Strike and Hunger


    ACT 1 SCENE 1


  • 1 OBA YEJIDE NINU IJOBA RE GBOGBO AWON ENIA RE SI NWARIRI NIW AJU RE

  • A won enia :
  • Iba o aki o Oba nla
  • Iba o aki o Oba iga
  • Iba o aki o Oba ogo
  • Yejide o lo o aki o Oba Ogo
  • Yejide Oba ajeji ajeji nile wa
  • Oba on’ ile erekusu e o od’ile
  • Oba on’ ile erekusu e o od’ ile
  • O t’ oju omi bo wa ba awa
  • O g’oke wa ba wa n’ile awa
  • E o d’ile
  • O lo b’awa s’ona sinu oko
  • O lo ba wa s’ona s’inu ira
  • O wa gun ori oye baba awa
  • O yi lo o yi lo o
  • Yejide o lo o a ki o Oba ogo
  • Oba erin l’ o nigbo
  • Oba efon l ‘ o l’ odan
  • Yejide iwo l’ o l’okun
  • Okun mi ho wuruwuru
  • Osa mi lu fiwafiwa
  • Olubombom ye (2)
  • Onigelegele o eiye okun
  • O yi lo o yi lo o
  • Yejide o lo o a ki o Oba ogo

  • OBA YEJIDE SI DA AWON ENIA RE LO OHUN PELU IGBERAGA, O SI SE ILERI
  • LATI GBA WON SI ISE KOBOKOBO OJUMO

  • Oba yejide
  • Enyin arugbo, enyin enia
  • Enyin iranse enyin iwafe
  • Enyin eru baba mi
  • Mo r ‘ire aiye mo j’ oba l ‘oke
  • Enyin enia e gbon
  • E gbon e gbon riri(ha ha)
  • E duro , emi Yajide oba ogo
  • Mo r’ire Ebumare
  • Emi r’ire Ebumare
  • Emi ajeji Oba nla o
  • Mo gba ile onile mo fi se le’le
  • mo gba ile onille fi sanra
  • Mo f’ okunkun lile bo won loju o
  • Nwon ngbon nwon ngbon riri
  • Kail e duro , kai le duro
  • Emi Yejide Oba ogo
  • Mo r’ ire Edumaaare o
  • Emi lo n’ ise owo
  • Ise ori akoowe
  • Ise irin lilu mo le
  • Ati ise irin lilu Reluwe
  • Enyin ti nwa se e ma be
  • Ise kobo l’ ose
  • E ko kuku le r’ ise omiran se
  • Af’ ise emi Oba
  • Ise kobo ojujumo
  • Ise kobo l’ oselose
  • E ma bo wa sise oba
  • O yi lo o
  • Okun mi ho wuruwuru
  • Osa mi lu iwafiwa
  • Olubombom ye (2) (Olubombom.
  • Onigelegele o eiye okun
  • O yi lo o yi lo o
  • Mo r’ ire Edumare

  • AWON ENIA RE SI GBA LATI SE ISE OBA WON NI KOBOKOBO OJUMO

  • Awon enia

  • Kabiyesi o Oba nla
  • Kabiyesi o Oba iga
  • Ase tire ni yio se
  • Ofin tire ni yio se
  • Ise tire la o se
  • Iwo to ni wa o a juba o
  • Alagbara meje
  • A ma mbowa s’ ise re o
  • A ma mbowa s’ ise Oba
  • Ise kobo ojujumo
  • Ise kobo l’ oselose
  • Iwo to niwa o a juba o
  • Alagbara meje
  • Alagbara ogun ni o
  • Alagbara abija kikan
  • O nfo l’ oke o nrin nile
  • O nrin l’omi o nrin l ‘osa
  • Oba erin lo n ‘igbo
  • Oba efon lo l’odan
  • Yejide iwo to l’okun
  • Okun mi ho wuruwuru
  • Osa mi lu fiwafiwa
  • Olubombom ye (Olubombom.
  • Onigelegele o eiye okun
  • O yi lo, o yi lo o
  • Yejide o lo, a ki o oba ogo

  • Awon Omobinrin A ti Omokunrin Ilu Njo Won nyo Si Nyo ninu ise Kobo Ojumo

  • Awon Onijo:

  • Iba o aki o oba nla

    ACT 1 SCENE 2


  • Awon enia Oba Nwa Ise Lati Se, A Si Gba Won Lati Se Orisirisi Ise Labe Oba

  • Awon Enia:

  • A nwa ise re o (2)
  • A nwa ise ti omo nfi npe
  • Enia ni Baba
  • A nwa ise ti ayie fi npe
  • Enia ni baba
  • A nwa ise re
  • K’ebi mase p’ore mi o
  • K’ebi mase p’ore re o
  • K’ebi mase pa baba
  • To bi wa l’omo a nwa ‘se
  • K’ebi mase p’agbalagba
  • Ko wa d’opuro o e
  • A nwa ise ire o
  • K’a ji l’owuro
  • Ka fi owo l’owo
  • K’a ji l’owuro
  • K’a ji l’owuro ka gbese soke
  • K’a sise k’a l’ohun l’eru
  • L’odun, Haramu l’ole jija
  • E! A nwa ‘se ire o
  • Je k’a lowa ‘se s’abe ijoba
  • Ijoba to ni wa
  • Ijoba to n’ile
  • Bo ba di ka sise ori o
  • Awa yio s’akowe
  • Bo ba di ka sise ogbon o
  • Awa yio s’akowe
  • Bo ba di ka sise eeri o
  • Awa yio fo gota
  • B’o ba di ka sise owo o
  • Awa yio wa moto
  • B’o ba di ka sise owo o
  • Awa yio te waya
  • B’o ba di ka sise agbara
  • A ti wa, awa yio lurinlurin
  • Awa yio lulelule
  • Awa yio f’irin tutu
  • Papo ka fi mo gbigbona
  • Awa yio pa mejeji papo
  • A wa di reluwe
  • A nwa ‘se ire o
  • A nwa ‘se ire o
  • A nwa ‘se ire o
  • A nwa ise t’omo fi npe
  • Enia ni baba
  • A nwa ‘se ire o
  • K’ebi mase p’ore mi o
  • K’ebi mase p’ore re o
  • K’ebi mase pa baba
  • To bi wa l’omo a nwa ‘se
  • K’ebi mase pa yeye
  • To bi wa l’omo a nwa ‘se
  • K’ebi mase p’agbalagba
  • Ko wa d’opuro o e
  • A nwa ise ire o

  • DIALOGUE

  • Akowe Oba Si De, A Si Gba Gbogbo Awon Osise na Si orisirisi Ise, Lati ise akowe titi De ise Gota Fifo ,
  • Inu Awon Enia Dun. Ohun Gbogbo Te Won Lorun. Won Nje, Won nmu, Won Si Nyo Ninu Ise Kobo Kan Ojumo

  • MUSIC

  • Awon Osise Wa L’enu Ise. Won Si Nkorin “Ise Ijoba Dun Li Adunju”

  • Oyinmomo, oyinmomo ado (2)
  • O dun o, o dun j’oyin lo
  • Ise ijoba mi, ijoba re
  • Ijoba awa Yejide aiye!
  • Ise ijoba o dun l’adunju
  • Owo ijoba o po l’apoju
  • K’iku ma pa wa o o Oba awa
  • K’arun ma mase gbe o de
  • Ara ka sise to dun o
  • Yejide ......................
  • Ka sise, ka sise, ka mu bo o
  • K’a lu gboun! gboun! gboun (2)
  • Ka lu gboun, ka sise
  • K’a lu gboun! gboun! gboun!
  • K’a lu gboun! ye!
  • K’a lu gboun! gboun! gboun! (2)
  • K’a lu gboun! ye!
  • Ise ijoba o dun l’adunju
  • Ise ijoba o dun l’adunju
  • Owo ijoba o po l’apoju
  • K’iku ma pa wa o o Oba mi
  • K’arun ma mase gbe o de
  • Ara ka sise to dun o Yejide
  • K’a lurin gbigbona K’ a lu tutu
  • A dun jem! jem! jem! (2)
  • A dun, jem ka sise
  • A dun jem! jem! jem! (2)
  • A dun, jem ye
  • Ise ijoba o dun l’adunju
  • Owo ijoba o po l’apoju
  • K’iku ma pa wa o o Oba awa
  • K’arun ma mase gbe o de
  • Ara ka sise to dun o Yejide
  • K’a sise ka sise ka mu bo o (2)
  • Ka f’ef’ri ka yinbo
  • Ka se se fika fika fika (2)
  • Fika fi -----ka sise
  • Ka se fika1 fika! Fika! (2)
  • Fika fi ---- ---- (2)
  • Fika fi ----- ------ ye
  • Ise ijoba o dun l’adunju
  • Owo ijoba o po l’apoju
  • K’iku ma pa wa o o Oba awa
  • K’arun ma mase gbe o de
  • Ara ka sise to dun o Yejide
  • Oyinmomo oyinmomo ado (2)
  • O dun o dun j’oyin lo (2)
  • Ise ijoba mi ijoba re
  • Ijoba awa, Yejide aiye
  • Ise ijoba o dun l’adunju
  • Owo ijoba o po l’apoju
  • K’iku ma pa wa o o Oba awa
  • K’arun ma mase gbe o de
  • Ara ka sise to dun o Yejide
  • Olajiboke! ------ ----- -------
  • Oluwa lo gbe ‘se yi bo o --- Olujibombom
  • Edumare gbe ‘se yi bo o ----- Olujibombom
  • A! ---- ---- ---- o yi o (2) ----- Olujibobom
  • Olujiboke! ---- ---- Olujibombom

  • DIALOGUE

  • Awon ojise Oba de lati Iga Oban nwon si jise
  • Oba Fun Awon Enia Na pe Onje Won Pupo Ni Ilu.
  • Ati pe A da oja Kan Sile Ni Iga Oba Nibiti
  • Gbogbo Awon Oba Kekeke to wani Igberiko la
  • Ma mu onje wa fun tita Iga Oba

  • MUSIC

  • Oba alade a gbo a gbo
  • Oba Iga a gba a gba dandan
  • Oba to ni wa a gbo a gba
  • Ase tire ni yio se
  • Aja to ba f’oju re d’ ekun
  • A ma ke kainkain
  • Ase tire ni yio se
  • Baba mi a
  • Oba erin lo n’igbo
  • Oba efon lo l’odan
  • Oba Yejide Oluwa
  • Lo n’ ile aiye o
  • Ase tire ni yio se
  • Baba mi a
  • Oba gba gari wa
  • O gba ikoko obe
  • O gba epo o gb’ eran a o ko
  • Tokotaya nje jero
  • O ko won sinu iga
  • A nlo raj a nile oba
  • To ba di lola
  • Ase tire ni yio se
  • Baba mi a
  • Oba awa wi , wi, o wi ,o , wi rere (2)
  • Oba awa fo fo o fo o for ere (2)
  • Alagogo to npe o e wi re o
  • A mbewa ra onje
  • Ninu oja ole bi
  • A mbowa ra onje
  • Ninu iga oluwa
  • A mbowa r’ epo
  • A mbowa r’ epo
  • Gbogbo ebi ara ore o
  • A mbo war a jero
  • Ase tire ni yio se
  • Baba mi a
  • Jero oniyo jero alata
  • Jero oniyo jero olomi
  • Gbogbo ebi ara ore o
  • A nbo wa ra jero
  • Ase tire ni yio se
  • Baba mi a

    ACT 1 SCENE 3


  • DIALOGUE

  • Gbogbo awon osise , l’okunrin l’obirin l’omode
  • Ati l’ agba si wa si oja ebi lati ra onje
  • A na opolopo ni pasan. Opolopo si gbogbe
  • ni oja ebi na a fun omode kan pa
  • Aboyun kan si bimo pelu agbara opolo po.
  • Awon ti owa lati o wa lati ra onje ko ri ra
  • Won si pada sile li owo ofo ati sinu ebi

  • MUSIC

  • Iba yejide aiye
  • Iba yejide ogo
  • Aiye nyi lo bi ogo a
  • Enia mi nlo bi osa o
  • Iwo ni baba awa
  • Ebi l’ayo ebi l’ayo
  • Ebi l’ayo ebi l’aye
  • Ebi l’ayo ebi l’ayo
  • Ebi l’ayo ebi l’ode
  • Aiye nyi lo bi ogo a
  • Enia mi lo bi osa o
  • Iwo m baba awa
  • Aja ki iko wagbawagba eko laiye
  • Eyele ki iko wagbawagba eko beni
  • Iponri aja o j’obi o
  • Iwo ni baba awa
  • Ebi l’ayo ebi layo
  • Ebi l’ayo l’ode
  • Aiye nyi lo bi ogo a
  • Enia mi lo bi osa
  • Iwo ni baba awa
  • Awa l’a b’onifa
  • Awa l’a b’alufa
  • Awa l’a b’nigbagbo o
  • Ko i d’omo Jesu o
  • Jesu ma je o
  • Jesu ma je o baje o

    ACT 1 SCENE 4


  • MUSIC

  • Ijoba aiye d’orikodo
  • Ijoba aiye ndarugbo lo
  • Ijoba aiye jin si koto
  • Ijoba aiye ndarugbo lo
  • Ojo ekun ku si dede
  • Ojo ekun ku si dede
  • Ojo ekun sunmo o
  • O nwo inu le laiye
  • Oba alagbara yejide aiye o
  • Njoba b’igbati ekun njoba o
  • L’ori awon eranko inu igbo
  • N’joba b’igbati ekun njoba
  • N’joba b’gbati esu njoba
  • L’ori awon eranko inu igbo
  • E o yi o Edumare to da
  • On leni to da wa
  • Be ko ma da wa saiye o
  • K’ a le s’eru re
  • Edumare a da oku orun a da
  • Ori baba wa to ku lo s’orun
  • A ba awon apania ja o
  • E bi npa wa a e gbo o
  • Ebi npa awa afiyajeun
  • Awon arugbo won nku iku ebi
  • N’ile awa afiya – jeun
  • Awon abiyamo won nku iku ebi
  • N’ile awa afiya jeun
  • Awon abiyamo won nku iku ebi
  • N’ile awa afiya jeun
  • Awon aboyun nbimo nbimo iya
  • Won nbimo l’agbara s’oja ebi
  • Edumare a da
  • Oku orun a da
  • Ori baba wa to ku lo s’orun
  • Aba awon apania ja o
  • Awa osise ko r’owo jeun
  • Be lao laso be lao lewu
  • Ihoho l’awa nrin bi obo
  • Oba yejide nje Yejide nmu
  • Ko ranti p’ojo esan nbo
  • Edumare a da
  • Oko orun a da
  • Ori baba wa toku lo s’orun
  • A baa won apania ja o

  • DIALOGUE

  • Awon osise Nse idaro Ara Won Ebi Ati
  • Iyan Nja Nilu. Onje Won pupo lati ra
  • Oba yejide ko lati fi owo kun owo awon
  • Osise awon eniti nku iku ebi. Ebi nle,
  • ebi l’ode, owon oja onje ati aso wiwo
  • Owo ise oba ti ko to, si mu gbogbo awon
  • osise da ise d’ile

  • MUSIC

  • Ebi npa wa o ara mi
  • Ebi npolomo awa
  • L’aiye l’aiye l’ogun ti nja
  • Eyi le julo
  • L’ati igbat’aye ti se
  • Enia dudu o ko ku iku ebi
  • Eyin a de –lu malo
  • Eyin l’e mu gari d’owon o loju wa
  • Edumare awa nbe oo
  • Dariji awon apania o
  • Yejide nje bota o
  • Enia dudu nje ero
  • Yejide nje nama
  • Enia dudu nja wo eran
  • L’ati igbat’aiye ti se
  • Enia dudu ko ku iku ebi
  • Eyin a – de- lu-ma-lo
  • Eyin le mu gari dowon o l’oju wa
  • Edumare awa nbe o
  • Dariji awon apania o
  • Yejide nje buredi o
  • Enia dudu nje jero
  • Yejide nje suga o
  • Enia dudu mu omi ata

  • Awon osise si da ise oba sile

  • Orin yi pada si ........

  • Ki la a o Fi Kobo Ojumo Se

  • A mi lo r’oba
  • A mi lo ri’joye l’ori aga
  • Owo ise wa ko to o
  • Kil’a o fi kobo ojumo se
  • Awon osise ngba kobo ojumo
  • K’i l’a o fi kobo ojumo se
  • B’aiye tile yi pada
  • To d’aye Adam l’oju wa
  • K’ila o fi kobo ojumo se
  • Iyawo mbe l’aye o
  • Ninu kobo nbe yio jeun
  • Omo t’abi laiye o
  • Ninu kobo nbe yio jeun
  • Baba to bi wa lomo
  • Ninu kobo nbe yio jeun
  • Yeye to bi wa lomo
  • Ninu kobo nbe yio jeun
  • B’omo wa lo ile we o
  • Ninu kobo l’a osan
  • Baiye tile yipada
  • T’ o d’aiye Adam loju wa
  • Kil’a o fi kobo ojumo se
  • Gari won o ju wura o
  • Kil’a o fi kobo ojumo se
  • Epo won o ju wura o
  • Kil’a o fi kobo ojumo se
  • A mi lo r’oba
  • A mi lo ri ijoye lori aga
  • Ko ye ko gbebe wa
  • Ye o ka ma ma daro o
  • Eni ma bimo a yo f’olomo a
  • Eni ma r’ire ayo f’oire a
  • Gbogbo araiye e wa
  • Parapo ka jija ebi
  • Osise ti mbe l’aiye
  • To ji ti ko r’onje je
  • To tun f’akisa bora
  • Lasanlasan lo nbe laye
  • Eni to ku san ju u lo
  • O tan o ko rorun a
  • Yaho.....(Yaho.....)
  • Tembelekun omo a f’oru rin o

  • Ayinde ;-

  • E ye e gbo ara mi
  • Bi a ba lo r’oba awa
  • To ba ko dandan
  • Bi a ba lo r’oba awa
  • To ba ko jale o
  • Ki’la o ti se eyi si o
  • Ki’la o ti se eyi si o
  • Ki la o fi kobo ojumo se?

  • Awon osise

  • A o da ise re sile fun
  • Bi a ba lo r’oba awa
  • To ba ko jale o
  • A o da se re sile fun
  • Kili a o fi kobo ojumo se?

    ACT II SCENE 1


  • Awon osise pejo lati lo ri oba Yejide

  • Nipa oran kobo ojumo lehin ti won ti
  • Da ise oba sile. Nwon si yan okunrin alagbara kan lati se Olori won
  • Oba si ko latifi owo kun owo ise won.
  • Awon osise si fi ake ko ri lati pada s’enu ise

  • MUSIC

  • Awa o gba awa o gba
  • Aawa o gba k’ ama sise
  • K’ enikan si ma k’ere re lo
  • Bi a ba sise ki a gbo
  • B’ a o ni le se ki a mo o
  • Eni ba sise ti ko r’ere je
  • O gbe ra sanle lasan o
  • Awa o gba awa o gba
  • Awa o gba k ‘ a ma sise
  • Enikan si ma ke ere re lo
  • Edumare a da oku orun a da
  • Ori baba wa to ku lo s’orun
  • A ba awon apania ja o
  • E je ki a da ise oba s’ile
  • E je ki a da ise oba sile
  • K’ a pe yejide oba awa
  • Oba oluwa abija- kikan
  • Boya a fi ade re s’ile o
  • Ki o ni kan sise ori
  • Ki onikan fogota o
  • Ko nikan sise owo
  • Ko nikan sise ori
  • Ko nikan fogota o
  • Ko nikan lu rin ( a egbo)
  • Ko nikan rorin ( a egbo)
  • Ko nikan rorin ( a egbo)
  • Awa o gba awa o gba
  • Awa o gba ka ma sise
  • K’ enikan si ma k’ere re lo
  • Edumare a da oku orun a da
  • Ori baba wa to ku lo s’orun
  • A ba awon apania ja o

    ACT II SCENE 2


  • Awon enia si tun wa si oja elebi l’ati ra
  • Onje. A si nta panu gari kan ni silemeta
  • Ni igboro. A si tun na won ni inakuna bi ti isaju
  • A si mu opolopo ninu won lati s’ejo fun , lati awon omode
  • Titi de awon arugbo ati awon osise ti nlo s’ibi ise

  • MUSIC

  • Asoju oba nje won nje
  • Won nje won mu
  • Ijoye oba nyo won nyo
  • Won nyo sese
  • Awon osise nku iku ebi
  • Tokot’aya nje jero
  • Edumare ye o o dowo re
  • a-wi-ma-ye-hun
  • ko gba wa lowo awon
  • abinu eni ti nba ni daro
  • asoju oba nje won nje
  • won nje won nmu
  • ijoye oba nyo
  • Won nyo sese
  • Gbati ola gori ola o
  • Gbati ola gun won l’egun o
  • Won gb’onje ti oluwa fun wa l’ojo aiye wa
  • Won si ko wa po won wa
  • Nbo wa bi eni nb’eranko
  • Tiya omo nfosanlo o
  • T’oko t’aya nku iku ebi
  • Gbogbo wa si ramota o
  • Ki a to jeun ata
  • Ramota ramoto ramoto rasewon o
  • Eni ramota ara si moto
  • Eni ramoto ara s’ ewon o
  • Edumare ye o d’ owo re
  • K’ ori wa ma mase ku iku ebi
  • K’ ori wa ma mase ramota o
  • Eni ramota ara si moto
  • Eni ramoto ara s’ ewon o

  • AWON ONIJO TI NKOJA LO SI YA LATI RA
  • ONJE WON SI SIRE IDARAYA FUN AWON ENIA
  • NA TI EBI NPA

  • Awon onijo: A e ma ku oja o
  • Enyin ti nfi ipa jeun
  • A e ma ku oja o
  • E yin ti nfi iya jeun
  • Kilo gbe yin d’oja ale o

  • Awon enia :- E bi lo gbe wa de bi aiye o
  • E bi lo gbe wa de bi
  • Ebi lo gbe mi de bi
  • Awa o sun lat’ale ana
  • A mi s’aisun onje
  • A wa o sun latale ana
  • A mi s’aisun ebi o
  • Ebi, ebi, ebi, ebi o
  • Ebi lo gb’ori wa,
  • De ile yi o ebi
  • Awon a-de-lu-ma lo awon lo
  • Mu gari do’owon l’oju wa
  • Edumare a da. Oku orun a da
  • Ori baba wa to ku jo s’orun
  • A baa won apania ja o
  • Eiye l’enia, eiye o, eiye o l’enia
  • Iwoyi ana omo wa ni yara o
  • Eiye l’enia
  • Yejide mi je o
  • Akowe mi je o
  • Won ni k’a wa gba ‘we
  • Ka’i je o, Yejide mi je o
  • Awodi e ku ewu o
  • Ewu ina ki ip’awodi o

  • AWON ONILU APALA TI NKOJA LO SI YA LATI SIRE IDARAYA FUN AWON ENIA NA TI EBI NPA

  • iye ni iye eiyele
  • Yiye ni ye eiyele ayie o
  • Riro ni iro adaba l’orun o
  • Owo olowo mo fi d’aso temi
  • Owo olowo lo fi d’aso tire
  • Ewu mi a, mo fi njo
  • T’e nwo mi
  • Okere wa g’ori iroko
  • Oju olode mo
  • O dile Yejide Oluwa
  • K’a to s’apero
  • Yiye ni iye eiyele
  • Yiye ni ye eiyele ayie o
  • Riro ni iro adaba l’orun o
  • Yiye ni iye eiyele
  • Yiye ni ye eiyele ayie o
  • Riro ni iro adaba l’orun o
  • Oba to s’abule di’gbo
  • Oba to s’abule d’ile o
  • Araiye ko ni gbagbe re
  • Oba elebi
  • Edumare ma ma je
  • K’a s’oju idaro obe o
  • Owo olowo mo fi d’aso t’emi
  • Bi mo ba joba
  • Bi iwo ba joba
  • Bi gbogbo wa ba parapo
  • Ka joba lojo ayie wa o
  • Edumare ma ma je
  • Ka joba elebi
  • Edumare ma ma je
  • Ka joba si’le iyan o
  • Aja ki ko wagbawagba eko laiye
  • Eyele ki ko wagbawagba oka beni
  • Iponri aja o jobi o
  • Iro ni won pa fa aja
  • Edumare ma ma je
  • Ka joba si’le iyan o
  • Owo olowo mo fi da’so temi etc

  • Awon osise d’a sele Won nlo bi omi

  • Ba wa be Yeside Oluwa
  • Ko ma mase bo ti mo o
  • Ko fun wa ni onje
  • Ebi npa wa o
  • K’o fun wa ni onje
  • K’ebi mase pa wa s’orun
  • K’o je ka ri je
  • K’o je ka ri mu
  • K’ebi ma se pa wa d’ale o
  • Ka ma se d’aro
  • Owo olowo mo fi daso temi etc

  • A MU AWON ARUFIN WA FUN IDAJO NI ILE EJO OBA YEJIDE. AWONOMODE,
  • AWON ABOYUN ATI AWON OBA IGBERIKO TI WON KO MU ONJE WA SI OJA ATI
  • AWON TI NTA OJA OWON. AWON OPOLOPO SAN OWO NLA SI APO OBA. AWON
  • OPOLOPO LI A SI JU S’EWON

  • Ile Ejo:

  • Ile ejo ile ejo e a
  • Ile ewon ile ewon o buse
  • Adajo aiye ma re o
  • Edumare l’adajo orun
  • Ohun i a de li aiye
  • O de gboingboin
  • Ohun ti a da li orun
  • O de gboingboin
  • Eni to ba t’owo wa
  • Wewon l’ojo oni o
  • O we’won olorun o we’won esu
  • Edumare ma maje
  • K’a r’ibi ewon Olorun
  • Ile ejo ile ejo e a ete
  • E lo ma ko wan lo
  • Awon arufin oba ninu oja elebi
  • Awon arufin oba ninu iga Oluwa
  • Awon to fi jero sile
  • T’o tun nra repo o
  • Awon oba alade ti won ko
  • Lati mu gari bo s’oja elebi
  • Awon to lo ramota o

  • Adajo:-

  • Idajo aiye re o
  • Idajo orun nbo o
  • Ipade di sanmma o
  • Sanma mejeje
  • Awon ti won sanwo ejo
  • Won jebi
  • Awon ti won sanwo oja
  • Won jebi
  • Enito ba pe k’ila nse
  • O d’ota Oluwa
  • Ipade di sanma o
  • Sanma mejeje
  • Idajo aiye re o
  • Idajo orun mbo
  • Ipade di sanma o
  • Sanma mejeje

  • OBA YEJIDE SI GBA LATI MA SAN SILE
  • MEWA OJUMO FUN AWON OSISE O SI DAWO
  • OJA EBI DURO INU AWON OSISE DUN
  • AWON ENIA SI NYO ILU TORO AIYE
  • SIROJU OPE NI FUN OLORUN

  • Awon osise:-

  • A a yo, dupe o l’owo Olorun
  • A a yo, a dupe o l’owo o re Jesu
  • Enito yo wa kuro
  • Ninu eru aiye o
  • Enito gba wa kuro
  • Ninu eru aiye o
  • N’ile enia dudu o
  • Awa odomobirin
  • N’ile enia dudu o
  • K’iku ma pa wa o
  • K’arun ma se gbe wa de o
  • Nje Oluwa awa nrele o
  • A nrele baba to bi wa
  • L’ojo aiye o
  • Ki’ku ma pa wa
  • K’arun mase wag be wa de
  • A ara mi a ara mi o
  • Bo ba w’ola Oluwa
  • Awa yio bo ajaga
  • Ajaga lile lile
  • Ajaga t’a wo sorun
  • Gbat’a ba d’alagbara
  • Oba a-wi-ma yehun
  • K’iku ma pa wa o
  • K’arun ma se wa gbe wa de o

  • AWON ONILU ILORIN

  • Yiye ni ye ye eyeile(2)
  • Yiye ni iye eyeile aye
  • Riro ni ro daba lorun
  • Owo olowo mo fi dasotemi
  • Ewu mi a mo fi njo
  • T’e nwo mi etc

  • AWON ONIJO ORU
  • Iba yejide aiye
  • Iba Yejide ogo
  • Aiye nyi lo bi ogo a
  • Enia mi lo bi osa
  • Iwo ni baba awA ete

  • AWON OSIRE

  • THE END