lo
 • Solomoni oluwa j’ ogun baba re o

  ACT II SCENE I


 • AWON AYA SOLOMONI NSE ARIYA NI TI
 • IWUYE OKO WON NWON SI NKE OKIKI RE

 • Awa aya Solomoni baba de o
 • Awa aya Solomoni baba de o
 • Baba legbafa aya
 • O legberin iwefa
 • Oba f’ ola jogun o Oba f’ ola jogun o
 • Ko sohun to mbo loke ti owo wa ko ka
 • A f’ awa a f’ enia a f’ awa a f’ Oluwa
 • Solomoni o Solomoni o
 • Ola igi ni ‘na fi njo l’ aiye
 • Eni t’ o ba pe kil’ a o da
 • Onwa yonu ni

 • O b’awon ota wa l’odi l’eso
 • Alawo mejo
 • A f’awa a f’enia a f’Oluwa
 • Solomoni o Solomoni

 • AWON OLORI OBA SOLOMONI SI
 • NKE OKIKI RE PELU

 • Enia lo laiye enia lo lorun
 • E wa wo oba ile aiye
 • Tani le ri oba ile orun ko ye
 • Solomoni o
 • B’ o wu igi a wo we
 • Eda kan o mehin ola
 • We, we, opebe o di le o
 • Solomoni o
 • Solo, Solomoni dade ob ire de
 • E mase soro oba lehin o
 • E mase soro oba lehin o
 • A Solomoni
 • Solomoni baba gbere o
 • Baba o tele yi pe o
 • Baba o tele yi pe o
 • Lola awa o
 • Baba ate le yi pe o
 • Lola Oluwa
 • Ade a pe lori bata a pe lese re o
 • Enikeni ti ko ba si gba
 • Ko lo ri sokun
 • A binu eni ko ma le yi kadara wa po
 • Ota nse lasan ni ko le ri wa mo o
 • A Solomoni o
 • Solomoni baba gbere o

  ACT II SCENE II


 • OBA SOLOMONI SI LO SI GEBEONI LATI
 • SE RUBO SI OLORUN AWON ARA ILU
 • NA SI GBA A TOWO TESE

 • E ma wole Solomoni
 • Oba Oluwa tiletile
 • E ma wole Solomoni
 • Oba Oluwa tonatona
 • Iwo to d’ade owo
 • Iwo to wo bata ileke wa
 • Omo Dafidi baba wa
 • A toba tele ko to joba
 • Iwo t’o fowo fowo mole
 • Iwo t’o fi’ leke se ogba
 • Edumare t’o yan o loba
 • K’o f’emi re gun l’oju wa
 • Kiniun oba a bi’jakankan
 • Solomoni o
 • Oba t’o ti l’egberun aya
 • T’o ti l’egbrin iwofa
 • Ati wundia ota-le-legbeje
 • Enyin agbagba enyin oselu
 • E gboju s’oke, k’e k’oba wa
 • Eni to fowo fowo mole
 • Iwo to fi leke se ogba
 • Edumare to yan o loba
 • Ko f’emi re gun loju wa
 • Kiniun oba abija Kankan
 • Solomoni o
 • Nje a be e lowo oba
 • Eredi ti oba wa
 • Dide lati wa se ibewo
 • Awa ara oko at’ra egan
 • Awa tin sun ‘le ole oko
 • Awa tin sun ‘le ile omi
 • O ya wa lenu tile tile
 • O ya wa lenu tona tona
 • Lati r’oba wa o ni ‘le wa
 • Edumare t’o yan o f’oba
 • K’o f’emi re gun loju wa
 • Kiniun oba abija kikan
 • Solomoni o

 • S0L0MONI OBA SI FI IRELE DA WON
 • ENIA NA LOHUN PE

 • Enyin olola, enyin agbagba
 • Enyin oselu, enyin igbimo
 • E mase je k’ oya nyin l’enu
 • Lati ri oba ni ‘le egan
 • Oba to l’aiye t’otun l’orun
 • Ko ma d’eni kun si ‘le omi
 • Ko ma d’eni kan si ‘le egan
 • Sugbon gbogbo wa l’ omo ogo
 • Sugbon gbogbo wa l’ omo iye
 • ‘Gbat’ a ba pari ise laiye
 • T’ oba t’ enia yio si papo
 • Lati yin Oluwa oba oba ogo
 • Enit’ O da mi sile aiye
 • Ati Dafidi Baba mi
 • To fi mi joye baba mi
 • E ma ku ile o ara mi
 • Alafia ko le wa bi o
 • Edumare yan mi l’oba
 • Ko f’emi mi gun loju wa
 • Kiniun oba abija kikan
 • Solomoni o

 • AWON ENIA NA SI FI ARA MO IMORAN OBA SOLOMONI

 • A Solomoni oba wi ire o
 • Oba t’O laiye to tun lorun
 • Ko ma denikan sile
 • Ko ma denikan sile egan
 • Sugbon gbogbo wa lomo ogo
 • Sugbon gbogbo wa lomo iye
 • Gbat’ a ba pari ise aiye
 • Tao sib ago ara sile
 • T’oba t’enia yio si papo
 • Latin yin Oluwa oba ogo
 • Baba to d’aiye
 • At’ enyin ero ti e wa
 • At’ enyin ero ti e bo
 • Ti e b’ o a wa de ‘je o
 • E wi fun wa, o ara wa
 • Eredi re, li l’ e ba wa o
 • E a ara e wi k’agbo

 • OBA SOLOMINI SI DAHUN BAYI PE

 • E gbo ara, mi
 • A wa se ‘rubo a wa s’aito
 • A si wa juba fun ola nla
 • Olodumare, Olugbala
 • B’akere juba, omi a to
 • B’ ekolo juba, ile ala
 • Eniti o juba, oba ogo
 • O s’ ori ara re d’ ori re
 • Nje Edumare, ye o awa juba o
 • Ki ‘ba wa le se l’ oju aiye

 • AWON ENIA SOLOMONI SI GBE OBA SOLOMONI L’ ESE PE

 • A o yi o awa se rubo awa saito
 • A wa juba fun ola nla
 • Olodumare Olugbala
 • B’ akere juba, omi a
 • B’ ekolo mjuba, ile a la
 • Eniti o juba oba ogo
 • Os’ ori ara re d’ ori re
 • Nje Edumare ye o, a wa juba o
 • Ki ‘ba wa le se l’ oju aiye

 • OBA SOLOMONI SI SE IRUBO NI ILU GEBEONI

 • A wa iya, iya, a mi rubo o
 • E re a mi rubo, Olugbala
 • Ariwo aiye ye ye ye ye
 • Awa iya a mi rubo o
 • Awa baba,baba, a mi rubo o
 • E re ami rubo Olugbala
 • Atiwo aiye, ye ye ye ye
 • Owenren, ami rubo o
 • Enyin omode, k’ e m’ Oluwa
 • Ariwo aiye, ye ye ye ye
 • Awa iya a mi rubo o
 • Enyin agbagba, k’e m’Oluwa
 • Ariwo aiye, ye ye ye ye
 • Awa iya, a mi rubo o
 • Enyin aboyun, k ‘e f’ owo s’osun
 • Abiyamo
 • Ariwo aiye, ye ye ye ya
 • Awa iya a mi rubo o
 • Enyin ijoye k’ e m’Oluwa
 • Ariwo aiye, ye ye ye ye
 • Awa iya, a mi rubo o
 • Enyin balogun nini ogun, ye ye o
 • Ariwo aiye, ye ye ye ye
 • Awa iya a mi rubo o
 • E! torotoro omi san e
 • Omi re
 • Omi san ! Ona tororo
 • Omi re
 • Omi san lo ona tarara
 • Omi re
 • Olumo dade owo
 • Ona ire
 • Olumo d’ona ola
 • Ona ire
 • Ona owo, ona omo
 • Ona ire
 • Ona aiku, ona airun
 • Ona ire
 • Orun oke gb’owo wa
 • Oware gba pa
 • Iwo t’o n’ile, gbewo wa
 • Owa re gbapa
 • Iwo gba pa, emi gba pa
 • Oware gba pa
 • K’aiye ilu toro k’ona ilu toro
 • K’aiye wa dun, k’o dun ju ‘le oyin lo
 • Ariwo aiye ye ye ye ye
 • Awa iya, a mi rubo
 • E arala an la, ode isawereo
 • Ode isa were o Olumennekunene o
 • E arala, arala ode osawere
 • Ode isawe e r’Erim fi re bi tele o

 • GBOGBO AWON ENIA SI FI OBA SOLOMONI
 • SILE LATI SUN NWON SI NKI I PE O DI OWURO

 • A dupe olore o a dupe o olore
 • K’a ki le k’a k’ ona ara wa e
 • Ki oba wa ko sun ko sun re e
 • A dupe olore o a dupe olore o
 • Ologose eiye igbo adaba eiye odan
 • Owenren eiye ogo
 • K’a ki le ka kona ara wa e
 • A dupe olore o a dupe o olore o
 • Ologose eiye igbo adaba eiye odan
 • Owenren eiye ogo
 • K’oba wa sun ko sun re o
 • A dupe olore o a dupe o olore o
 • Ologose eiye igbo aluko eiye osa
 • Owiwi eiye oru
 • K’oba wa sun ko sun re o
 • A dupe olore a dupe o olore o

 • OLUWA SI KO SI SOLOMONI LI OJU ALA BAYI PE

 • Omo mi a gboju soke o
 • Arole ile Oluwas Solomoni o
 • Alade aiye alade orun oba to fileke bora lai e
 • Oba to fileke bora o
 • Eledumare ye o a juba o Solomoni o
 • Nje bere (2) Nje bere ohun li wo fe o
 • Bere ohun ti wo yio gba wo ba bere
 • Bere ohun t’ogba julo ohunkohun ti
 • Titi lo borun to ga julo
 • L’ao fi fun o tile tile l’ao fi fun o tona tona
 • Bere ohun ti wo ge o, Solomoni

 • SOLOMONI OBA SI GBE OHUN OPE
 • S’OKE O SI MU IBERE RE WA BAYI PE

 • Mo dupe oba to ga julo
 • Eni to gbe mi sip o ola o
 • To fi mi joye baba mi o
 • Eniti o ti rin ninu ona
 • To dara ju loju re Baba Dafidi o
 • Ati emi se omo kekere ni mo nse
 • Beni nko logbon beni nko loye
 • Mo si njoba sibesibe
 • Lori omode ati agbalagba
 • Awon amoye gigagiga o
 • A o yi o, Eledumare ko gbo
 • Nitori eyi o Oluwa wa
 • Fun mi ni oye giga lorun
 • Lati se dajo awon enia
 • Lati se dajo awon omo Re
 • Lati mo yato buburu
 • Ati iyato rere o

 • OLUWA SI TI ENU AWON ANGELI
 • RE DA SOLOMONI LOHUN BAYI PE

 • A o wi ire, A o fo re
 • Arole ile Oluwa Solomoni o
 • Nitoriti o gbero rere
 • Niroriti o huwa rere o
 • Ti o bere iyi ara
 • Ti o ko bere emi gigun
 • Al’emi tin se l’ola re
 • Iwo sib ere oye giga
 • Lati se dajo ara aiye
 • Ati enia ile gbogbo
 • Arole ile Oluwa Solomoni o
 • Emi yio fun o bi o ti fe
 • Emi yio fun o bi o ti yan
 • Emi yio fun o lebun ogbon o

 • At’ebun ola a t’ebun ola
 • Ati ebun owo at’ ebun omo
 • Ki yio si s’oba saju
 • Ki yio si s’oba lehin
 • Ti yio dabi re laiye o
 • Arole ile Oluwa Solomoni o

 • AWON ANGELI SI NSE ARIYA NIPA TI
 • IYONU OLUWA SI OBA SOLOMONI

 • Ye !!!
 • Oro yi d’orun, oro yi d’orun
 • Awa ti ko ‘rin ogo, awa tin sere iye
 • Awa ti ns’alagbawi o, lodo Baba
 • Ti ns’aiye yi di ire o
 • Ye !!!
 • Oro yi do’run, oro yi do’run o
 • Enit’o logbon ori o
 • Enit’o lognon okan
 • Eni fe saiye ogo
 • K’ofakan bale
 • Ye !!!
 • Oro yi d’un o

  ACT II SCENE III


 • SOLOMONI OBA SI JOKO LORI ITE
 • IDAJO AWON NA A SI NJUBA R
 • E ma ku abo Solomoni
 • E ma ku abo, baba awa
 • Iwo t’o dade ade owo
 • Iwo t’o wo bata ileke
 • Iwo t’o ni wa, juba o
 • Adajo aiye o
 • O ti se ‘rubo, o ti s’aito
 • O sanwo osun o sanwo adin o
 • O ti r’Oluwa l’oju koju
 • O ti r’Oluwa lona-kona
 • O bere ogbon, o bere ore
 • Eyi t’o ku se o o d’owo re
 • Iwo to ni wa a juba
 • Adajo aiye o
 • Ire, ire owo ire, ire, ogo
 • O f’ara s’aiye o f’okan s’orun
 • O mba t’aiye t’orun soro
 • O j’oba l’aiye, o j’oye l’orun
 • Iwo to ni wa a juba o
 • Adajo aiye o

 • SOLOMONI OBA SI DA AWON ENIA NA LOHUN PE

 • E gbo mi ara mi
 • Mo ti se rubo mo ti saito
 • Mo sanwo osun mo sanwo adin o
 • Mo ti r’Oluwa lojukoju
 • Mo ti r’Oluwa lonakona
 • Mo bere ogbon mo bere oye
 • Eyi toku se o dowo re
 • Edumare ye o mo wa juba o
 • Adajo aiye o

 • AWON ENIA TUN DAHUN BAYI PE

 • Ire, ire owo ire, ire oge
 • O f’ara s’aiye, o f’okan s’orun
 • O mba t’aiye, t’orun s’oro
 • O j’oba l’aiye, o j’oye l’orun
 • Iwo t’oni wa, a juba o
 • Adajo aiye o

 • SI KIYESI AWON ABIYAMO MEJI SI KO ARA WON WA
 • SIWAJU OBA SOLOMONI FUN IDAJO OKAN NINU NWON SI WIPE

 • A Solomoni, oba nla
 • A Solomoni oba mi
 • Adajo aiye adajo ile
 • Mo wa f’ejo kan sun o ye e
 • Ejo ipania, ejo ole
 • Mo wa f’ejo kan sun o ye o
 • Adajo aiye
 • Jowo oluwa, oba mi
 • Se o r’obinrin ti o ri yen
 • Igara ole, aj’omo gbe o
 • Awa meji ni ngbe ile kan
 • Abiyamo si l’awa meji
 • Ko s’eni ti ngbe ile yen
 • A f’awa meji l’aiye o
 • A oba k’o o gbo seti
 • Gbat’osun l’omo re li oru
 • L’omo re ba wa d’ogbe o
 • L’o bag be omo re t’o ti ku
 • O si te e sile l’aya mi
 • O si gbe aye omo mi
 • Lo si aiya re laye o
 • A oba kio gbo s’eti
 • Gbati mo dide li owuro
 • Lati fi omu fun omo mi
 • A o ti ku, A o ti sun
 • Gba ti o si wo li owuro
 • Ki ise omo ti mo bi o
 • Mo wa f’ejo kan sun o ye o
 • Adajo iye o

 • OBIRIN EKEJI SI DAHUN BAYI PE

 • Iro l’emi pa eke l’emi se
 • Eke odale alakora
 • Agboju logun f’ara re f’osi ta
 • Lasan lon tan ra re je
 • Eyi oku yen l’omo re
 • Eyi alaye l’omo mi o
 • A oba ko gbo seti

 • OBIRIN OLOMO NA FI TEDUNTEDUN WIPE

 • Bi Iluwa bam be laye
 • Eyi oku yen lomo re
 • Eyi alaye lomo’ mi
 • A oba ko gbo s’eti

 • OBIRIN IKEJI SI FI IBURA DAHUN PE

 • Mo bura ni le mo f’ Olorun seri
 • K’omi Jodani ko pa mi
 • Bi mo ba puro f’ oba mi
 • Eyi oku yen l’omo re
 • Eyi alaye l’omo mi o
 • A! oba ko gbo s’eni

 • OBA SOLOMONI SI KUN FUN OGBON
 • PUPO O SI DAJO NA BAYI

 • E gbo ara mi
 • Eyi sajeji eyi ma yato
 • O dabi ala loju mi
 • Alo lemi pa tabi itan
 • Ekini wipe omo ni t’on
 • Ekeji wipe omo ni t’on
 • Ki lao ti mo eyi si o
 • Ejo ajeji ma re o
 • Araiye egbo o
 • E mu ida wa e gbo o
 • Idajo ma re o
 • E pin alaiye sona meji
 • E si fun okan li apakan
 • Ke fun ekeji li apakan
 • Idajo ma re o

 • Jowo oluwa oba mi
 • E gba alaiye yi, omo na
 • K’e kuku fun fi fun u
 • K’ o ma ba tire lo
 • Oluwa mbe li orun
 • E ye e mase pin wa l’omo

 • SUGBON AGBERE OBIRIN NA TENU MO O WIPE

 • Ko ni je tire, ko ni je t’emi
 • E pin omo na s’ona meji
 • E la omo na s’ona meji
 • Ko ni je t’emi, ko nije tire
 • K’oju gbogbo wa k’o lo mo o
 • Solomoni o

 • SOLOMONI OBA SI MO IYA OMO NA YATO O SI PASE PE

 • E gbe alaye omo na soke
 • E fi f’obirin ti e ri yen
 • On lo l’omo, e gbo
 • Idajo ma re o

  ACT III SCENE I


 • OKIKI IDAJO OLOGBON NA SI YI ILU JERUSALEMU
 • KA AWON ENIA SI NYO AYO NLA

 • Awa ndajo aiye o, awa ndajo ile
 • A ye, ye, ye, ye, ye, o
 • Edumare l’oba onidajo orun
 • Agbere aya t’o sun li orun
 • T’o pa omo re li apa de orun
 • T’o gb’omo olomo pon
 • Emi o ri i, iwo o ri i
 • Awa o ri I, eda kan o ri i
 • Solomoni l’oba adajo aiye o
 • Edumare l’oba onidajo orun
 • Araiye e gbo, araiye e gba
 • Iwa kiwa ko ma ye ‘ni ‘re
 • Bi o nyo ‘le, ti o nse ‘bi
 • T’enikan o f’oju ri o
 • K’o ranti pe ojo esan mbo
 • B’oba aiye ko ri o
 • Oba r’orun a da
 • Solomoni l’oba ti ndajo aiye o
 • Edumare l’oba onidajo orun
 • A dupe fun ogbon re adajo ile o
 • Ki yio si s’oba sa’ju
 • Ki yio si s’oba l’ehin
 • Ti yio dabi re
 • Solomoni, oba ti ‘dajo aiye
 • A eda aiye, A eda orun mbo o
 • Awa nre ‘le o
 • Solomoni oba ti ndajo aiye
 • K’a to r’erin o di gbo o
 • K’a to r’efon, o d’odan
 • K’a to r’eiye bi okin o
 • O di ‘le ile
 • K’a to radajo irure
 • O di ‘le Oluwa
 • Awa nre ‘le o
 • Solomoni oba ti ndajo aiye
 • A eda aiye A eda orun mbo
 • Awa nrele o
 • Solomoni oba ti ndajo aiye


  ACT III SCENE II


 • ORIN SOLOMONI
 • AWON ARA ILU JERUSALEM SI NKO ORIN SOLOMONI

 • A araiye, e yo o
 • A araiye, e yo o
 • Gbati mo dide li owuro
 • Mo ko lati je, mo ko lati sun
 • Mo nw’eni t’okan mi nfe o
 • Mo nw’eni t’kan ni nfa
 • Olufe mi, olufe mi
 • Ehin fun j’owo amororo
 • Apon bepo re, awe roro
 • Obandaji, ye
 • E wa w;ejire, omo a f’oru sun
 • Ejire omo abija-kikan
 • Ejire ara isoku
 • Omo adaro pa ‘le aso
 • E ba mi wa olufe mi
 • Iyawo mi o
 • A araiye o eba mi yo
 • A araiye o e ba mi pe
 • E ba mi gbohun ope s’oke
 • Tori! Mo ri olufe mi iyawo mi o
 • Iwo li ewa omobinrin
 • Iwo to loju bi ti eiyele
 • T’o dubule bi agbo eran
 • Bi a ba w’ehin ehin re
 • O dabi tomo aguntan
 • To si ngoke ninu omi
 • Oju re meji bi t’adaba
 • Adaba ile adaba oko
 • Adaba meji ti ise ejire o
 • Ejire omo a foru sun
 • Omo abija kikan
 • Ejire ara isoku
 • Omo adaro pale so
 • E bami wa olufe mi
 • Iyawo mi o
 • Oju re meji bi t’adaba
 • Adaba ile adaba ile adaba oko

 • Ejire omo a foru sun
 • Ejire omo abija kikan
 • Ejire ara isoku
 • Omo a daro pale aso
 • E ba mi wa olufe mi iyawo mi o
 • Tombolo tombolo a ye
 • Enu eiye tombolo
 • Onijaiye mo re Ijaiye (2)
 • Arakunrin mai lo ijaiye
 • Onijaiye mo re le ijaiye
 • Arakunrin mai lo ijaiye
 • Onijaiye mo rele ijaiye (4)
 • Kawa mo bunrin fobirin ijaiye
 • Onijaiye mo re le Ijaiye
 • K’awa mobirin fokunrin Ijaiye
 • Onijaiye mo rele Ijaiye
 • Onijaiye mo re le
 • Onijaaiye mo re le Ijaiye
 • Araiye fawo mi lo mi Ijaiye
 • Onijaiye mo re le Ijaiye
 • Arugbo f’awo mi lo mi
 • Oniyaiye mo re le Ijaiye
 • Onijaiye mo re le
 • Onijaiye mo re le Ijaiye


  ACT III SCENE III


 • OBA SOLOMONI JOKO LORI ITE AWON ENIA RE SI NYE SI

 • Iba Solomoni o
 • Oba to d’ade ade aiye
 • T’o ns’oloye l’orun
 • Okiki re lo ti kan
 • S’ori awon ile gbogbo
 • Iku baba orisa
 • Okiki ki ip’owo
 • Okiki ki ip’oja
 • Eni rere l’o ni o
 • Solomoni o
 • Iba Solomoni o
 • Ologbon wewe inu aiye e n
 • Oniwa tutu bi ti egbin en
 • Iba omo nla Dafidi
 • Teletele laiye o
 • Ogbon ori enia
 • Diedie l’asan ni
 • Sugbon a dupe lowo re
 • F’ogbon ori re
 • Ogbon to ga ju laiye
 • Ogbon t’o ga ju l’orun
 • Ogbon Olodumare
 • Okiki re ti kan
 • S’ori awon ile gbogbo
 • Iku baba orisa
 • Okiki ki ip’owo
 • Okiki ki ip’oja
 • Eni rere l’o bi o
 • Solomoni o

 • SOLOMONI OBA SI DAHUN BAYI PE

 • Mo dupe lowo yin
 • Enyin enia gbogbo
 • Teletele l’aiye o
 • Ogbon ori enia
 • Diedie l’asan ni
 • Mo dupe fun ogbon ori mi
 • T’Oluwa fun mi
 • Ogbon to ga ju l’aiye
 • Ogbon to ga ju l’orun
 • Okiki mi lo ti kan
 • S’ori awon ile gbogbo
 • Okiki ki ip’owo
 • Okiki ki ip’oja
 • Eni rere lo bi mi
 • Solomoni o

 • AWOM ENIA SOLOMONI SI DAHUN BAYI

 • Iba Solomoni o
 • Ologbon wewe inu aiye e a
 • Oni tutu bi ti egbin e a
 • Iha omo nla Dafidi o
 • Teletele l’aiye o
 • Ogbon ori enia
 • Diedie l’asan ni
 • Sugbon mo dupe l’owo re
 • F’ogbon ori re
 • Ogbon t’o ga ju l’orun
 • Ogbon Olodumare
 • Okiki re l’o ti kan
 • S’ori awon ilu gbogbo
 • Iku baba orisa
 • Okiki ki ipowo
 • Okiki ki ipoja
 • Eni rere li bi o
 • Solomoni o

 • AYABA SEBA SI WA LATI BE OBA SOLOMONI WO AWON ARA ILU JERUSALEM SI GBA TOWO-TESE

 • E ku abo o
 • E ku abo aya’ba
 • Aya ‘ba Seba
 • E ku abo, olola
 • Aya ‘ba Seba
 • O ti gbokiki i re o ti gbokiki wa
 • A ti mo pe olola ni’wo ninu ilu ew
 • O ti mo p’olola l’awa ninu ilu wa
 • Ibi meji lo papo ola meji nlo papo
 • Oba meji lo pade o eku abo aya ‘ba

 • AYABA SEBA SI KI SOLOMONI TOWOTOWO

 • E ku ile o e ku ile o mo ki o towotowo
 • Solomoni oluwa mo ki o lopolopo
 • Solomoni oluwa mo k’eyin agbagba
 • Mo ki eyin oselu mo ki eyin igbimo
 • Mo ki enyin iriju o tomode tagba ile
 • Alafia ko lewa bi mo ki o towotowo
 • Solomoni oluwa mo ki o lopolopo
 • Solomoni oluwa

 • OBA SOLOMONI SI GBA AYABA SEBA TOWOTOWO

 • E ku abo o, e ku abo o ayaba Seba ti wa
 • E ku abo o mo ki o tiletile
 • Mo ki o tonatona awon oselu ki o
 • Awon agbagba ki o awon irinjunile
 • Awon iwefa tiwa t’omo de t’agba ile
 • Alafia ko le bo mo ki o tile-tile
 • Mo ki o t’ona-t’ona Ayaba Seba tiwa
 • E ku abo

 • AWON ENIA SOLOMONI SI NKI OBA NIPA TI ALEJO RE AYABA SEBA

 • Oba Solomoni o E ku alejo
 • E ku alejo wa Aya ‘ba Seba
 • Iba meji lo papo ola meji l’o papo
 • Oba meji l’opade o E ku alejo
 • E ku alejo awa Aya ‘ba Seba o
 • AYA’BA SEBA SI DA AWON ENIA NA LOHUN WIPE

 • Mo ki enyin agbagba mo ki enyin oselu
 • Enyin iriju ile enyin iwefa baba
 • Mo ki o towotowo Solomoni oluwa
 • Mo ki o lopolopo Solomoni Oluwa
 • O ti gbokiki mi o ti mo pe olola l’emi
 • Ninu ilu re okiki re lo ti kan
 • Sori won ile gbogbo okiki ki ipowo
 • Okiki ki ipoja eni rere lo bi o
 • Solomoni o sugbon gbati mo de bi
 • O ya mi lenu poju a ko rohin idaji fun mi
 • Lohun to sele ohun gbogbo wa leto
 • Mo ri awon ikole mo ri awon enia
 • Mo ri awon iranse
 • At’awon wura oba mo ri ile Olorun
 • Ati ategun ona ti o ti ko f’Oluwa
 • Teletele laiye o ogbon ori enia
 • Diedie lasan ni sugbon a dupe lowo re
 • F’ogbon ori re okiki re lo ti kan
 • Sori awon ile gbogbo okiki ki ipowo
 • Okiki ki I p’oja eni rere lo bi o Solomoni o

 • SOLOMONI SI DA AYA’BA SEBA LOHUN BAYI PE

 • Mo dupe lowo re ayaba Seba
 • Awon agbagba dupe Awon iwefa mi yo
 • A dupe lowo re ayaba Seba o ti gbokiki mi
 • Mo ti gbo okiki re o ti mo pe olola l’emi
 • Ninu ilu mi mo ti mo pe olola ni wo
 • Ninu ilu re awon ohun ti o ri
 • T’o si nya o lenu ki sogbon enia
 • Ogbon Olorun wa ni ogbon Olodumare
 • Ko mase ya o lenu
 • Aya ‘ba Seba teletele laiye o
 • Ogbon ori enia d’iedie l’asa ni
 • Okiki I p’owo okiki ki ip’oja
 • Eni rere l’obi mi Solomoni o

 • GBOGBO AIYE SI NYO, NWON NSE ARIYA NLANLA
 • NITIRI OGBON GIGA TOLUWA FIFUN SOLOMONI

 • Tombolo, tombolo aiye
 • Enu eiye tombolo
 • Onijaiye, mo re ‘le Ijaiye
 • Onijaiye, mo re ‘e Ijaiye
 • Arabirin, ma ilo Ijaiye
 • Onijaiye, mo re ‘le Ijaiye
 • Onijaiye mo re le
 • Onijaiye, mo re ‘le Ijaiye
 • K’awa mo m’okunrin f’obirin
 • Onijaiye, mo re ‘le Ijaiye
 • K’awa m’obirin f’okunrin Ijaiye
 • Onijaiye mo re ‘le Ijaiye
 • Onijaiye, mo re ‘le
 • Onijaiye, mo re ‘le Ijaiye
 • Ara ‘ye f’awo mi lo mi Ijaiye
 • Onijaiye mo re ‘le Ijaiye
 • Onijaiye mo re ‘le Ijaiye
 • Onijaiye, mo re ‘le
 • Ori re o, Ori re o
 • Ori buruku ki igbogun odun o
 • Ori iwefa tun wa day’ oba o
 • Aropin ni te’da, aropin n’tenia
 • Ko s’eni t’ole ri opin enia ara
 • Talaka ti ko ku tun le pada d’elesin
 • Ori iwefa tun wa d’aya oba o
 • Batseba, aya oba, o wi ‘re o
 • Ori buruku ki igb’ogun odun o
 • Ori iwefa tun wa daya oba o
 • Araiye e mura ara ona bamiyo
 • Eba migb’ohun soke
 • Kakorin iyin s’Oluwa
 • Ko ma s’eni tole ri opin enia rara
 • Talaka ti koku tun le pada d’elesin
 • Ori iwefa wa d’aya oba o
 • A deni a awa se hun
 • Erin j’ogun ola o erin j’ogun dada re
 • Igb’ojo se wo t’ojo d’ojo ale’ E gbo o
 • Edumare je ka fo gun omo sile ka ilo
 • Solomoni oluwa jogun baba re o
 • Ina ku f’eru bo’ju
 • Ogede ku f’omo re ro’po baba Dafidi
 • Igba ojo o oja lo igba otutu n bo
 • Igba eru ni yio j’ogun
 • T’oye t’otutu dandan
 • Solomoni oluwa o j’ogun baba re o
 • A! beni awa se hun
 • Erin j’ogun ola o erin j’ogun baba re o
 • Igb’ojo se wo, t’ojo d’ojo ale e gbo o
 • Edumare je k’a f’ogun omo sile k’a ilo
 • Solomoni oluwa j’ogun baba re o
 • Baba l’aiye o, Hun
 • Baba l’orun o, Hun
 • Baba t’o dade aiye, t’o f’eti ba le
 • Boya nwon atun pe on l’orun
 • Hun
 • Solomoni oluwa o j’ogun baba re o
 • Ye
 • Oro yi d’orun oro yi d’orun o
 • Awa ti nkorin ogo awa tin sere iye
 • Awa ti ns’alagbawi o lodo baba
 • Ti ns’aiye yi di re e
 • Ye
 • Oro yi d’orun oro yi d’orun o
 • Enit’o l’ogbon ori o
 • Enit’o l’ogbon okan
 • Eni fe s’aiye ogo Ko f’okan bale
 • Ye
 • Oro yi d’orun oro yi d’orun o
 • A! Solomoni o
 • Solomoni baba gbere o
 • Baba a re ‘le yip e o
 • Lo la Oluwa
 • Baba atele yi pe o
 • L’ola awa o
 • Ade a pe l’orire, bata l’ese re o
 • Enikeni ti ko ba si gba
 • K’o lo ri s’okun
 • Abinu eni ko ma le pa kadara wa po
 • Ota nse l’asan ni ko le ri wa mo o
 • A! Solomoni o
 • Solomoni baba gbere o

 • THE END

 • ALL RIGHTS RESERVED