Worse than Crime



    ITAN ERE NA


  • Li ojo igbani afotele kan jade
  • Lat’enu Olugbala
  • Pe egbon ni yio sin aburo l’ojo aiye o
  • Sugbon l’ola oluwa, egbon yio bo ajaga (2)
  • Ajaga lile lile,ajaga to wo s’ orun
  • Gba t’ogba d’ alagbara
  • Oba awi ma ye ‘hun, ki ku ma pa wa o
  • K’a run ma se gbe wa de o
  • Awon t’ o ni ‘reke aiye
  • Awon t’ o ni reke ile (2)
  • Nwon ko ri alagbase
  • Nwon ko ri eru kan sin
  • Baba Tomosi, Baba olore
  • Oun l’ o la won loye
  • Oun lo si mu won mo
  • P’ awon ara kan tun wa
  • Ti nwon l’awo dudu o
  • Ti won ni leke l’ orun
  • Ti won lo ko won bo
  • Nwon wa fi won s‘eru aiye o
  • Nwon ko ni gbagbe re
  • Tomosi a
  • Awon odomokunrin awon odomobinrin
  • Ni ‘le enia dudu o
  • Awon arugbo aiye
  • Awon ab’oyun ile
  • Ni ‘le enia dudu o
  • L’ a lo ni lo ku lo
  • L’a na ni na ku na
  • L’ a tun ju won ni bo mi
  • L’ a tun ju won ri bo le
  • B’ araiye ba gbagbe o
  • K’ awon t’oku lo s’orun
  • Nwon ko ni gbagbe re
  • Tomosi a
  • A e gbo o. A e gbo o.
  • Awon igbimo aiye awon igbimo ile
  • Ni ‘le alawo fun fun
  • Nwon ko ra won po l’ okun
  • Nwon s’ ofin lile ide
  • P’ enikeni ko gbodo tun sin eru aiye o
  • Ki iku ma pa won o
  • K’ arun ma se wag be won de o
  • Baba tomosi , baba olore
  • Oun l’ o la won l’ oye
  • Oun l’ osi mu won mo
  • P’ awon ara ka tun wa
  • Ni ‘le enia dudu o
  • Ti nwon ni ‘ ru bi obo
  • Ti nwon nil ‘leke l’orun
  • Nwon lo ko won bo
  • Nwon ti wa won s’ eru aiye o
  • Nwan ko ni gbagbe re
  • Tomosi a
  • Awon odomokunrin Awon adodomobinrin
  • Ni’le enia dudu o
  • Awon arugbo aiye awon aboyun ile
  • Ni mle enia dudu o
  • L‘ a lo ni lokulo
  • L’ a na ni ku no
  • L’ ato juu won ri b’omi
  • L’ a tun ju won ri bo le
  • Baraiye ba gbagbe o
  • Tomosi o
  • A ara mi, a rami o
  • B o ba wo ola oluwa
  • Egbon yo bo ajaga
  • Ajaga lile lile
  • Ajaga ton won s orun
  • Gbe to ba d alagbara
  • Oba awi ma ye hun
  • Ki ku ma pa wa o
  • K arun ma se wa gbe wa de o
  • A a yi o igbimo baba
  • B’igbimo wa gbe wa s’oke s’odo
  • Ire mbo l’ola
  • A a yi o igbimo baba
  • A ko ni je to ri re sepe
  • Ire mbo l’ola
  • A a yi o igbimo baba
  • Eni to ba d ori re k odo
  • O gba gbe Oluwa
  • A oyi o igbimo baba

    ACT 1 SCENE 1


  • Ni ilu awon alawo fun fun , ireke ni nwon gb’oju le l aiye won. Si kiyesi ireke won mbaje loko be ni awon alagbase ko si. Idamu si de ba won

  • Emo o Emo o - (2)
  • Ireke wan ba je l oko
  • Ireke wan ba je ni le
  • Awon a lagbase ko ma si o
  • Eyi su wa o
  • Be a ko l’ona meji se o
  • Ti a fi le gba r’ owo jeun
  • L ai se ireke ti agbin o
  • T o si nbaje ninu oko
  • Awon alagbase ko masi o
  • Eyi su wa o
  • Ebi npa wa orugben ngbe wa o
  • Awon aya wa ko r’ owo jeun
  • Be l awon omo ti abi o
  • Mura lati ku iku ebi
  • Awon alagbase ko ma si o
  • Eyi su wa o

  • Josefu okan ninu awon omo won si ranti
  • Ohun kan ti o’ se le l’ oju re

  • Josefu:
  • Enyi ara mi ma ranti o
  • Mo ranti oro kekere kan
  • E yi to se le loju mi
  • Niwoyi ana ni le o
  • Se kin ma so kin ma wi o

  • Nwon si mbe e nwon si nro o lati wi
  • Oro no jade

  • A! Josefu omo wa
  • A! Josefu eni re
  • Jowo wi ka gbo o
  • B o ko ba tete wi k a gbo l oni o
  • Ranti pe ojo nlo }2ce

  • Josefu si bere si rohin bayi pe

  • Enyin ara mi e gbo o
  • Baba Tomosi alagba o
  • Baba Tomosi olore
  • Eni t’o ti lo s’ ona jinjin
  • Ati s’orile aiye gbogbo
  • Oun lo pada bo wa si le o
  • To si nrohin l’oju mi
  • Niti enia aiye gbogbo
  • Titi lo ba awon tin won ni ru
  • Awon to njola iru bi obo
  • E je k a lo pe Tomosi wa o
  • Eni t o l o ogbon aiye
  • Eni t o mo we jinle jinle
  • K o la wa f ogbon aiye han wa o
  • Baba tomosi o

  • Awon enia re si dupe dupe lawo re.Nnwon be a lati pa baba Tomosi wa
  • A josefu omo wa
  • A Josefu eni re
  • A dupe dupe lowo re
  • Jowo ba w ape Tomosi
  • Jowo b a w ape Tomosi wa o
  • Eni t o l’ogbon ogbon aiye
  • Eni t o mo we jinle jinle
  • K o la wa f ogbon aiye han wa o
  • Bi a o ti se ri eru ra
  • Bi a o ti se ri eru sin
  • Ki reke wa ma baje mo o je
  • Ki reke wa ma baje ni le
  • K a tun le pada r’ owo jeun
  • K a tun le pada r owo ra so
  • K aiye ilu wa le toro
  • Ki joba ti a ni le lagbara
  • Jowo bawa pe Tomosi wa o
  • K’ o le wa f’ ogbon aiye han wa o
  • Baba tomosi o

  • Josefu si lope Baba Tomosi wa nwon so
  • Ohun edun won fun o nwon sib ere fun
  • Imoran

  • Baba Tomosi ,alagba o
  • Baba Tomosi, olore
  • Iwo t’o ti lo sona jinjin
  • Ati s’orile ayie gbogbo
  • Jowo wa f’ogbon ayie han wa o
  • Baba Tomasi o
  • Ireke wa nbaje l’oko
  • Ireke wa nbaje nile
  • Awon alagbase ko ma si o
  • Eyi su wa o
  • Be a ko lona meji se o
  • Ti a fi le gba rowo jeun
  • Lai se ireke ti a gbin o
  • To si nbaje ninu oko
  • Awon alagbase ko ma si o
  • Eyi su wa o
  • Jowo wa f’ogbon ayie han wa o
  • Bi a o ti se ri eru ra
  • Bi a o ti se ri eru sin
  • Ki ireke wa ma baje mo o
  • Ki ireke wa ma baje nile
  • Ki a tun le pada rowo jeun
  • Ki a tun le pada rowo ra so
  • K’ayie ilu wa de le toro
  • Kona ilu wa dele toro
  • Ki ijoba ti a ni le l’agbara
  • Awon alagbase ko ma si o
  • Eyi su wa o

  • Baba Tomosi si lawon loye bayi pe

  • Eyin ara mi ti e pe
  • Eyin ti npe mi l’olore
  • Ati Tomosi alagba
  • Ati Josefu ara
  • Mo dupe ola ti e fun mi
  • Emi to ti lo sona jinjin
  • Ati s’ori ile ayie gbogbo
  • Titi lo ba’ won tin won ni’ru
  • Awon ti n’jola iru bi obo
  • Awon ti n’so l’eke si orun
  • Nwon ko si m’eni to ns’Olorun
  • Nwon ko si m’eni tin se Jesu
  • E je ki a ko won bo
  • Ki a le wa fi won s’eru eru wa, iba o
  • Nwon dudu lara bi isaasun
  • Irun ori won bi koriko
  • Nwon ko si l’aso, nwon ko si l’ewu
  • Ihoho ni won nrin bi obo
  • E je k’a ko won bo
  • Ki a le wa fi won s’eru , eru wa, iba o
  • Ile won je inu iho
  • Nwon ko si ni bon tin won yio lo
  • Bi a ba mura bi ologun
  • E je ka lo ko won bo
  • Ki a la wa fi won se eru eru wa iba o
  • Bi e ba f era ninu won
  • Ogun poun lo wan wo
  • Bi e ko f era ni nu won
  • E je ka mura bi ologun
  • E je ka ko wan bo
  • Ki a le wa fi won s’eru eru wa, iba o

  • Awon enia re dupe dupe lowo re. Nwon si mura lati lo ko awon enia dudu bo wa se eru aiye

  • Baba tomosi, baba olore (2)
  • Iwo lo la wa loye
  • P awon arak an tun wa
  • Ti nwon lawo dudu o
  • Ti won ni ru bi obo
  • Ti nwan nil eke lorun
  • K a lo ko won bo
  • K a wa fi wan se eru aiye o
  • A ko no gba gbe re
  • Tomosi a
  • E je ka mura ka mura bi ologun
  • K a mu ra tijatija
  • Si le enia dudu o
  • K a lo ko wan b o
  • K awa fi wan s eru aiye o
  • A ko ni gbagbe re
  • Tomosi a
  • Baba tomosi , a dupe o
  • F ogbon ori re
  • A nlo kawon ti ko gbon bo
  • Fi won s’eru o
  • Ki reke wa ti a gbin
  • Ma se baje laye o
  • K a le pada rowo jeun
  • Ki joba ti a ni le pada
  • Tun wa lagbara
  • Iwo l’ si mu wa mo o
  • A ko si gbagbe re
  • Tomosi a
  • Baba Tomosi baba olore
  • Iwo lo la wa loye
  • A ko ni gbagbe re
  • Tomosi a
  • Baba Tomosi olore
  • Iwo l o i mu wa mo o
  • A ko ni gbagbe re
  • Tomosi a

    ACT 1 SCENE 2


  • Ni ile enia dudu nwon nje yan ,nwan nje su
  • Nwon f’ oyin mu ko , nwon se ariya Nwon si npa alo

  • Aso alaso to gbe o (2)
  • Alaso mbere re
  • Awa lo nile aiye o
  • Gbajumo bere o
  • Adaba gbori gi da ro
  • Felebute (3)
  • E agbe l o laro o, aluko lo l’osun (2)
  • Sa o jo re le o eyie ogo
  • Aluko eyie osa
  • Ma ba o re le o, eyie ogo

  • Sangonuga ati awon arabirin re si mura lati pa alo kekere kan

  • Eyin ara wa mo ranti itan kan
  • Itan kekere kan l’ori awa o (2)

  • Awon enia won si nsi won l’ori lati so itan na

  • A omo rere o
  • A omo rere
  • Sangonuga omo wa
  • Sangonuga omo wa
  • Sangonuga omo wa o
  • A omo rere

  • Nwon si bere si itan iso

  • Ninu iseda ayie o
  • Olodumare Baba
  • O da kokoro agbon
  • O da kokoro oyin
  • O pe kokoro oyin
  • O si s’alaye re fun u
  • Pe ka m’ewe iragba
  • K’a fi m’ewe iragba
  • K’a tun f’omi ojo kun n
  • Ohun gbogbo a wa d’oloyin
  • Ko ma yi pada o
  • Kokoro yi f’eti re si’le
  • O gbo t’Oluwa
  • Gba t’o de ile ayie
  • Ohun gbogbo di rere
  • Didundidun ni’le oloyin
  • Ko ma yi pada o
  • Olodumare Baba
  • Tun pe kokoro agbon
  • Agbon to ma’moju
  • Ko je gbe’ko Oluwa
  • Asehin wa asehin bo
  • Se kikoro ni’le agbon o
  • Ko ma yi pada o

  • Awon enia si nko eko ninu alo na

  • A omo rere o (2)
  • A o se bi oloyin
  • Ko ma yi pada o
  • ( A ko ni hu wa bi agbon o elenu meje o)
  • A omo rere o
  • A omo rere
  • A o se bi oloyin
  • Didundidun ni’le oloyin
  • Ko ma yi pada o

  • Asiko yen l’awon ojise oba si wa lati je ise oba ni ti odun ayo ti o di ojo meje

  • Sango oba l’o npe o
  • Obakoso l’o npe o (2)
  • Enyin ara ile at’ara oko
  • L’omode ati l’agba o ara wa
  • Eni nje yan ati eni nje’su
  • Eni mu’ko at’eni mu oyin
  • Eni t’o npejo o nini omi
  • Eni t’o nj’akara pelu eko
  • E sare wa ke wa wo Oba Ogo
  • Obakoso l’o npe yin o
  • Oba Sango da ojo ayo si ojo meje (2)
  • Ajodun wa di ojo meje e ma bo o
  • Agere ologijo agemo ofiyoyo (2)
  • Ojo odun d’ojo meje e ma bo o

  • Awon enia si njuba fun Obakoso, nwon si mura lati lo se odun na

  • Iba Iba Iba a ki oba Sango o
  • Oba t’o l’ayie (2)
  • A! Obakoso o
  • A! Obakoso
  • Sango l’ayie onida meji
  • E ku odun o o
  • A! Obakoso o
  • A! Obakoso
  • Oba Sapatirapa
  • Oba Sapatirapa
  • Lomilomi l’Oluwa
  • Oba t’o gbe’le ayie
  • T’o ns’alejo l’orun
  • Oba t’o nsoke di’le
  • Aja t’o ba f’oju re d’ekun
  • Iku re de o
  • A! Obakoso o
  • A! Obakoso
  • Owo ayie d’owo re
  • Igbala wa d’owo re
  • Sango Oba wi rere
  • Oba Sango for ere
  • Sango layie onida mej i
  • E ku odun o
  • A! Obakoso
  • A! Obakoso

    ACT 1 SCENE 3


  • Awon enia alawodudu na si lo je ipe Obakoso, nwon sin se odun ayo na lo

  • E! Agbe l’o l’aro o
  • Aluko lo l’osun (2)
  • S’a o jo re’le e eyie ogo
  • Aluko eyie osun
  • M’a ba o re’le o eyie ogo
  • Aluko eyie osa
  • Mu mi ka re’le o eyie ogo
  • Aluko eyie osa
  • E ma je o bo e ma je o bo
  • Eyi ti o bo a ro bi ewe (2)
  • Igo dudu oloje o ) 2ce
  • Mo f’oya be yin k’e mu wa o (2)
  • E wo b’o ti ns’ese t’o njo l’ode o
  • Ololufe njo l’ode o
  • Edumare t’o mo’jo ola
  • Ba mi gbo t’emi l’ojo ale o

  • Odun Agere si bere, awon enia si’nse ariya

  • Aiye re re o gbajumo yi o
  • Aiye re re o gbajumo yi o (2)
  • B’ aiye re ndun , ko gb’ona ti o to
  • B’ ola re ndun ko gbona ti o to
  • B ‘ ola re re ndun ko gbona ti o to
  • Aiye re re o gbajumo yi o
  • Adaba orofo
  • Eiye mi soro eiye
  • Eiye mi soro eiye)2ce
  • Adaba orofo
  • Eiye mi soro eiye
  • Eiye mi soro eiye o
  • S ‘ e ngbo hun l’ enu mi
  • Adaba orofo
  • Eiye mi s oro eiye
  • Ekun omo re , ekun omo da o (2)
  • Ekun omo t o nka o
  • Oro mi se yanmu yanmu
  • K aiye ma se baje o
  • Baba aiye o
  • K aiye ma se baje o
  • Baba mi a
  • E mase gbagbe o
  • Omo aiye o
  • E mase gbagbe o
  • Ara mi a
  • E.....baba mi a
  • K’ayie ma se baje o
  • Baba mi a
  • Oluwa gbare o
  • Baba ayie o
  • T’ojo t’erun bakan lo ju re o

  • Odun Agemo si bere, awon enia sin na nse ariya

  • Jalaka jalaka
  • Jobiri jobiri
  • B o ba ba le a dide
  • A t’orun bo wa jaiye
  • Aiye re ko m’enikan (2)
  • Arugbo ile won e a)
  • Arugbo ile won (2)
  • O ta agba e sagba
  • O to bale e se lo
  • Arugbo ile won o
  • Koro l’o wa to ngbo bi aja o
  • Asa igbo mbo o
  • K’ oloyele k’ oyele so (3)
  • Ijo wo l’o ma d’agba
  • Olurebete olurebete (3)

  • Ale si le gbo gbo won si lon sun ....

  • A o jo re le o ao lo sun
  • Nenene – nekunene(2)
  • Ojo ti dale ojo nlo
  • Nenene – nekunene
  • Osupa imole roro
  • Nenene – nekunene
  • Owiwi eiye afosan sun o
  • Nenene – nekunene
  • Odide eiye ale o
  • Nenene – nekunene
  • Nenene – nekunene
  • E! O yi o
  • A o jo re le o a o lo sun
  • Nenene – nekunene

  • Si lkiyesi i , li oru ojo ana, a si ko gbogbo Won le ru

    ACT 1 SCENE 4


  • Bayi li a se mu awon odo l eru

  • Ode aiye nlo
  • Ode aiye nlo )2ce
  • Pakute alegbede
  • Ode aiye nlo
  • Eku oko la o pa
  • Ati okere aiye o
  • Lobirikoto oku oko
  • Awo sen re o oku ona o
  • Eku emo la o pa
  • Pakute alegbede
  • Ode aiye nlo
  • Pakute l a nlo wo
  • Bo ya o le peku oko
  • Bo ya o le peku oko
  • Bo ya o le peku ona o
  • Ka ro uhun mu bowa je
  • Ka ro uhun mu bowa ta
  • Pakute alegbede
  • Ode aiye nlo
  • Ekute oko bo
  • K o wa d eku ile o yi o
  • A o yi o awoseun eku

  • Bayi li a si se ko awon obirin pelu leru

  • Ona oja

  • A nlo soja a n lo ta o
  • A nlo soja a n lo ta o
  • Ori wa bi re gbe wa de o (2)
  • Ajalamo ti o mo ri wa
  • Ba mi gbo t emi l ojo ale o
  • Kile nlo ta ara wa?
  • Isu ewura ni isu mi
  • Isu to funfun dabi iyan o
  • Isu t o funfun dabi owu
  • O s onje f emi ati iwo
  • O s onje fawa ati eyin o
  • A nlo ta ja foko wa
  • K awon omo wa le rowo jeun
  • Ori wo bi re gbe mi de o
  • A jalamo ti o mo ri wa
  • Ba mi gbo t emi l ojo ale o
  • Kile nlo ta ara wa
  • Gari gberefu gari mi
  • Gari gberefu gari mi
  • Gari t o funfun dabi eba
  • O s onje f emi ati iwo
  • O s onje f awa ati eyin o
  • A nlo ta ja foko wa
  • A nlo ta ja foko wa o
  • K’awon omo wa le rowo jeun
  • Ori wo bi re gbe mi de o
  • Ajalamo ti mo ri wa
  • Ba mi gbo temi lojo ale o
  • Kile nlo ta ara wa ?
  • Isu ewura ni isu mi
  • Isu ewura ni isu mi
  • Isu to funfun dabi iyan o
  • Isu t o funfun dabi owu
  • O s onje f emi ati iwo
  • O s onje lawa ati eyin o
  • A nlo ta ja foko wa
  • K awon omo wa le rowo jeun
  • Ori wo bi re gbe mi de o
  • A jalamo ti o mo ri wa
  • Ba mi gbo t emi l ojo ale o
  • Kile nlo ta ara wa
  • Gari gberefu gari mi
  • Gari gberefu gari mi
  • Gari t o funfun dabi eba
  • O s onje f emi ati iwo
  • O s onje f awa ati eyin o
  • A nlo ta ja foko wa
  • A nlo ta ja foko wa o
  • K’awon omo wa le rowo jeun
  • Ori wo bi re gbe mi de o
  • Ajalamo ti mo ri wa
  • Ba mi gbo temi lojo ale o
  • Kile nlo ta ara wa ?
  • E lubo, epo ati le oyin
  • Efo ebolo ati adiye
  • A t eko tutu ni le wa
  • O s onje fawa ati eyin
  • O sonje f eyin ati awa o
  • A nlo ta ja foko wa o
  • K’awon omo wa le rowo jeun
  • Ori wo bi re gbe mi de o
  • Ajalamo ti mo ri wa
  • K’awon omo wa le rowo jeun
  • Ori wo bi re gbe mi de o
  • Ajalamo ti mo ri wa
  • Ba mo gbo temi lojo ale o

  • Bayi li a si tun se ko awon arugbo li eru
  • Awa arugbo aiye o (2)
  • A nlo j ipe egbe wa
  • K a lo m emu onimole o
  • Awon omo torisa fun wa
  • L’ ojo aiye o
  • Ki ku ma pa won de o
  • K aruo mase wa gbe won de o (2)
  • A nlo j ibe egbe wa
  • K a lo me emu animole o
  • E ! omo laloye
  • Eni omo sin l o bi mo (3)

    ACT 2 SCENE 1


  • OJA - ERU

  • A si ko awon eru na wa si oja fun tita....

  • Awon a teru

  • Awon eru aiye re o
  • Awon eru aiye re o
  • Awa nta ja eru aiye o
  • Awa nta ja eru aiye wa
  • Eni t o f era k o ma bo o
  • K o bo w a re ru, eru wa
  • Owo eyo ni lopolopo
  • Iparo aso meje meje
  • B o ba f era win , o di lola
  • E ma bo wa ra eru wa
  • Awon eru aiye re o
  • Awon eru aiye re o
  • Awon eru aiye re o
  • Eyi to d’agba ninu won
  • L’awon okunrin to le to le
  • A’baiya fife bi erinmi
  • Ogoji oke l’owo won
  • Onini kan ko le din o
  • E ma bo wa r’eru wa
  • Awon eru aiye re o
  • Awon eru aiye re o
  • Awon eru aiye re o
  • Eyi t’o dagba ninu won
  • L’awon obinrin t’o le t’o le
  • Ati wundia, e gbo o
  • Ti a le ra bo w a fi s’aya
  • Etalelogbon l’owo eyo
  • Onini kan ko ma din o
  • E ma bo wa r’eru wa
  • Awon eru aiye re o
  • Awon eru aiye re o
  • Awon eru aiye re o
  • Awon eru aiye re o
  • Awon eru aiye re o
  • Awon eru aiye re o
  • Bi o ba r’eru, eru rere
  • Eru aboyun o, tomo-tomo
  • ‘Gba to ba bi mo, e gbo o
  • Wa f’owo s’osun, osun omo
  • Wa f’owo jere, owo re
  • E ma bo wa r’eru wa
  • Awon eru ayie re o

  • Awon Areru:-

  • Enyin oloja e ku oja o 2ce
  • Elelo le mi t’eru yen
  • Awon okunrin t’o le t’o le
  • Ab’aya fife bi t’erinmi
  • Awon eru aiye re o

  • Awon At’eru

  • A! Ara wa (2)
  • Awon okunrin t’o le t’o le
  • A ba’aya fife bi t’erinmi
  • Ogoji oke l’owo won
  • Onini kan ko le din o
  • Awon eru aiye re o

  • Awon Ar’eru:-

  • Elelo le mi t’eru yen
  • Awon obirin t’ole t’ole
  • Ati Wundia e gbo o
  • Ti a le ra bo w a fi s’aya
  • Awon eru ayie re o

  • Awon At’eru:-

  • A ara wa (2)
  • Awon obirin t’ole t’ole
  • Ati Wundia e gbo o
  • Ti a le ra bow a fi s’aya
  • Etalel’ogbon l’owo eyo
  • Onini kan ko le din o
  • Awon eru ayie re o

  • Awon Ar’eru:-

  • Elelo le mi t’eru yen
  • Awon aboyun o tomo-tomo
  • Olowo aro, elese osun
  • Elelo le mi t’eru yen
  • Awon eru ayie o

  • Awon At’eru:-

  • A ara wa 2ce
  • A ko le d’iye l’aboyun o 2ce
  • Boya ibeji lo ma bi o
  • Boya ibeji lo ma bi o
  • A ko le d’iye l’aboyun o
  • Awon eru ayie re o
  • Sugbon kini kan la o le so
  • Ogorun oke l’owo eyo
  • Onini kan ko le din o
  • Awon eru ayie re o
  • Eyin ti nra ja e ma ilo 2ce
  • E wa ba wa r’eru wa
  • Eru arugbo l’eru wa
  • Oke meji pere l’owo eyo
  • B’o d;onini kan awa ko ko
  • Ninu oke meji owo eyo
  • Awon eru ayie re o

  • Awon Ar’eru:-

  • Ewo l’ayie o )
  • Ewo l’ayie o ) 2ce
  • Bi o ba r’eru arugbo o
  • Inawo d’ona meji fun wa
  • Ko ni le s’ise ko ni le r’eru
  • Ko ni le s’are ko ni le wa le
  • Yio si tun jeun bi’le mo o
  • A ko ni r’eru arugbo o
  • Eewo o

  • Awon At’eru:-

  • Jowo r’eru wa

  • Awon Ar’eru:-

  • A ko ni r’eru arugbo o
  • Eewo o

    ACT 2 SCENE 2



  • Awon Alawo funfun fi oko ko awon enia alawo dudu l’eru lo si ilu won.
  • Awon enia dudu si ndaraya ninu oko

  • Sangonuga ati awon arabirin re

  • Enyin ara wa (2)
  • Ero kil’e nro (2)
  • Ti e d’ori kodo layie o
  • E wi k’a gbo o
  • Kil’e nro, ojo ayie nlo (2)

  • Awon eru:-

  • T’awa to wa ro ni tiwa
  • T’emi to mi ro ni t’emi(2)
  • Awon bale ile
  • Ti nwon o jade ri o
  • Awon iyale ile
  • Ti nwon ko jade ri o
  • L’a so l’okun po
  • T’a wa fi won s’eru ayie o
  • Ti’wa to war o ni ti’wa
  • Temi to mi ro ni t’emi
  • A ko ko le ayie o
  • A ko k’ona ayie o
  • A ko ni ki ti won
  • Ma sunwon l’ojo ayie o
  • Ewon gigun bi t’obo
  • Li a fi ko won po
  • T’a wa d’eru ayie o
  • Tiwa to wa ro ni tiwa
  • Temi to mi ro ni t’emi

  • Sangonuga ati awon arabirin re:-

  • A ara wa (2)
  • E ma banuje o
  • Tiwa to war o ni tiwa
  • T ‘ emi to mi ro ni t emi (2)
  • A won bale ile
  • Ti nwon ko jade ri o
  • L a so lokun po
  • T ‘ a wa ti won s eru aiye o
  • Tiwa to war o ni tiwa
  • T ‘ emi to mi ro ni t emi
  • A ko ko laiye o
  • A ko ni kiti won
  • Ma sunwon l ojo aiye o
  • Ewon gigun bi t’obo
  • L a ti ko wa po
  • T a wa d eru aiye o
  • Tiwa to war o to no tiwa
  • T ‘ emi to mi ro ni temi
  • Awon oga era si fi iya je won lopolopo
  • Nwon si fi won si enu ise lati lo mu oti
  • A nlo k a bo a nlo mu ti aiye
  • A nlo k a bo a nlo ki baba (2)
  • E ma s sie eru lo
  • A nlo k a bo a nlo mu ti aiye
  • A nlo k a bo a nlo ki baba (2)

  • Awon eru na si fi ibanuje da won l ohun

  • Bayi pe

  • A E ma se e lo o
  • A e ma se e o (2)
  • Awa ko da yin l ebi
  • Awa ko da yin lare o
  • Adake –dajo mbo o
  • Oba ologo meta
  • Adajo aiye mbo o
  • Oba t o mo boo la o
  • Oba t o mo jola
  • A e ma se e lo

    ACT 2 SCENE 4


  • Ninu iponju abi ise oko neru awon enia dudu
  • Ranti ilea won nmo esun wa si waju
  • Edumare

  • L ai se l ai ro
  • L ai pomo olomo je
  • L ai gba ya alaya lo
  • L ai ri wa oniwa f owo ho ri wa
  • Nwon taw a l eru o si le won
  • Edumare gba yi ro o
  • O buru j ese aiye lo
  • Edumare ye o dowo re o
  • Ajalamo ti o mo ri wa
  • Ile ogere a fokoye ri o
  • K o gba wa lowo awon abinu eni
  • Edumare gba yi ro o
  • O buru j esu aiye lo

  • Awon odo si mu esun won wa.....

  • Jeje l a duro o si lewa
  • Ti a nje yan o ni le w
  • Ti a nje su baba awa
  • Ti a nmu ko o ni le wa
  • Pelu akara pelu oyin
  • Awon alawo funfun ni nwon ko wa be
  • Si le baba to bi won lolm
  • Nwon si ko wa bo a wa d eru aiye o
  • Edumare gba yi ro o
  • O buru j esu aiye o
  • L ai se lai ro
  • Lai pomo olomo je

  • Awon omode mu esun ti won wa pelu

  • Awa omode o laiye wa
  • T a ko ti mo na taiye ngba
  • Nwon mu wa leru o ni le wa
  • Ni bi tan je iyan pelu isu
  • Ni ‘ bi t a mu akara pelu eko
  • T ‘a alafia
  • T ‘ o tun johun gbogbo gbogbo o laiye wa
  • Edumare t o daw a
  • O leni t o daw a
  • Be ko ma daw a saiye o
  • K a le s eru won
  • Ajalamo ti o mo ri wa
  • Ile \ogere af okoye ri o
  • K o gba wa lowo awon abinu eni
  • Edumare gba yi ro o
  • O buru j ese aiye lo
  • L ai se lairo
  • Lai pomo olomo je
  • Be ni awon aboyun o ni le wa
  • Ti ojo ibi ku fefe o
  • Nwon mu wa leru o ni le wa
  • Edumare k o da tiwa s are
  • Ajalamo ti o mo riwa
  • Ile ogere af okoye ri o
  • K o gba wa lowo awon abinuneni
  • O buru j ese aiye lo
  • L ai se lair o
  • Lai pomo olomo je(2)

  • Ani awon arugbo tun ri so pelu

  • Awa arugbo aiye o
  • A! Baba nwon lo nile
  • Ni bi t a ti ko wa wa o
  • T a si ko wa ta leru o
  • Awa nwo ja olorun lo
  • A mu wa kuro nile
  • Baba t o bi wa lomo
  • A ko raya mo o
  • A ko r’omo mo o
  • Edumare gba yi ro o
  • O buru j ‘ese aiye lo
  • L’ai se lairo
  • L’ai pomo olomo je (2)

    ACT 3 SCENE 1


  • Ojo ipade igbimo nla si de ni nla awon
  • Alawo – funfun nwon a fi adura bere ipade o

  • Ini ki dun , o dun o
  • Nwon fi fun wi pe (2)
  • Inu mi dun , odun o
  • O dun ni gbati
  • Nwon wi fun mi pe o
  • E je k’ a lo e je ka lo
  • Si le oluwa
  • Olodumare oba wa
  • Ojo aiye gbogbo wa d’owo re
  • K a feso jaiye olu
  • K a feso jaiye wa o
  • K a ma se gba gbe Oluwa wa
  • Eni to daw a lode leso
  • Enia dudu enia funfun
  • Gbo gbo l a o pa –po
  • T a o si f ola fun baba t o daw a
  • Ye ............. eni owo wa o
  • Af ‘oluwa af ‘oluwa
  • Ko si enia t o le tun t eda se
  • Edumare to mo jola o
  • Ba mi gbo temi lojo ale o
  • B aiye ba ko ji oku orun dide
  • Ba mi gbo t’emi lojo ale o
  • Edumare t o m’ ojo ola
  • Ba mi gbo temi lojo ale o

  • Alaga igbimo na sib ere fun imoran....

  • Enyin olola enyin igbimo
  • Enyin balogun ninu ogun
  • Enyin ti ngbero t’ aiye t’ orun
  • Titi lo ba won t’ona won jin
  • Awon alawo dudu gbogbo
  • Ero kila s oro loni o
  • E ‘ wi ki ngbo s’eti

  • Ogbeni olola ka ( William Wilberforce)
  • Si sir o nipa ti iya ti a fe je awon ala
  • Wodudu ti a ti ko leru

  • E duro e gbo ara mi
  • Mo si ni oro gigun jojo
  • Lati gbe ka’le loju wa
  • Nipa enia aiye gbogbo
  • Titi lo ba won l’ona won jin
  • Awon alawodudu gbogbo
  • Awon ti wan fi nseru aiye
  • Awon tin won fin a e rile
  • L’ oko ireke o , ile oyin
  • E f’eyi s’ero l’oni o a
  • Mo fe ki e gbo s’eti
  • Awon ara wa ti enyin mo
  • L’o ra won l eru o ni le won
  • L o ta won l eru osi le wa
  • Awon obinrin t o le to le
  • Awon ab’oyun at alagba
  • Ati omode o ni ile oyin
  • E gba yi ro po ara wa
  • E mase je ki aiye baje o
  • L’ oju yin o

  • Awon igbimo na sib a awon enia alawodudu
  • K edun nwon si so ofin lati fi opin si
  • Eru siosin

  • A! Ara wa A! Ara wa
  • Eyi ma koro l eti wa
  • Eyi ma yato l oju wa
  • P awon okunrin t o le tole
  • Pawon obirin to le to le
  • Awon aboyun ati agbalagba
  • Ati omode o ni le wo
  • L awon alawodudu gbogbo
  • L a fi nseru aiye
  • L a fin se ru ile
  • L okoo ireke o ile oyin
  • Eyi ma buro lojuu wa
  • O je ese aiye lo
  • E je k a so fin t o la to le
  • Pe enikeni ko ma gbodo
  • Sin eru aiye o l’ju wa
  • Enikeni ti ko ba si gba
  • K a fi won sewon titi aiye o
  • K aiye wa le simi (3)

    ACT 3 SCENE 2


  • Si kiyesi i awon alawo – dudu nse ise nseku
  • Ni oko ireke, si w obo awon alaweo funfun
  • Ti nfi won se eleya. Eyi si mu ikunsinu
  • Ati ija wa---

  • Awa l a ni reke aiye )
  • Awa la ni ireke ile)2ce
  • Baba wa ti mbe lorun
  • Baba wa tin be loke
  • L o fun wa ni le oloyin
  • Edumare gbowo wa o
  • A o je reke wa
  • Se ti baba wa ni ise
  • Enikene ti ko ba si gba
  • K o lo ri sokun
  • Edumare gbawa o

  • Awon eru na si ri eyi , nwon nke pe Sango
  • oba won lati gba won

  • Oju wa o dowo re
  • Igbala wa dowo re o (2)
  • A ki sango onida meji
  • A gb’orun jagun
  • Eni sango t’oju re wo le
  • Ko ni boba mo o
  • Asese jade akan
  • A ko mo bi t o nlo
  • Sugbon Sango , baba orisa
  • Ko daw a l’are
  • Oju wa d owo re
  • Igbala wa d’ owo re o

  • Awon oga eru gbo eyi, nwon si fi won
  • Se efe
  • A nlo k a bo
  • A nlo mu ti aiye
  • A nlo k a bo
  • A nlo ki baba wa
  • Eyin omo aborisa
  • E ma sise eru lo
  • Sango baba yion loriun
  • L ‘ oti so yin deru wa
  • E ma e
  • Ise era lo
  • A nlo k a bo
  • A nlo mu ti aiye
  • A nlo k a bo
  • A nlo ki baba wa

  • Awon eru na si da won l ohun bayi pe
  • A! E ma se e lo
  • A! E ma ase e lo (2)
  • Awa ko da yin lebi
  • Awa ko da yin lare o
  • A e ma se lo
  • Adake –dajo mbo o
  • Oba ologo meta
  • Adajo aiye mboi o
  • Oba t o mo j’ola
  • A e ma se lo

  • Awon oga eru na si bi won lere wipe

  • Tani eni t oko yin , l’oro , oro oluwa
  • Tani eni t’; oko yin l’oro ti jesu
  • Nibo lefi sango si
  • Sango baba orisa
  • Tani eni t oko yin , l’oro , oro oluwa
  • Tani eni t’; oko yin l’oro ti jesu

  • Awon eru na si fi binu da won lohun
  • Bayi pe

  • Baba wa ti mbe li orun(2)
  • On lo ko wa l’ona
  • Ona ile Olorun
  • Baba wa ti mbe li orun
  • Tiwa ye, tiwa ye, tiwa ye wa (2)
  • Tiwa ye wa ni ‘kun ara wa o
  • Pe awa npe Olorun o
  • Tiwa ye wa ni’kun ara wa o
  • Awa npe Olorun baba

  • A si j’ise fun awon enia dudu na nipa idasile won kuro ninu oko eru

  • Enyin omode ayie
  • Enyin agbagba ile
  • Enyin arugbo ayie
  • Enyin aboyun ile
  • Enyin eru ayie o
  • E f’eti ba le (2)
  • K’e gbo ise didun t’a ran o
  • Si enyin ti ns’eru aiye o
  • Igba yipada o
  • Awon igbimo ayie
  • Awon igbimo ile
  • Ni’le alawo funfun
  • Nwon ko ra won l’okun
  • Nwon s’ofin lile lile
  • Pe enikeni ko gbodo tun sin
  • Eru ayie o
  • Enikeni to ba si laya
  • Lati se s’ofin
  • La o ju s’ewon ayie o
  • Igba yipada o
  • A da yin s’ile, atu yin s’ile
  • E ma gbona ile lo si’le enia dudu o
  • S’ile oloyinmomo k’iku ma pa yin o
  • K’arun ma se wa gbe yin de o

  • Awon enia na si nyo nipa ti idasile won

  • A! a yo, a dupe o lowo Oluwa
  • A! A yo a dupe o lowo Re Jesu (2)
  • Eni t’o mu wa kuro ninu eru ayie o
  • Eni t’o yow a kuro ninu eru ayie o
  • Awa odomokunrin, awa odomobinrin
  • Ni le enia dudu
  • Awa arugbo ayie, awa aboyun ile
  • Ni le enia dudu
  • B’arayie ba gbagbe o
  • Awon t’o ku lo s’orun
  • A ko ni gbagbe re Olodumare o
  • A dupe lowo yin enyin igbimo
  • Enyin igbimo ile n’ile alawo funfun
  • T’o s’ofin lile lile
  • P’enikeni ko gbodo tun sin
  • Eru ayie o
  • Ki’ku ma pa yin o
  • K arun mase wa gbe yin o
  • Eeyin ara wa awa ore le o
  • Nje oluwa awa nre le o
  • A nre le baba t o bi wa
  • L ‘ojo aiye o
  • Ile enja dudu o ile oloyin – momo
  • Ki ku ma pa w o
  • K arun mase wag be wade o

  • A l ara mi A! Arami
  • B o ba woo la oluwa
  • Egbon yio bo ajaga
  • Ajaga lile lile,ajaga to wo s’ orun
  • Gba t’ogba d’ alagbara
  • Oba awi ma ye ‘hun, ki ku ma pa wa o
  • K’a run ma se gbe wa de o

    ACT 3 SCENE 3



  • A si fi oko awon alawo-dudu na pada
  • Si ilu won , nwon ain se ariya ninu okona

  • Ekun omo re,ekun omo da o}2ce
  • Ekun omo t o nke o
  • Oro nse yanmuyanmu
  • K aiye mase baje o
  • Baba aiye o
  • K aiye mase baje o
  • Baba mi a
  • E mase gba gbe o
  • Omo aiye o
  • E mase gbagbe o
  • Ara mi a
  • E ! ..............baba aiye o
  • K aiye mase baje o
  • Baba mi o
  • Oluwa gbere o
  • Baba mi a
  • Oluwa gbere o
  • Baba aiye o
  • T ojo t erun bakan
  • Loju re o

  • Nwon gunle ai ilu won nwon si fi ayo
  • Pade awon ara won:-

  • Iya mi laye anu iya se mi
  • Baba mi laiye anu baba se mi
  • Ori won ori won (2)
  • Gbe mi de ile iya}
  • Bi mi si ewo o
  • Iya mi abo ma re o omo rere(2)
  • Obirin ti so yunnwon so leke
  • Nitori owo ebi
  • A gbogbo wa le mi katike
  • K a le ba won lo
  • Iya mi abo ma re o omo rere (2)
  • Alajabi ewo, alajani ogo (2)
  • Alajani iya ogo iwo ni baba ewe
  • Iya mi abo ma re o omo rere (2)

    ACT 3 SCENE 4


  • Ada awon enia dudu na pada lo si ile
  • Nwon de ile li Alafia nwon si gbe ohun
  • Ope soke si Olorun

  • Edumare k’o gbo
  • Edumare k’o gba o (2)
  • Awa t a so d omo nipa re
  • Edumare ko gba o
  • K awa elese k a le de le wa
  • Edumare ko gba o
  • K awu elese k a le dade ogo
  • Edumare k o gba o
  • Fun wa ni gba gbo o olore
  • Edumare k o gba o
  • Ba wa le su sa o ka ma lo
  • Edumare k o gba o
  • Fun wa ni ye se o ojo nlo
  • Edumare k o gba o
  • Edumare k o gba o
  • Edumare k o gba o
  • Edumare k o gba owo wa
  • Awa t a so d omo nipa re
  • Edumare k o gba o
  • A ! messiah o, A! Messiah o (2)
  • Iran lowo wa, dowo re
  • Gba wa lowo esu o l’aiye wa
  • Gba t a ba pari o ise wa
  • K a ma de pade bi ebi
  • A! Olodumae o
  • Ope ope ope l a mu wa
  • Jesu Baba iyanu o
  • K a ma de pada wa d’eni idalobi
  • Jesu Baba Iyanu o
  • B aruni ri wa ,ona ko si pada lo
  • Jesu Baba iyanu o
  • K a tun le pada wa d eni idalare
  • Jesu baba iyanu o
  • K a ma de pada d omo igberiko
  • Jesu Baba iyanu o

  • THE END
  • ALL RIGHTS RESERVED.

Copyright © Ogunde Museum 2019